Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 3


Ori 3

Jósẹ́fù ní Égíptì rí àwọn ará Nífáì nínú ìran—Ó sọtẹ́lẹ̀ nípa Joseph Smith, aríran tí ọjọ́ ìkẹhìn; nípa Mósè, ẹni tí yíò gba Isráẹ́lì sílẹ̀; àti nípa jíjáde wá Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí mo wí fún ọ, Jósẹ́fù, àbígbẹ̀hìn mi. A bí ọ ní ijù àwọn ìpọ́njú mi; bẹ̃ni, ní àwọn ọjọ́ ìrora-ọkàn mi tí ó pọ̀ jùlọ ni ìyá rẹ bí ọ.

2 Kí Olúwa sì ya ilẹ̀ yí sí mímọ́ fún ọ pẹ̀lú, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ iyebíye jùlọ, fún ìní rẹ àti ìní irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ, fún ãbo rẹ títí láé, bí ó bá ṣe pé ẹ̀yin yíò pa àwọn òfin Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì mọ́.

3 Àti nísisìyí, Jósẹ́fù, àbígbẹ̀hìn mi, ẹni tí mo ti mú jáde kúrò ní ijù àwọn ìpọ́njú mi, kí Olúwa kí ó bùkún ọ títí láé, irú-ọmọ rẹ ni a kì yíò parun pátápátá.

4 Nítorí kíyèsĩ i, ìwọ ni irú-ọmọ inú mi; èmi sì jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù ẹni tí a gbé ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Égíptì. Nlá sì ni àwọn májẹ̀mú Olúwa èyí tí ó ṣe sí Jósẹ́fù.

5 Nítorí-èyi, Jósẹ́fù rí ọjọ́ wa nítõtọ́. Ó sì gba ìlérí Olúwa, pé lára irú-ọmọ inú rẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yíò gbé ẹ̀ká ódodo kan sókè sí ará ilé Isráẹ́lì; kì í ṣe Messia nã, ṣùgbọ́n ẹ̀ká éyí tí a ó ṣẹ́ kúrò, bíótilẹ̀ríbẹ̃, tí a ó rántí ni àwọn májẹ̀mú Olúwa pé a ó fi Messia nã hàn sí wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, ní ẹ̀mí agbára, sí mímú wọn jáde kúrò ní òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀—bẹ̃ni, kúrò ní òkùnkùn tí ó pamọ́ àti kúrò ní ìgbèkùn sí òmìnira.

6 Nítorí Jósẹ́fù jẹ́rĩ nítõtọ́, wípé: Aríran kan ni Olúwa Ọlọ́run mi yíò gbé sókè, ẹni tí yíò jẹ́ àṣàyàn aríran sí irú-ọmọ inú mi.

7 Bẹ̃ni, Jósẹ́fù sọ nítõtọ́ pé: Báyĩ ní Olúwa wí fún mi: Àṣàyàn aríran kan ni èmi yíò gbé sókè lára irú-ọmọ inú rẹ; a ó sì gbé e níyì ga lãrín irú-ọmọ inú rẹ. Àti sí òun ni èmi yíò sì fi òfin fún pé òun yíò ṣe iṣẹ́ kan fún irú-ọmọ inú rẹ, àwọn arákùnrin rẹ̀, èyí tí yíò jẹ́ iye nlá sí wọn, àní sí mímú wọn wá sí ìmọ̀ àwọn májẹ̀mú èyí tí mo ti ṣe pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ.

8 Èmi yíò sì fi òfin kan fún un pé òun kì yíò ṣe iṣẹ́ míràn, àfi iṣẹ́ èyí tí èmi yíò pàṣẹ fún un. Èmi yíò sì ṣe é ní títóbi ní ojú mi; nítorí òun yíò ṣe iṣẹ mi.

9 Òun yíò sì jẹ́ ẹni nlá bí ti Mósè, ẹni tí mo ti sọ pé èmi yíò gbé sókè sí ọ, láti gba àwọn ènìyàn mi là, A! ará ilé Isráẹ́lì.

10 Mósè sì ni èmi yíò gbé sókè, láti gba àwọn ènìyàn rẹ là kúrò ní ilẹ̀ Égíptì.

11 Ṣùgbọ́n aríran kan ni èmi yíò gbé sókè láti irú-ọmọ inú rẹ; òun sì ni èmi yíò fi agbára fún láti mú ọ̀rọ̀ mi jáde wá fún irú-ọmọ rẹ—kò sì jẹ́ sí mímú ọ̀rọ̀ mi jáde wá nìkan, ni Olúwa wí, ṣùgbọ́n sí fífi òye ọ̀rọ̀ mi yé wọn, èyí tí yíò ti jáde lọ ṣíwajú lãrín wọn.

12 Nítorí-èyi, irú-ọmọ inú rẹ yíò kọ̀wé; irú-ọmọ inú Júdà nã yíò sì kọ̀wé; àti èyí tí a ó sì kọ nípa ọwọ́ irú-ọmọ inú rẹ, àti pẹ̀lú èyí tí a ó kọ nípa ọwọ́ irú-ọmọ Júdà, yíò jùmọ̀ dàgbà, sí dídãmú àwọn ayédèrú ẹ̀kọ́ àtí títú ìjà ká, àti fífi àlãfíà lalẹ̀ lãrín irú-ọmọ inú rẹ, àti mímú wọn wá sí ìmọ̀ àwọn baba wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, àti pẹ̀lú sí ìmọ̀ májẹ̀mú mi, ni Olúwa wí.

