Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 25


Ori 25

Nífáì nyọ̀ nínú ìṣe kedere—Àwọn ìsotẹ́lẹ̀ Ìsáíàh yíò yéni ní àwọn ọ́jọ́ ìkẹhìn—Àwọn Jũ yíò padà láti Bábílọ́nì, wọn yíò kan Messia mọ́ àgbélèbú, a ó sì tú wọn ká a ó sì jẹ wọ́n níyà—A ó mú wọn padà sípò nígbàtí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú Messia—Òun yíò wá níṣãjú ní ẹgbẹ̀ta ọdún lẹ́hìn tí Léhì fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀—Àwọn ará Nífáì pa òfin Mósè mọ́ wọ́n sì gbàgbọ́ nínú Krístì, ẹni tí ó jẹ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí mo ti kọ, èyí tí a ti sọ nípa ẹnu Isaiah. Nítorí kíyèsĩ i, Isaiah sọ àwọn ohun púpọ̀ tí ó le fún púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mi láti mọ̀; nítorí wọn kò mọ̀ nípa irú sísọ-tẹ́lẹ̀ ni ãrín àwọn Jũ.

2 Nítorí èmi, Nífáì, kò tí ì kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nípa íṣe àwọn Jũ; nítorí àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́ àwọn iṣẹ́ òkùnkùn, àwọn ìṣe wọn sì jẹ́ àwọn ìṣe ẹ̀gbin.

3 Nítorí-èyi, mo kọ̀wé sí àwọn ènìyàn mi, sí gbogbo àwọn wọnnì tí yíò gba àwọn ohun wọ̀nyí tí mo kọ lẹ́hìn èyí, kí wọ́n lè mọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run, pé kí wọ́n wá sórí gbogbo orílẹ̀-èdè, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ nã èyí tí ó ti sọ.

4 Nítorí-èyi, ẹ fetísílẹ̀, A! ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì, kí ẹ sì fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi; nítorí bí àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah kò bá tilẹ̀ ṣe kedere sí yín, bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n ṣe kedere sí gbogbo àwọn wọnnì tí ó kún fún ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n mo fi ìsọtẹ́lẹ̀ kan fún yín, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí èyí tí mbẹ nínú mi; nítorí-èyi èmi yíò sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìṣe kedere èyí tí ó ti wà pẹ̀lú mi láti ìgbà tí mo ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú bàbá mi; nítorí kíyèsĩ i, ọkàn mi yọ̀ ní ìṣe kedere sí àwọn ènìyàn mi, kí wọ́n lè kọ́ èkọ́.

5 Bẹ̃ni, ọkàn mi sì yọ̀ nínú àwọn ọrọ Isaiah, nítorí mo jáde wá láti Jerúsálẹ́mù, ojú mi sì ti kíyèsĩ àwọn ohun ti àwọn Jũ, mo sì mọ̀ pé àwọn Jũ mọ́ àwọn ohun ti awọn wòlĩ, kò sì sí àwọn ènìyàn míràn tí ó mọ́ àwọn ohun tí a sọ sí àwọn Jũ bí àwọn, àfi tí ó bá jẹ́ pé a kọ́ wọn ní irú ọ̀nà àwọn ohun àwọn Jũ.

6 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi, Nífáì, kò tí ì kọ́ àwọn ọmọ mí ní irú ọ̀nà àwọn Jũ; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi, tìkarãmi, ti gbé ní Jerúsálẹ́mù, nítorí-èyi mo mọ̀ nípa àwọn agbègbè rẹ̀ yíká; mo sì ti ṣe ìrántí sí àwọn ọmọ mi nípa ìdájọ́ Ọlọ́run, èyí tí ó ti ṣe lãrín àwọn Jũ, sí àwọn ọmọ mi, gẹ́gẹ́bí gbogbo èyí tí Isaiah ti sọ, èmi kò sì kọ wọ́n.

7 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi ntẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ tèmi, gẹ́gẹ́bí ìṣe kedere mi; ní èyí tí mo mọ̀ pé ẹnìkan kò lè ṣe àṣìṣe; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ní àwọn ọjọ́ tí a ó mú àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ Isaiah ṣẹ àwọn ènìyàn yíò mọ̀ dájú, ní àwọn àkókò tí wọn yíò ṣe.

8 Nítorí-èyi, wọ́n jẹ́ ìtóye sí àwọn ọmọ ènìyàn, ẹni tí ó bá sì ṣèbí wọn kò jẹ́ bẹ̃, ni èmi yíò bá sọ̀rọ̀ ní pàtàkì, èmi yíò sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn tèmi nìkan; nítorí mo mọ̀ pé wọn yíò jẹ́ ìtóye nlá sí wọn ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn; nítorí ní ọjọ́ nã ni wọn yíò mọ̀ wọ́n; nitórí-èyi, fún ire wọn ni mo ṣe kọ wọ́n.

