Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 18


Ori 18

Krístì yíò jẹ́ bí òkúta ìkọsẹ̀ àti àpáta ẹ̀ṣẹ̀—Ẹ wá Olúwa, kí ì ṣe àwọn oníyọjúsí àjẹ́—Ẹ yí padà sí òfin àti sí ẹ̀rí fun ìtọ́nà—Fi Isaiah 8 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ọ̀rọ̀ Olúwa wí fún mi pé: Ìwọ mú ìwé nlá kan, kí o sì kọ̀wé sí inú rẹ̀ pẹ̀lú kálámù ènìyàn, níti Maher-ṣàlál-hàṣ-básì.

2 Èmi sì mú àwọn ẹlẹ́rĩ òtítọ́ sọ́dọ̀ mi láti ṣe ẹlẹ́rĩ, Ùríah àlùfã, àti Sekeríah ọmọkùnrin Jeberekíah.

3 Mo sì wọlé tọ wòlĩ obìnrin nì lọ; ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbànã ni Olúwa wí fún mi pé: Sọ orúkọ rẹ̀ ní, Maher-ṣàlál-hàṣ-básì.

4 Nítorí kíyèsĩ i, ọmọ nã kì yíò ní òye láti ké, Bàbá mi, àti ìyá mi, kí a tó mú ọrọ̀ Damáskù àti ìkógun Samáríà kúrò níwájú ọba Assíríà.

5 Olúwa sì tún wí fún mi, wípé:

6 Níwọ̀n bí ènìyàn yí ti kọ omi Ṣílóà tí nṣàn jẹ́jẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì nyọ̀ nínú Résínì àti ọmọkùnrin Remalíàh.

7 Njẹ́ nítorínã, kíyèsĩ i, Olúwa nfà awọn omi odò wá sórí wọn, tí ó le tí ó sì pọ̀, àní ọba Assíríà àti gbogbo ògo rẹ̀; òun yíò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀, yíò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀.

8 Òun yíò sì kọjá ní ãrin Júdà; yíò ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yíò sì mù ú dé ọrùn; nína ìyẹ́ rẹ̀ yíò sì kún ìbú ilẹ̀ rẹ, A! Immánúẹ́lì.

9 Ẹ kó ara yín jọ, A! ẹ̀yin ènìyàn, a ó sì fọ́ yín tũtú; ẹ sì fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ará orílẹ̀ èdè jíjìnà; ẹ di ara yín ní àmùrè, a ó sì fọ́ yín tũtú; ẹ di ara yín ní àmùrè, a ó sì fọ́ yín tũtú.

10 Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yíò sì di asán; ẹ sọ̀rọ̀ nã, kì yíò sì dúró; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.

11 Nítorí Olúwa wí báyĩ í fún mi pẹ̀lú ọwọ́ agbára, ó sì kọ́ mi kí nmá rìn ní ọ̀nà ènìyàn yí, wípé:

12 Ẹ máṣe sọ pé, Ìdìmọ̀, sí gbogbo awọn tí àwọn ènìyàn yí yio sọ pé, Ìdìmọ̀; bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀rù ìbẹ̀rù wọn, ẹ má sì ṣe fòyà.

13 Ya Olúwa àwọn Ọmọ-ogun tìkararẹ̀ sí mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ kí ó jẹ ìbẹ̀rù yín, sì jẹ́ kí ó ṣe ìfòyà yín.

14 Òun yíò sì wà fún ibi mímọ́; ṣùgbọ́n fún òkúta ìdìgbòlù, àti fún àpáta ẹ̀ṣẹ̀ sí ilé Isráẹ́lì méjẽjì, fún ẹgẹ́ àti okùn dídẹ sí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.

15 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn yíò sì kọsẹ̀ wọn yíò sì ṣubú, a ó sì fọ́ wọn, a ó sì dẹ okùn fún wọn, a ó sì mú wọn.

16 Di ẹ̀rí nã, fi èdìdì di òfin nã lãrín àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mi.

17 Èmi yíò sì dúró de Olúwa, tí o pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò lára ilé Jákọ́bù, èmi ó sì wã.

18 Kíyèsĩ i, èmi àti àwọn ọmọ tí Olúwa ti fi fún mi wà fún iṣẹ́ àmì àti fún iṣẹ́ ìyanu ní Isráẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wá, tí ngbé Òkè Síónì.

19 Nígbàtí wọ́n yíò bá sì wí fún yín pe: Ẹ wá àwọn ẹ̀mí tí nbá òkú lò, àti àwọn oṣó tí nké tí nsì nkùn—kò ha yẹ kí orílẹ̀-èdè kí ó wá Ọlọ́run wọn ju ki àwọn alãyè ma gbọ́ láti ọ̀dọ̀ òkú bí?

20 Sí òfin àti sí ẹ̀rí; bí wọn kò bá sì sọ gẹ́gẹ́bí ọrọ̀ yí, ó jẹ́ nítorípé kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú wọn.

21 Wọn yíò sì kọjá lãrín rẹ̀ nínú ìnilára àti ebi; yíò sì ṣe pé nígbàtí ebi yíò pa wọ́n, wọn yíò ma kanra, wọn yíò sì fi ọba wọn àti Ọlọ́run wọn ré, wọn yíò sì ma wo òkè.

22 Wọn yíò sì wo ilẹ̀ wọn yíò sì kíyèsĩ ìyọnu, àti òkùnkùn, ìṣújú ítorí àròkàn, a ó sì lé wọn lọ sínú òkùnkùn.

Tẹ̀