Ori 12
Isaiah rí tẹ́mpìlì ìgbà-ìkẹhìn, kíkójọ Isráẹ́lì, àti ìdájọ́ òun àlãfíà ti ẹgbẹ̀rún ọdún—Àwọn onígberaga àti àwọn oníwà-búburú ni a ó fà wá sílẹ̀ ní Bíbọ̀ Èkejì–Fi Isaiah 2 wé é. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Ọ̀rọ̀ tí Isaiah, ọmọkùnrin Ámós, rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù:
2 Yíò sì ṣe ní àwọn ìgbà ìkẹhìn, nígbàtí a ó fi òkè ilé Olúwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè nlá, a ó sì gbée ga ju àwọn òkè kékèké lọ; gbogbo orílẹ̀-èdè ni yíò sì wọ́ sí inú rẹ̀.
3 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yíò sì lọ wọn ó sì wí pé, Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí á lọ sí òkè Olúwa, sí ilé Ọlọ́run Jákọ́bù; òun yíò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, àwa yíò sì ma rìn ní ipa rẹ̀; nítorí láti Síónì ni òfin yíò ti jáde lọ, àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerúsálẹ́mù.
4 Òun yíò sì ṣe ìdájọ́ lãrín àwọn orílẹ̀-èdè, yíò sì bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wí: wọn yíò sì fi idà wọn rọ irin ọrọ̀ ìtulẹ̀, àti ọ̀kọ̀ wọn sí dòjé—orílẹ̀-èdè kì yíò gbé idà sókè sí orílè-èdè, bẹ́ni wọn kì yíò kọ́ ogun jíjà mọ́.
5 A! ará ilé Jákọ́bù, ẹ wá ẹ sì jẹ́ kí á rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa; bẹ̃ni, ẹ wá, nítorí gbogbo yín ti ṣìnà, olúkúlùkù yín sí àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀.
6 Nítorínã, A! Olúwa, ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, ilé Jákọ́bù, nítorí tí wọ́n kún láti ìlà-oòrùn wá, wọ́n sì fetísílẹ̀ sí aláfọ̀ṣẹ bí àwọn ará Filístínì, wọ́n sì n ṣe inú dídùn nínú àwọn ọmọ àlejò.
7 Ilẹ̀ wọn pẹ̀lú kún fún fàdákà àti wúrà, bẹ̃ni kò sí òpin fún àwọn ìṣura wọn; ilẹ̀ wọn kún fún ẹṣin pẹ̀lú, bẹ̃ni kò sí òpin fún àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn.
8 Ilẹ̀ wọn kún fún àwọn òrìṣà pẹ̀lú; wọ́n nbọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn, èyí nì tí ìka àwọn tìkarawọn ti ṣe.
9 Ènìyàn lásán kò sì foríbalẹ̀, ẹni nlá kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, nítorínã, má ṣe dáríjì í.
10 A! ẹ̀yin ẹni búburú, ẹ wọ inú àpáta lọ, kí ẹ sì fi ara yín pamọ́ nínú ekuru, nítorí ìbẹ̀rù Olúwa àti ògo ọlánlá rẹ yíò lù yín.
11 Yíò sì ṣe tí a ó rẹ ìwọ gíga ènìyàn sílẹ̀, a ó sì tẹ orí ìgbéraga ènìyàn bá, Olúwa nìkanṣoṣo ni a ó sì gbé ga ní ọjọ́ nã.
12 Nítorí ọjọ́ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun yíò wá láìpẹ́ sí órí orílẹ̀-èdè gbogbo, bẹ̃ni, sí órí olúkúlùkù; bẹ̃ni, sí órí ẹni tí o réra àti tí ó sì gbéraga, àti sórí olúkúlùkù ẹni tí a gbé sókè, òun ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀.
13 Bẹ̃ni, ọjọ́ Olúwa yíò wá sí órí gbogbo igi kédárì Lébánọ́nì, nítorí wọ́n ga a sì gbé wọn sókè; àti sórí gbogbo igi-nlá Báṣánì;
14 Àti sí órí gbogbo òkè gíga, àti sí órí gbogbo òkè kékèké, àti sí órí gbogbo orílẹ̀-èdè tí a gbé sókè, àti sí órí olúkúlùkù ènìyàn;
15 Àti sí órí gbogbo ilé-ìṣọ́ gíga, àti sí órí gbogbo odi;
16 Àti sí órí gbogbo ọkọ̀ òkun, àti sí órí gbogbo ọkọ̀ Tarṣíṣì, àti sí órí gbogbo àwòrán tí ó wuni.
17 A ó sì tẹ orí ìgbéraga ènìyàn balẹ̀, ìréra àwọn ènìyàn ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀; Olúwa nìkanṣoṣo ni a ó sì gbéga ní ọjọ́ nã.
18 Àwọn òrìṣà ni òun yíò sì parẹ́ pátápátá.
19 Wọn yíò sì wọ inú ihò àwọn àpáta lọ, àti inú ihò ilẹ̀, nítorí ìbẹ̀rù Olúwa yíò wá sí órí wọn ògo ọlánlá rẹ̀ yíò sì lù wọ́n, nígbàtí ó bá dìde láti mi ilẹ̀ ayé kìjikìji.
20 Ní ọjọ́ nã ènìyàn yíò ju àwọn òrìṣà fàdákà rẹ̀, àti àwọn òrìṣà wúrà rẹ̀, èyí tí ó ti ṣe fún ara rẹ̀ láti máa bọ, sí àwọn èkúté àti sí àwọn àdán;
21 Láti lọ sínú àwọn pàlàpálá àpáta, àti sókè àpáta sísán, nítorí ìbẹ̀rù Olúwa yíò wá sí órí wọn ọlánlá ògo rẹ̀ yíò sì lù wọ́n, nígbàtí ó bá dìde láti mi ilẹ̀ ayé kìjikìji.
22 Ẹ simi lẹ́hìn ènìyàn, ẹ̀mí ẹni tí ó wà ní ihò imú rẹ̀; nítorí nínú kíni a lè kà á sí?