9 Bí a sì ti pa ìran kan run lãrín àwọn Jũ nítorí tí àìṣedẽdé, àní bẹ̃ni a ti pa wọ́n run láti ìran dé ìran gẹ́gẹ́bí àìṣedẽdé wọn; a kò sì pa èyíkéyí nínú wọn run rí àfi tí a bá sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlĩ Olúwa.

10 Nítorí-èyi, a ti sọ fún wọn nípa ìparun èyí tí yíò wá sórí wọn, lọ́gán lẹ́hìn tí bàbá mí kúrò ní Jerúsálẹ́mù; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n sé ọkàn wọn le; àti gẹ́gẹ́bí ìsọtẹ́lẹ̀ mi a ti pa wọ́n run, àfi ti àwọn wọnnì tí a mú ní ìgbèkun sínú Bábílọ́nì.

11 Àti nísisìyí èyí ni mo sọ nítorí ti ẹ̀mí tí mbẹ nínú mi. Àti l’áìṣírò a ti mú wọn lọ wọn yíò tún padà, wọn yíò sì jogún ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù; nítorí-èyi, a ó tún mú wọn padà sípò sí ilẹ̀ ìní wọn.

12 Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, wọn yíò ní ogun, àti ìró ogun; nígbàtí ọjọ́ nã bá sì wá tí Ọmọ bíbí Kanṣoṣo ti Bàbá, bẹ̃ni, àní Bàbá ọ̀run òun ayé, yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní ẹran ara, kíyèsĩ i, wọn yíò kọ̀ ọ́, nítorí ti àìṣedẽdé wọn, àti líle ọkàn wọn, àti líle ọrùn wọn.

13 Kíyèsĩ i, wọn yíò kàn án mọ́ àgbélèbú; lẹ́hìn tí a bá sì ti gbe ẹ dùbúlẹ̀ ní ibojì fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta òun yíò jínde kúrò nínú òkú, pẹ̀lú ìmúláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀; gbogbo àwọn tí yíò sí gbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀ ní a ó gbà là ní ìjọba Ọlọ́run. Nítorínã, ọkàn mi yọ̀ láti sọ-tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, nítorí mo ti rí ọjọ́ rẹ̀, ọkàn mi sì gbé orúkọ mímọ́ rẹ̀ ga.

14 Sì kíyèsĩ i yíò ṣe pé lẹ́hìn tí Messia bá ti jínde kúrò nínú òkú, tí ó sì ti fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀, sí ọ̀pọ̀ àwọn tí ó bá gbàgbọ́ ní orúkọ rẹ̀, kíyèsĩ i, a ó tún pa Jerúsálẹ́mù run; nítorí ègbé ni fún àwọn tí mbá Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn ìjọ rẹ̀ jà.

15 Nítorí-èyi, a ó tú àwọn Jũ ká lãrín àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo; bẹ̃ni, Bábílọ́nì ni a ó sì parun pẹ̀lú; nítorí-èyi, a ó tú àwọn Jũ ká nípasẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míràn.

16 Lẹ́hìn tí a bá ti tú wọn ká, tí Olúwa Ọlọ́run sì ti fìyà jẹ wọ́n nípasẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè míràn fún ìwọ̀n àkókò ìran púpọ̀, bẹ̃ni, àní láti ìran dé ìran títí a ó fi yí wọn lọ́kàn padà láti gbàgbọ́ nínú Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, àti ètùtù, èyí tí kò lópin fún gbogbo aráyé—nígbàtí ojọ́ nã yíò sì de tí wọn ó gbàgbọ́ nínú Krístì, tí wọn ó sì sin Bàbá ní orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ tí kò ní ẽrí, tí wọn kò wo iwájú mọ́ fún Messia míràn, nígbànã, ní àkókò nã, ọjọ́ nã yíò dé tí yíò di yíyẹ dandan pé kí wọ́n gba àwọn ohun wọ̀nyí gbọ́.

17 Olúwa yíò sì tún ṣe ọwọ́ rẹ̀ ní ìgbà èkejì láti mú àwọn ènìyàn rẹ̀ padà sípò láti ipò wọn tí wọ́n ti sọnù tí wọ́n sì ti ṣubú. Nítorí-èyi, òun yíò tẹ̀ síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu àti àjèjì lãrín àwọn ọmọ ènìyàn.

18 Nítorí-èyi, òun yíò mu àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde sí wọn, àwọn ọ̀rọ èyí tí yíò dá wọn lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn, nítorí a ó fi wọ́n fún wọn fún ète yíyí wọn lọ́kàn padà nípa Messia òtítọ́, ẹnití wọ́n kọ̀ sílẹ̀; àti sí yíyí wọn lọ́kàn padà pé wọ́n lè ṣe láé wo iwájú mọ́ fún Messia láti wá, nítorí kò yẹ kí èyíkéyí wá, àfi tí yíò bá jẹ́ Messia èké tí yíò tan àwọn ènìyàn jẹ; nítorí àfi Messia kan ni àwọn wòlĩ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Messia nã sì ni ẹni tí àwọn Jũ yíò kọ̀ sílẹ̀.

