Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 9


Ori 9

A ó kó àwọn Jũ jọ ní gbogbo àwọn ilẹ̀ ìlérí wọn—Ètùtù nã nra ènìyàn padà kúrò ní Ìṣubú nì—Àwọn ara ti òkú yíò jáde wá láti isà òkú, àti àwọn ẹ̀mí wọn láti ọ̀run àpãdì àti láti ọ̀run rere—A ó dá wọn lẹ́jọ́—Ètùtù nì ngba ni là lọ́wọ́ ikú, ọ̀run àpãdì, èṣù, àti oró àìnípẹ̀kun—Olódodo ni a ó gbàlà ní ìjọba Ọlọ́run—Àwọn Ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ni a gbé kalẹ̀—Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì ni olùpamọ́ ẹnu ọ̀nà òde. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi ayanfẹ, èmi ti ka àwọn ohun wọ̀nyí kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ nípa àwọn májẹ̀mú Olúwa tí ó tí dá pẹ̀lú gbogbo ará ilé Isráẹ́lì—

2 Tí ó ti sọ sí àwọn Jũ, nípasẹ̀ ẹnu àwọn wòlĩ mímọ́ rẹ̀, àní láti ìbẹ̀rẹ̀ sísàlẹ̀, láti ìran dé ìran, títí àkókò nã yíò dé tí a ó mú wọn padà sí ìjọ onígbàgbọ́ òtítọ́ àti agbo Ọlọ́run; nígbàtí a ó kó wọn jọ sílẹ̀ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn, tí a ó sì fi wọ́n kalẹ̀ ní gbogbo àwọn ilẹ̀ ìlérí wọn.

3 Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, mo sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún yín kí ẹ̀yin lè yọ̀, kí ẹ sì gbé orí yín sókè títí láé, nítorí ti àwọn ìbùkún tí Olúwa Ọlọ́run yíò fi fún àwọn ọmọ yín.

4 Nítorí mo mọ̀ pé ẹ̀yin ti wádĩ púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín, láti mọ̀ nípa àwọn ohun tí mbọ̀; nítorí-èyi mo mọ̀ pé ẹ̀yin mọ̀ pé ẹran ara wa kò lè ṣe àìsòfò kúrò kí ó sì kú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nínú ara wa ni àwa yíò rí Ọlọ́run.

5 Bẹ̃ni, èmi mọ̀ pé ẹ̀yin mọ̀ pé nínú ara ni òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn wọnnì ní Jerúsálẹ́mù, láti ibi tí àwa ti wá; nítorí ti ó yẹ kí ó wà lãrín wọn; nítorí ó yẹ kí Ẹlẹ́dã nlá kí ó yọ̃da ara rẹ̀ láti di ẹni tí nsìn ènìyàn nínú ẹran ara, kí ó sì kú fún gbogbo ènìyàn, kí gbogbo ènìyàn lè di ẹni tí nsìn ìn.

6 Nítorí bí ikú ti wá sí orí gbogbo ènìyàn, láti mú ìlànà tí ó ni ãnú ti Ẹlẹ́dã nlá ṣẹ, o di dandan kí agbára àjínde òkú wà, o si di dandan ki àjínde òkú wá fún ènìyàn nípa ìdí ìṣubú nì; ìṣubú nã sì wá nípa ìdí ìrékọjá; nítorí tí ènìyàn sì di ìṣubú a ké wọn kúrò níwájú Olúwa.

7 Nítorí-èyi, ó di dandan kí ètùtù àìnípẹ̀kun wà—àfi tí ó bá jẹ́ ètùtù àìnípẹ̀kun ìdìbàjẹ́ yí kò lè mu àìdìbàjẹ́ wọ̀. Nítorí-èyi, ìdájọ́ ekíní èyí ti ó wá sórí ènìyàn níláti dúró fún ìgbà àìnípẹ̀kun. Bí ó bá sì rí bẹ̃, ẹran ara yí níláti di fífi fi lé lẹ̀ láti jẹ rà àti láti fọ́ sí wẹ́wẹ́ lọ sínú ilẹ̀, láti máṣe dìde mọ́.

8 A! ọgbọ́n Ọlọ́run, àanú àti õre-ọ̀fẹ́ rẹ̀! Nítorí kíyèsĩ i, bí ẹran ara kò bá dìde mọ́ àwọn ẹ̀mí wa kò lè ṣe àìdi ẹni tí nfi oribalẹ fun angẹ́lì nì tí ó ṣubú kúrò níwájú Ọlọ́run Ayérayé, tí ó sì di èṣù, láti máṣe dìde mọ́.

9 Àwọn ẹ̀mí wa kò sì lè ṣe àìdi bí ti òun, a sì di àwọn èṣù, angẹ́lì sí èṣù, tí a ó tì jáde kúrò níwájú Ọlọ́run wa, àti tí a ó dúró pẹ̀lú bàbá èké, nínú òṣì, bí oun tìkárarẹ̀; bẹ̃ni, sí ẹ̀dá nì tí ó tan àwọn òbí wa èkíní jẹ, tí ó pa ara rẹ̀ dà tí ó fẹ́rẹ̀ dàbí angẹ́lì ìmọ́lẹ̀ kan, tí ó sì rú àwọn ọmọ ènìyàn sókè sí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ìpànìyàn àti irú àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ gbogbo.

10 A! báwo ni õre Ọlọ́run wa ṣe tóbi tó, ẹnití ó pèsè ọ̀nà fún ìsálà wa kúrò ní ìdìmú èyà búburú yí; bẹ̃ni, ẹ̀yà nì, ikú àti ọ̀run àpãdì, èyítí mo pè ní ikú ti ara, àti ikú ti ẹ̀mí pẹ̀lú.

11 Àti nítorí ti ọ̀nà ìdásílẹ̀ Ọlọ́run wa, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, ikú yí, nípa èyítí mo ti sọ, èyítí ó jẹ́ ti ara, yíò jọ̀wọ́ òkú rẹ̀; ikú èyí tí nṣe ìsà òkú.

12 Ikú yí, nípa èyítí mo sì ti sọ, èyítí ó jẹ́ ikú ti ẹ̀mí, yíò jọ̀wọ́ òkú rẹ̀; ikú ti ẹ̀mí èyítí i ṣe ọ̀run àpãdì; nítorí-èyi, ikú àti ọ̀run àpãdì kò lè ṣe àì jọ̀wọ́ òkú wọn, ọ̀run àpãdì kò sì lè ṣe àì jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀mí ìgbèkùn rẹ, ìsà òkú kò sì lè ṣe àì jọ̀wọ́ àwọn ara ìgbèkùn rẹ̀, àwọn ara àti àwọn ẹ̀mí àwọn ènìyàn ni a ó sì mú padà sípò ọ̀kan sí èkejì; ó sì jẹ́ nípasẹ̀ agbára àjínde òkú ti Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì.

13 A! báwo ni ìlànà Ọlọ́run wa ṣe tóbi tó! Nítorí ní ọ̀nà míràn, párádísè Ọlọ́run kò lè ṣe àì jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀mí olódodo, àti isà òkú jọ̀wọ́ ara olódodo; ẹ̀mí àti ara ni a sì tún mú padà sípò òun tìkararẹ̀, gbogbo ènìyàn sì di aláìdìbàjẹ̀, àti aláìkú, wọ́n sì jẹ́ ọkàn alãyè, tí ó ní ìmọ̀ pípé bí ti àwa nínú ẹran ara, àfi tí ó jẹ́ pé ìmọ̀ wa yíò pé.

14 Nítorí-èyi, àwà yíò ní ìmọ̀ pípé ní ti gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti ìwà àìmọ́ wa, àti ìhòhò wa; olódodo yíò sì ní ìmọ̀ pípé nípa ìgbádùn wọn, àti òdodo wọn, tí a wọ̀ láṣọ mímọ́, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú ẹ̀wú òdodo.

15 Yíò sì ṣe pé nígbàtí gbogbo ènìyàn yíò bá ti kọjá láti ikú kíni yí sí ìyè, níwọ̀n bí wọn ti di aláìkú, wọn gbọ́dọ̀ farahàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ti Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nígbànã sì ni ìdájọ́ yíò dé, nígbànã sì ni a kò ní ṣe àì dá wọn lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdájọ́ mímọ́ ti Ọlọ́run.

16 Àti dájúdájú, bí Olúwa ti mbẹ, nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ́, ó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ ayéraye rẹ̀, èyí tí kò lè rékọjá, pé àwọn tí ó bá jẹ́ olódodo yíò jẹ́ olódodo síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tí ó bá sì jẹ́ elẽrí yíò jẹ́ elẽrí síbẹ̀síbẹ̀; nítorí-èyi, àwọn tí ó jẹ́ elẽrí ni èṣù àti àwọn angẹ́lì rẹ̀; wọn yíò sì kúrò lọ sínú iná àìlópin; tí a pèsè fún wọn; ìdálóró wọn sì rí bí adágún iná àti imi ọjọ́, tí ọwọ́ iná rẹ̀ gòkè sókè títí láé àti láé ti kò sì ní òpin.

17 A! títóbi àti àìṣègbè ni Ọlọ́run wa! Nítorí ó ṣe gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ti jáde lọ láti ẹnu rẹ̀, òfin rẹ̀ ni a kò sì lè ṣe àìmú ṣẹ.

18 Ṣùgbón, kíyèsĩ i, àwọn olódodo, àwọn ènìyàn mímọ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, àwọn tí wọ́n ti gbàgbọ́ nínú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, àwọn tí wọ́n tí faradà àwọn ágbélẽbú ayé, tí wọ́n sì ṣãtá ìtìjú rẹ̀, wọn yíò jogún ìjọba Ọlọ́run, èyítí a pèsè sílẹ̀ fún wọn láti ìgbà ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, ayọ̀ wọn yíò sì kún títí láé.

19 A! títóbi ni ãnú Ọlọ́run wa, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì! Nítorí ó gba àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ là lọ́wọ́ èyà búburú nì èṣù, àti ikú, àti ọ̀run àpãdì, àti adágún iná nì àti imí ọjọ́, èyítí ó jẹ́ oró àìnípẹ̀kun.

20 A! báwo ni títóbi mímọ́ Ọlọ́run wa! Nítorí ó mọ́ ohun gbogbo, kò sì sí ohunkóhun tí òun kò mọ̀.

21 Òun sì mbọ̀wá sínú ayé kí ó lè gba gbogbo ènìyàn là bí àwọn bá fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ̀; nítorí kíyèsĩ i, òun jìyà àwọn ìrora gbogbo ènìyàn, bẹ̃ni, àwọn ìrora ẹ̀dá alãyè gbogbo, àti àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Ádámù.

22 Ó sì jìyà èyí kí àjínde òkú lè rékọjá lórí gbogbo ènìyán, kí gbogbo ènìyàn lè dúró níwájú rẹ̀ ní ọjọ nla àti ti ìdájọ́ nì.

23 Ó sì pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn pé wọn kò lè ṣe àì ronúpìwàdà, kí a sì rì wọn bọmi ní orúkọ rẹ̀, kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ pípé nínú Ẹni Mímọ́ Isráẹ́lì, bíbẹ̃kọ́ a kò lè gbà wọ́n là ní ìjọba Ọlọ́run.

24 Bí wọn kò bá sì ronúpìwàdà kí wọ́n sì gbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀, kí a sì rì wọn bọmi ní orúkọ rẹ̀, kí wọ́n sì forítì í dé òpin, wọn kò lè ṣe àìjẹ́ ẹni ègbé; nítorí Olúwa Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, ti sọ ọ́.

25 Nítorí-èyi, ó ti fi òfin kan fún ni; níbití a kò bá sì ti fi òfin fún ni kò sí ìjìyà; níbití kò bá sì sí ìjìyà kò sí ìdálẹ́bi; níbití kò bá sì sí ìdálẹ́bi àwọn ãnú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì ní ẹ̀tọ́ lórí wọn, nítori ti ètùtù nì; nítorí a gbà wọn sílẹ̀ nípasẹ̀ agbára rẹ̀.

26 Nítorí ètùtù nnì tẹ́ àwọn ìbẽrè àìṣègbè rẹ̀ lọ́rùn lórí gbogbo àwọn wọnnì tí a kò fi òfin fún, kí á lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà búburú nì, ikú àti ọ̀run àpãdì, àti èṣù, àti adágún iná ni àti imí ọjọ́, èyítí ó jẹ́ oró àìnípẹ̀kun; a sì mú wọn padà sípò Ọlọ́run nì tí ó fún wọn ní ẽmí, èyítí nṣe Ẹni Mímọ́ Isráẹ́lì.

27 Ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí a fi òfin nã fún, bẹ̃ni tí ó ní gbogbo ofin Ọlọ́run, bí àwa, tí ó sì ré wọn kọjá, tí ó sì fi àwọn ọjọ́ ìdánwò rẹ̀ ṣòfò, nítorí búburú ni ipò rẹ̀!

28 A! ète àrékérekè ẹni búburú nì! A! asán, àti àìlera, àti ẹ̀gọ̀ àwọn ènìyàn! Nígbàtí wọ́n bá kọ́ ẹ̀kọ́ wọ́n rò pé àwọn gbọ́n, wọn kò sì ní fetísílẹ̀ sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run, nítorí wọ́n pa á tì, wọ́n ṣèbí wọn mọ́ ní tìkarãwọn, nítorí-èyi, ọgbọ́n wọn jẹ́ ẹ̀gọ̀ kò sì ṣe wọ́n ní ànfàní. Wọn yíò sì parun.

29 Ṣùgbọ́n láti kọ́ ẹ̀kọ́ dára bí wọ́n bá fetísílẹ̀ sí àwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run.

30 Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn ọlọ́rọ̀, tí wọ́n ní ọrọ̀ ní ti àwọn ohun ayé. Nítorí tí wọ́n ní ọrọ̀ wọn kẹ́gàn àwọn tálákà, wọ́n sì nṣe inúnibíni sí àwọn ọlọ́kàn tútù, ọkàn wọn sì wà lórí ìṣura wọn; nítorí-èyi, ìṣura wọn ni ọlọ́run wọn. Sì kíyèsĩ i, ìṣura wọn yíò parun pẹ̀lú wọn bakannã.

31 Ègbé sì ni fún adití tí kì yíò gbọ́ran; nítorí wọn yíò parun.

32 Ègbé ni fún afọ́jú tí kì yíò ríran; nítorí wọn yíò parun bakannã.

33 Ègbé ni fún aláìkọlà ní ọkàn, nítorí ìmọ̀ àwọn àìṣedẽdé wọn yíò lù wọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn.

34 Ègbé ni fún elékẽ, nítorí a ó sọ ọ́ sísàlẹ̀ sí ọ̀run àpãdì.

35 Ègbé ni fún apànìyàn tí ó mọ̃mọ̀ pani, nítorí òun yíò kú.

36 Ègbé ni fún àwọn tí ó nhu ìwà àgbèrè, nítorí a ó sọ wọ́n sísàlẹ̀ sí ọ̀run àpãdì.

37 Bẹ̃ni, ègbé ni fún àwọn wọnnì tí nsin àwọn òrìṣà, nítorí èṣù gbogbo àwọn èṣù nṣe inúdídùn sí wọn.

38 Àti, ní àkópọ̀, ègbé ni fún gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n kú sínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; nítorí wọn yíò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, wọn yíò sì kíyèsĩ ojú rẹ̀, wọn a sì wà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

39 A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ rántí bíburú ní rírékọjá sí Ọlọ́run Mímọ́, àti pẹ̀lú bíburú ìtũbá sí ẹ̀tàn ẹni àrékérekè nì. Ẹ rántí, láti ronú nípa ti ara jẹ́ ikú, láti ronú nípa ti ẹ̀mí sì jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.

40 A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Ẹ rántí títóbi Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Ẹ máṣe sọ pé mo ti sọ àwọn ohun líle sí yín; nítorí bí ẹ bá sọ ọ́, ẹ̀yin yíò kẹ́gàn sí òtítọ́; nítorí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dá yín. Èmi mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ le si gbogbo ìwà àìmọ́; ṣùgbọ́n àwọn olódodo kò bẹ̀rù wọn, nítorí wọ́n fẹ́ràn òtítọ́ wọn kò sì dãmú.

41 A! nígbànã, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ wá sọ́dọ̀ Olúwa, Ẹní Mímọ́ nì. Ẹ rántí pé àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ òdodo. Kíyèsĩ i, ọ̀nà fún ènìyàn jẹ́ tõró, ṣùgbọ́n ó lọ ní ipa ọ̀nà tàrà níwájú rẹ̀, olùpamọ́ ẹnu ọ̀nà nã sì ni Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, òun kò sì gba ìrànṣẹ́ kan sí iṣẹ́ níbẹ̀; kò sì sí ọ̀nà míràn àfi nípasẹ̀ ẹnu ọ̀nà òdè nã; nítorí a kò lè tàn án jẹ, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni orúkọ rẹ̀.

42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kànkùn, ni òun yíò ṣi-sílẹ̀ fún; àti àwọn ọlọgbọ́n, àti àwọn amòye, àti àwọn tí ó ní ọrọ̀, tí wọ́n nfẹ̀ sókè nítorí ti ẹ̀kọ́ wọn, àti ọgbọ́n wọn, àti ọrọ̀ wọn—bẹ̃ni, àwọn ni ẹni tí òun kẹ́gàn; àfi tí wọn yíò bá sì sọ àwọn ohun wọ̀nyí nù kúrò, tí wọ́n sì ro ara wọn wò bí aṣiwèrè níwájú Ọlọ́run, tí wọ́n sì wá sílẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ ìrẹ̀lẹ̀, òun kì yíò ṣi-sílẹ̀ fún wọn.

43 Ṣùgbọ́n àwọn ohun ti àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye ni a ó pamọ́ kuro lójú wọn títí láé—bẹ̃ní, àlãfíà nì èyí tí a pèsè fún àwọn ènìyàn mímọ́.

44 A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Kíyèsĩ i, èmi bọ́ àwọn ẹ̀wù mi, mo sì gbọ̀n wọ́n níwájú yín; mo gbàdúrà Ọlọ́run ìgbàlà mi kí ó síjúwò mí pẹ̀lú ojú ìwádĩ fífín rẹ̀; nítorí-èyi, ẹ̀yin yíò mọ̀ ní ọjọ́ ìkẹhìn, nígbàtí a ó ṣe ìdájọ́ fún gbogbo ènìyàn ní ti àwọn iṣẹ́ wọn, pé Ọlọ́run Isráẹ́lì jẹ́rĩ pé mo gbọn àwọn àìṣedẽdé yín kúrò ní ọkàn mi, àti pé mo dúró pẹ̀lú dídán níwájú rẹ̀, mo sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀jẹ̀ yín.

45 A! ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ yí kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín; ẹ gbọn àwọn ẹ̀wọ́n rẹ̀ kúrò tí yíò dè yín pinpin; ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run nì tí ó jẹ́ àpáta ìgbàlà yín.

46 Ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀ fún ọjọ́ ológo nì nígbàtí a ó pín àìṣègbè fún olódodo, àní ọjọ́ ìdájọ́, kí ẹ̀yin má bà á súnkì pẹ̀lú ìbẹ̀rù búburú; kí ẹ̀yin má bà á rántí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ búburú yín ní pípé, kí á sì fi agbára mú yín láti kígbe sókè: Mímọ́, mímọ́ ni àwọn ìdájọ́ rẹ, A! Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè—ṣùgbọ́n mo mọ́ ẹ̀bi mi; mo ré òfin rẹ kọjá, àwọn ìrékọjá mi sì jẹ́ tèmi; èṣù sì ti gbà mí, tí èmi jẹ́ ìkógun sí òṣí búburú rẹ̀.

47 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi, ó ha yẹ kí èmi kí ó jí yín sí òtítọ́ búburú àwọn ohun wọ̀nyí bí? Njẹ́ èmi yíò dá ọkàn yín lóró bí inú yín bá mọ́ bí? Njẹ́ èmi yíò ṣe kedere sí yín gẹ́gẹ́bí kedere ti òtítọ́ bí a bá sọ yín di òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí?

48 Kíyèsĩ i, bí ẹ̀yin bá jẹ́ mímọ́ èmi yíò bá a yín sọ̀rọ̀ nípa ìwà mímọ́; ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò ti jẹ́ mímọ́, tí ẹ̀yin sì nwò mí bí olùkọ́, kò lè ṣe àìyẹ kí èmi kí ó kọ́ yín ní ìgbẹ̀hìn ẹ̀ṣẹ̀.

49 Kíyèsĩ i, ọkàn mi kórìra ẹ̀ṣẹ̀, ọkàn mi sì yọ̀ ní òdodo; èmi yíò sì yin orúkọ mímọ́ Ọlọ́run mi.

50 Ẹ wá, ẹ̀yin arákùnrin mi, gbogbo ẹni tí npòùngbẹ, ẹ wá sí ibi àwọn omi; àti ẹni tí kò ní owó, ẹ wá rà kí ẹ sì jẹ; bẹ̃ni, ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìsí iye.

51 Nítorí-èyi, ẹ máṣe ná owó fún èyí nì tí kò ní ìtóye, tàbí ṣe lãlã fun èyí nì tí kò lè tẹ́ ni lọ́rùn. Ẹ fetísílẹ̀ lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sí mi, kí ẹ sì rántí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti sọ; kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, kí ẹ si jẹun lórí èyí tí kò lè parun, tabi tí kò lè bàjẹ́, ẹ sì jẹ́ kí ọkàn yín yọ̀ sí sísanra.

52 Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ gbàdúrà sí i léraléra nígbà ọ̀sán, kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀ nígba òru. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín yọ̀.

53 Sì kíyèsĩ bí májẹ̀mú Olúwa ti tóbi tó, àti bí ìrẹ̀lè rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn ti tóbi to; àti nítorí títóbi rẹ̀, àti õre-ọ̀fẹ́ àti ãnú rẹ̀, ó ti ṣe ìlérí fún wa pé a kò ní pa irú-ọmọ wa run pátápátá, gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara, ṣùgbọ́n pé òun yíò pa wọ́n mọ́; ní ìrandíran ìgbà tí mbọ̀ wọn yíò sì di ẹ̀ká ólódodo ti ará ilé Isráẹ́lì.

54 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi yíò bá a yín sọ̀rọ̀ si; ṣùgbọ́n ní ọ̀la èmi yíò sọ ìyókù àwọn ọ̀rọ̀ mi fún yín. Àmín.