13 Àti nínú àìlera ni a ó sì sọ ọ́ di alágbára, ní ọjọ́ nã ti iṣẹ́ mi yíò bẹ̀rẹ̀ lãrín gbogbo àwọn ènìyàn mi, sí mímú ọ padà sípò, A! ará ilé Isráẹ́lì, ni Olúwa wí.

14 Báyĩ sì ni Jósẹ́fù sọtẹ́lẹ̀, wípé: Kíyèsĩ, aríran nì ni Olúwa yíò bùkún fun; àwọn tí ó bá sì nwá láti pa á run ni a ó parun; nítorí ìlérí yí, èyí tí mo ti gbà lọ́wọ́ Olúwa, níti irú-ọmọ inú mi, ni a ó mú ṣẹ. Kíyèsĩ, mímú ìlérí yí ṣẹ dá mi lójú;

15 Orúkọ mi ni a ó sì fi pè é; yíò sì jẹ̃ tẹ̀lé orúkọ bàbá rẹ̀. Òun yíò sì rí bí èmi; fún ohun nã, èyí tí Olúwa yíò mú jáde wá nípa ọwọ́ rẹ̀, nípasẹ̀ agbára Olúwa yíò mú àwọn ènìyàn mi wá sí ìgbàlà.

16 Bẹ̃ni, báyĩ ni Jósẹ́fù sọtẹ́lẹ̀: Mo ni idánilójú nípa nkan yí, àní bí mo ṣe ni idánilójú ìlérí ti Mósè; nítorí Olúwa ti wí fún mi, èmi yíò pa irú-ọmọ rẹ mọ́ títí láé.

17 Olúwa sì ti wípé: Èmi yíò gbé Mósè kan dìde; èmi yíò sì fi agbára fún un nínú ọ̀pá kan; èmi yíò sì fi ìdájọ́ fún un ní ìkọ̀wé. Síbẹ̀ èmi kì yíò tú ahọ́n rẹ̀ sílẹ̀, tí yíò sọ̀rọ̀ púpọ̀, nítorí èmi kì yíò ṣe é ní alágbára ní sísọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n èmi yíò kọ òfin mi fún un, nípa ìka ọwọ́ tèmi; èmi yíò sì pèsè agbọ̀rọ̀sọ kan fún un.

18 Olúwa sì wí fún mí pẹ̀lú pé: èmi yíò gbé dìde sí irú-ọmọ inú rẹ; èmi yíò sì pèsè agbọ̀rọ̀sọ kan fun un. Èmi, kíyèsĩ i, èmi yíò sì fi fún un wipe oun yíò kọ ìwé irú-ọmọ inú rẹ, sí irú-ọmọ inú rẹ; agbọ̀rọ̀sọ irú-ọmọ inú rẹ nã yíò sì kéde rẹ̀.

19 Àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí òun yíò sì kọ yíò jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí ó jẹ́ yíyẹ ní òye mi kí ó jáde lọ sí irú-ọmọ inú rẹ. Yíò sì dàbí ẹnipé irú-ọmọ inú rẹ ti kígbe sí wọn láti inú erùpẹ̀ wá; nítorí mo mọ́ ìgbàgbọ́ wọn.

20 Wọn yíò sì kígbe láti inú erùpẹ̀ wá; bẹ̃ni, àní ìrònúpìwàdà sí àwọn arákùnrin wọn, àní lẹ́hìn tí ìrandíran púpọ̀ ti lọ nípasẹ̀ wọn. Yíò sì ṣe tí igbe wọn yíò lọ, àní gẹ́gẹ́bí ìdẹ̀rùn àwọn ọ̀rọ̀ wọn.

21 Nítorí ìgbàgbọ́ wọn àwọn ọ̀rọ̀ wọn yíò jáde láti ẹnu mi wá sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ inú rẹ; àìlágbára àwọn ọ̀rọ̀ wọn sì ni èmi yíò mú lágbára nínú ìgbàgbọ́ wọn, sí rírántí májẹ̀mú mi èyí tí mo ṣe pẹ̀lú àwọn bàbá yín.

22 Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, ọmọ mi Jósẹ́fù, gẹgẹ báyĩ ni bàbá mi ti ìgbà àtijọ́ sọtẹ́lẹ̀.

23 Nítorí-èyi, nítorí ti májẹ̀mú yí, ìwọ jẹ́ alábùkún fún; nítorí a kì yíò pa irú-ọmọ rẹ run, nítorí wọn yíò fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ ìwé nã.

24 Alágbára kan ni a ó sì gbé dìde lãrín wọn, ẹni tí yíò ṣe rere púpọ̀, àti ní ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe, tí yíò jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ó tayọ, láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó lágbára, àti láti ṣe ohun nì èyí tí ó jẹ́ títóbi ní ojú Ọlọ́run, sí mímú láti ṣe ìmúpadà sípò sí ará ilé Isráẹ́lì, àti sí irú-ọmọ àwọn arákùnrin rẹ.

25 Àti nísisìyí, alábùkún fún ni ìwọ, Jósẹ́fù. Kíyèsĩ i, ìwọ kéré; nítorí-èyi fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ arákùnrin rẹ, Nífáì, a ó sì ṣe é sí ọ àní gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti sọ. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ bàbá rẹ tí o nkú lọ. Àmín.