19 Nítorí gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, Messia nã mbọ̀wá ní ẹgbẹ̀ta ọdún láti ìgbà tí bàbá mi kúrò ní Jerúsálẹ́mù; àti gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ, àti pẹ̀lú ọ̀rọ̀ angẹ́lì Ọlọ́run nì, orúkọ rẹ̀ yíò jẹ́ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run.

20 Àti nísisìyí, ẹyin arákùnrin mi, èmi ti sọ̀rọ̀ kedere kí ẹ má bá ṣìṣe. Bí Olúwa Ọlọ́run sì ti mbẹ tí ó mú Isráẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì, tí ó fi agbára fún Mósè kí ó lè wo áwọn orílẹ̀-èdè nì sàn lẹ́hìn tí àwọn ejò olóró ti bù wọ́n jẹ, bí wọ́n bá gbé ojú wọn sí ejò tí ó gbé dìde sókè níwájú wọn, ó sì fi agbára fún un pẹ̀lú kí ó lu àpáta tí omi sì jáde wá; bẹ̃ni, kíyèsĩ i mo wí fún yín, pé bí àwọn ohun wọ̀nyí ti jẹ́ òtítọ́, àti bí Olúwa Ọlọ́run ti wà lãyè, kò sí orúkọ míràn tí a fi fún ni lábẹ́ ọ̀run àfi ti Jésù Krístì yí, nípa ẹni tí mo ti sọ, nípa èyí tí a ó fi gba ènìyàn là.

21 Nítorí-èyi, nítorí ìdí èyí ni Olúwa Ọlọ́run ti ṣe ìlérí fún mi pé àwọn ohun wọ̀nyí tí mo kọ ni a ó tọ́jú ti a ó sì pamọ́, a ó sì fi lelẹ fún irú-ọmọ mi, láti ìran dé ìran, kí a lè mú ìlérí nã ṣẹ sí Jósẹ́fù, kí irú-ọmọ rẹ̀ má bá parun láé níwọ̀n ìgbàtí ayé bá ṣì dúró.

22 Nítorí-èyi, àwọn ohun wọ̀nyí yíò lọ láti ìran dé ìran níwọ̀n ígbàtí ayé bá ṣì dúró; wọn ó sì lọ gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti inú dídùn Ọlọ́run; àwọn orílẹ̀-èdè tí yíò sì ní wọn ni a ó ṣe ìdájọ́ fún nípa wọn gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a kọ.

23 Nítorí a ṣiṣẹ́ láìsinmi láti kọ̀wé, láti yí àwọn ọmọ wa lọkàn padà, àti àwọn arákùnrin wa pẹ̀lú, láti gbàgbọ́ nínú Krístì, àti láti ṣe ìlàjà sí Ọlọ́run; nítorí a mọ̀ pé nípa õre-ọ̀fẹ́ ni a gbà wá là, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe.

24 Àti, l’áìṣírò a gbàgbọ́ nínú Krístì, a pa òfin Mósè mọ́, a sì nwo iwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin sí Krístì, títí a ó fi mú òfin ṣẹ.

25 Nítorí, fún òpin èyí ni a ti fi òfin fún ni; nítorí-èyi òfin nã ti di òkú sí wa, a sì mú wa yè nínú Krístì nítorí ìgbàgbọ́ wa; síbẹ̀síbẹ̀ àwa n pa òfin nã mọ́ nítorí àwọn àṣẹ.

26 A sì nsọ̀rọ̀ nípa Krístì, a nyọ̀ nínú Krístì, a nwãsù nípa Krístì, a nsọ-tẹ́lẹ̀ nípa Krístì, a sì nkọ̀wé gẹ́gẹ́bí àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ wa, kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ orísun èwo ni àwọn lè wò fún ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ wọn.

27 Nítorí-èyi, à sọ̀rọ̀ nípa òfin nã kí àwọn ọmọ wa lè mọ́ kíkú òfin nã; àti kí àwọn, nípa mímọ́ kíkú òfin nã, lè wo iwájú sí ìyè nã tí mbẹ nínú Krístì, kí wọ́n sì mọ ìdí tí a fi fúnni ní òfin nã. Lẹ́hìn tí a bá sì mú òfin nã ṣẹ nínú Krístì, wọn ó mọ̀ pé kò yẹ kí wọn sé ọkàn wọn le sí i nígbàtí ó bá to láti pa òfin nã tì.

28 Àti nísisìyí kíyèsĩ i, ẹ̀yin ènìyàn mi, ọlọ́rùn-líle ènìyàn ni yín; nítorí-èyi, mo ti bá a yín sọ̀rọ̀ kedere, tí kò lè sàiyé yin. Àwọn ọ̀rọ̀ tí mo sì ti sọ yíò dúró bí ẹ̀rí sí yín; nítorí wọ́n to láti kọ́ ẹni kẹ́ni ní ọ̀nà tí ó tọ́; nítorí ọ̀nà tí ó tọ́ ni láti gbàgbọ́ nínú Krístì kí á máṣe sẹ́ ẹ; nítorí nípa sísẹ́ ẹ ