Ori 8
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, Olúwa yíò tu Síónì nínú yíò sì kó Isráẹ́lì jọ—Àwọn tí a ràpadà yíò wá sí Síónì lãrín ayọ̀ nla—Fi Isaiah 51 àti 52:1–2 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Gbọ́ ti èmi, ẹ̀yin tí ntẹ̀lé òdodo. Wo àpáta nì nínú èyí tí a ti gbẹ́ yín, àti ihò kòtò nì láti ibi tí a gbé ti wà yín.
2 Ẹ wo Ábráhámù, bàbá yín, àti Sárà, òun tí ó bí yín; nítorí òun nìkan ni mo pè, mo sì súre fún un.
3 Nítorí Olúwa yíò tu Síónì nínú, òun yíò tu gbogbo ibi òfò rẹ̀ nínú; òun yíò sì ṣe aginjù rẹ̀ bí Édẹ́nì, àti asálẹ̀ rẹ̀ bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inúdídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ìdúpẹ́ àti ohùn orin.
4 Tẹ́tílélẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi, sì fi etí sí mi, A! orílẹ̀-èdè mi; nítorí òfin kan yíò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá, èmi yíò sì gbé ìdájọ́ mi kalẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn.
5 Òdodo mi wà nítòsí; ìgbàlà mi ti jáde lọ, apá mi yíò sì ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Àwọn erékùsù yíò dúró dè mí, apá mi ni wọn yíò sì gbẹ́kẹ̀lé.
6 Ẹ gbé ojú yín sókè sí àwọn ọrun, kí ẹ sì wo ayé nísàlẹ̀; nítorí àwọn ọ̀run yíò fẹ́ lọ bí ẽfín, ayé yíò sì di ogbó bí ẹ̀wù; àwọn tí ngbé inú rẹ̀ yíò sì kú bákannã. Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yíò wà títí láé, òdodo mi kì yíò sì parẹ́.
7 Gbọ́ ti èmi, ẹ́yin tí ó mọ́ òdodo, ènìyàn nínú àyà ẹnití mo ti kọ òfin mi sí, ẹ máṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn, ẹ má sì ṣe fòyà ẹ̀sín wọn.
8 Nítorí kòkòrò yíò jẹ wọ́n bí ẹ̀wù, ìdin yíò sì jẹ wọ́n bí irun àgùtàn. Ṣùgbọ́n òdodo mi yíò wà títí lae, àti ìgbàlà mi láti ìran dé ìran.
9 Jí, jí! Gbé agbára wọ̀, A! apá Olúwa; jí bí ní ọjọ́ ìgbanì. Ìwọ ha kọ́ ni ó gé Ráhábù, tí ó sì ṣá drágónì ní ọgbẹ́?
10 Ìwọ ha kọ́ ni ó gbẹ òkun, omi ibú nlá wọnnì; tí ó ti sọ àwọn ibú òkun di ọ̀nà fún àwọn ìràpadà láti gbà kọjá?
11 Nítorínã, àwọn ẹni-ìràpada Olúwa yíò padà, wọn ó sì wá pẹ̀lú orin kíkọ sí Síónì; ayọ̀ àìnípẹ̀kun àti ìwà mímọ́ yíò sì wà ní orí wọn; wọn yíò sì rí inúdídùn àti ayọ̀ gbà; ìrora-ọkàn àti ọ̀fọ̀ yíò fò lọ.
12 Èmi ni òun; bẹ̃ni, èmi ni ẹni tí ntù yín nínú. Kíyèsĩ i, tani ìwọ, tí ìwọ fi bẹ̀rù ènìyàn, ẹni tí yíò kú, àti ti ọmọ ènìyàn, tí a ó ṣe bí koríko?
13 Tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́da rẹ, tí ó ti na àwọn ọ̀run jádewá, tí ó sì ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ìwọ sì ti nbẹ̀rù nígbà-gbogbo lójojúmọ́, nítorí ìrúnú aninilára nì, bí ẹnipé ó ti múra láti panirun? Níbo sì ni ìrúnú aninilára nã ha gbé wà?
14 Òndè tí a ti ṣí nípò yára, ki a bá lè tú u sílẹ̀, àti kí ó má bà kú sínú ihò, tàbí kí oúnjẹ rẹ̀ má bà tán.
15 Ṣùgbọ́n èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ìgbì rẹ̀ hó; Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni orúkọ mi.
16 Èmi sì ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ, mo sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀ ní òjìji ọwọ́ mi, kí èmi kí ó lè gbin àwọn ọ̀run kí èmi sì lè fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, àti kí èmi lè wí fún Síónì pé: Kíyèsĩ i, ìwọ ni ènìyàn mi.
17 Jí, jí, dìde dúró, A! Jerúsálẹ́mù, tí ó ti mu ní ọwọ́ Olúwa ago ìrúnú rẹ̀—ìwọ ti mu gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ago tí ìwárìrì fọn jáde—
18 Kò sì sí ẹnìkan láti tọ́ ọ nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó bí; bẹ̃ni tí ó fà á lọ́wọ́, nínú gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí òun tọ́ dàgbà.
19 Àwọn ọmọkùnrin méjì wọ̀nyí ni ó wá sọ́dọ̀ rẹ, tani yíò kãnú fún ọ—ìdáhóró àti ìparun rẹ, àti ìyàn àti idà—nípa tani èmi yíò sì tù ọ́ nínú?
20 Àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin ti dákú, àfi àwọn méjì wọ̀nyí; wọ́n dùbúlẹ̀ ní gbogbo ìkóríta; bí ẹfọ̀n nínú àwọn, wọ́n kún fún ìrúnú Olúwa, ìbáwí Ọlọ́run rẹ.
21 Nítorínã gbọ́ èyí ná, ìwọ ẹni tí a pọ́n lójú, tí ó sì mu àmuyó, tí kì í sì ṣe nípa ọtí-wáínì:
22 Báyĩ ni Olúwa rẹ wí, Olúwa àti Ọlọ́run rẹ nṣìpẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀; kíyèsĩ i, èmi ti gba ago ìwárìrì kúrò lọ́wọ́ rẹ, gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ago ìrúnú mi; ìwọ kì yíò tún mu ú mọ́.
23 Ṣùgbọ́n èmi ó fi í sí ọwọ́ àwọn tí ó pọ́n ọ lójú; tí wọ́n ti wí fún ọkàn rẹ pé: Wólẹ̀, kí a bá lè rékọjá—ìwọ sì ti tẹ́ ara rẹ sílẹ̀ bí ilẹ̀ àti bí ìta fún àwọn tí ó rékọjá.
24 Jí, jí, gbé agbára rẹ wọ̀, A! Síónì; gbé aṣọ arẹwà rẹ wọ̀, A! Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ nã; nítorí láti ìgbà yí lọ aláìkọlà àti aláìmọ́ kì yíò wọ inú rẹ mọ́.
25 Gbọn ekuru kúrò ní ara rẹ; dìde, jóko, A! Jerúsálẹ́mù; tú ara rẹ kúrò nínú ìdè ọrùn rẹ, A! òndè ọmọbìnrin Síónì.