Ori 29
Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn Kèfèrí ni yíò kọ Ìwé ti Mọ́mọ́nì sílẹ̀—Wọn yíò wípé, Àwa kò fẹ́ Bíbélì mọ́—Olúwa bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀—Òun yíò ṣe ìdájọ́ fún ayé láti inú àwọn ìwé èyí tí a ó kọ. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, ọ̀pọ̀ ni yíò wà—ni ọ̀jọ́ nã nígbàtí èmi yíò tẹ̀ síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín wọn, kí èmi lè rántí àwọn májẹ̀mú mi èyí tí mo ti ṣe sí àwọn ọmọ ènìyàn, kí èmi lè tún mú ọwọ́ mi ní ìgbà kejì láti gba àwọn ènìyàn mi padà, tí wọ́n jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì;
2 Àti pẹ̀lú, kí èmi lè rántí àwọn ìlérí èyí tí mo ti ṣe sí ọ, Nífáì, àti pẹ̀lú sí bàbá rẹ, pé èmi yíò rántí irú-ọmọ rẹ; àti pé àwọn ọ̀rọ̀ irú ọmọ rẹ yíò tẹ̀ jáde lọ láti ẹnu mi sí irú ọmọ rẹ; àwọn ọ̀rọ̀ mi yíò sì kọ jáde títí dé ikangun ayé, fún ọ̀págun sí àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì;
3 Àti nítorí àwọn ọ̀rọ̀ mi yíò kọ jáde—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Kèfèrí yíò wípé: Bíbélì kan! Bíbélì kan! Àwa ti ní Bíbélì kan, kò sì lè sí Bíbélì èyíkeyí mọ́.
4 Ṣùgbọ́n báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: A! àwọn aṣiwèrè, wọn yíò ní Bíbélì kan; yíò sì jáde wá láti ọ̀dọ̀ àwọn Jũ, àwọn ènìyàn mi àtijọ́ tí mo bá dá májẹ̀mú. Wọ́n ha dúpẹ́ fún àwọn Jũ fún Bíbélì èyí tí wọ́n gbà láti ọ̀dọ̀ wọn? Bẹ̃ni, kíni àwọn Kèfèrí rò? Njẹ́ wọn rántí àwọn lãlã, àti ìṣẹ́, àti ìrora àwọn Jũ, àti ãpọn wọn sí mi, ní mímú ìgbàlà jáde wá sí àwọn Kèfèrí bí?
5 A! ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ̀yin ha ti rántí àwọn Jũ, àwọn ènìyàn mi àtijọ́ tí mo bá dá májẹ̀mú bí? Rárá; ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fi wọ́n bú, tí ẹ sì ti kórìra wọn ẹ kò sì tí ì wá láti mú wọn padà. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi yíò dá gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí padà sórí ara yín; nítorí èmi Olúwa kò ì tí ì gbàgbé àwọn ènìyàn mi.
6 Ẹ̀yin aṣiwèrè, tí yíò wípé: Bíbélì kan, àwa ti ní Bíbélì kan, àwa kò fẹ́ Bíbélì si i. Ẹ̀yin ha ti rí Bíbélì gbà bíkòṣe nípasẹ̀ àwọn Jũ?
7 Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé orílẹ̀-èdè wà ju ọ̀kan lọ? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé èmi, Olúwa Ọlọ́run yín, ti dá gbogbo ènìyàn, àti pe èmi rántí àwọn wọnnì tí ó wà lórí erékùṣù òkun; àti pe mo jọba ní òkè ọ̀run àti nísàlẹ̀ ilẹ̀; èmi sì mú ọ̀rọ̀ mi jáde wá sí àwọn ọmọ ènìyàn, bẹ̃ni, àní sí órí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé?
8 Èéṣe tí ẹ̀yin fi nkùn, nítorí tí ẹ̀yin yíò gba ọ̀rọ̀ mí sĩ? Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé ẹ̀rí orílẹ̀-èdè méjì jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé èmi ni Ọlọ́run, pé mo rántí orílẹ̀-èdè kan bí ti òmíràn? Nítorí-èyi, mo sọ àwọn ọ̀rọ̀ kannã sí orílẹ̀-èdè kan bí ti òmíràn. Nígbàtí àwọn orílẹ̀-èdè méjẽjì yíò sì péjọ ẹ̀rí àwọn orílẹ̀-èdè méjẽjì yíò péjọ pẹ̀lú.
9 Èmi sì ṣe èyí kí èmi lè fihàn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ pé èmi jẹ́ ọ̀kannã ní àná, ní òní, àti títí lae; àti pé èmi sọ àwọn ọ̀rọ̀ mi jáde gẹ́gẹ́bí inú dídùn tèmi. Nítorí tí mo sì ti sọ ọ̀rọ̀ kan kò yẹ́ kí ẹ̀ ṣebí pé èmi kò lè sọ òmíràn; nítorí iṣẹ́ mi kò ì tí ì parí síbẹ̀; bẹ̃ni kì yíò rí bẹ̃ títí òpin ènìyàn, bẹ̃ni kì í sì ṣe láti ìgbà nã lọ àti títí láé.
10 Nítorí-èyi, nítorí tí ẹ̀yin ní Bíbélì kan kò yẹ kí ẹ̀yin ṣebí pé ó ní gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú; bẹ̃ni kò yẹ kí ẹ ṣebí pé nkò ti mú kí á kọ sí i.
11 Nítorí mo pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn, àti ní ìlà-oòrùn àti ní ìwọ̀-oòrùn, àti ní àríwà, àti ní gũsù, àti ní àwọn erékùṣù òkun, pé wọn yíò kọ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo sọ sí wọn; nítorí láti inú àwọn ìwé èyí tí a ó kọ ni èmi yíò ṣe ìdájọ́ fún ayé, olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí àwọn iṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́bí àwọn èyí tí a kọ.
12 Nítorí kíyèsĩ i, èmi yíò bá àwọn Jũ sọ̀rọ̀ wọn yíò sì kọ ọ́; èmi yíò sì bá àwọn ará Nífáì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn yíò sì kọ ọ́; èmi yíò sì bá àwọn ẹ̀yà ará ilé Isráẹ́lì míràn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú, tí mo ti tọ́ kúrò lọ wọn yíò sì kọ ọ́; èmi yíò sì bá gbogbo orílẹ̀-èdè àgbáyé sọ̀rọ̀ wọn yíò sì kọ ọ́.
13 Yíò sì ṣe tí àwọn Jũ yíò ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ará Nífáì, àwọn ará Nífáì nã yíò sì ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn Jũ; àwọn ará Nífáì àti àwọn Jũ yíò sì ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀yà Isráẹ́lì tí ó ti sọnù; àwọn ẹ̀yà Isráẹ́lì tí ó ti sọnù yíò sì ní àwọn ọ̀rọ̀ àwọn ará Nífáì àti àwọn Jũ.
14 Yíò sì ṣe tí a ó kó àwọn ènìyàn mi, tí nṣe ti ará ilé Isráẹ́lì, jọ sílẹ̀ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn; a ó sì kó ọ̀rọ̀ mi jọ ní ọ̀kan pẹ̀lú. Èmi yíò sì fi hàn sí àwọn tí nbá ọ̀rọ̀ mi àti àwọn ènìyàn mi jà, tí nṣe ti ará ilé Isráẹ́lì, pé èmi ni Ọlọ́run, àti pé èmi dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ábráhámù pé èmi yíò rántí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé.