Ori 14
Síóni àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ni a ó ràpadà tí a ó sì wẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ ti ẹgbẹ̀rún ọdún—Fi Isaiah 4 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Àti ní ọjọ́ nã, obìnrin méje yíò dìmọ́ ọkùnrin kan, wípé: Àwa ó jẹ oúnjẹ ara wa, àwa ó sì wọ aṣọ ara wa; Jẹ́ kí á fi orúkọ rẹ pè wá nìkan láti mú ẹ̀gàn wa kúrò.
2 Ní ọjọ́ nã ni ẹ̀ka Olúwa yíò ní ẹwà tí yíò sì lógo; èso ilẹ̀ yíò ní ọlá yíò sì dára fún àwọn tí ó sálà ní Isráẹ́lì.
3 Yíò sì ṣe, pé, àwọn tí a fi sílẹ̀ ní Síónì tí wọ́n sì kù ní Jerúsálẹ́mù ní a ó pè ní mímọ́, olúkúlùkù ẹni tí a kọ pẹ̀lú àwọn alãyè ní Jerúsálẹ́mù—
4 Nígbàtí Olúwa bá ti wẹ ẹ̀gbin àwọn ọmọbìnrin Síónì nù, tí ó sì ti fọ ẹ̀jẹ̀ Jerúsálẹ́mù kúrò ní ãrín rẹ̀ nípa ẹ̀mí ìdájọ́ àti nípa ẹ̀mí ìjóná.
5 Olúwa yíò sì dá, awọsanma àti ẽfín ní ọ̀sán àti dídán ọ̀wọ́ iná ní òru; ní órí olúkúlùkù ibùgbé òkè Síónì, àti ní órí àwọn àpèjọ rẹ̀, nítorí lórí gbogbo ògo Síónì ni àbò yíò wà.
6 Àgọ́ kan yíò sì wà fún òjìji ní ọ̀sán kúrò nínú õru, àti fún ibi ìsásí, àti fún ãbò kúrò nínú ìjì àti kúrò nínú òjò.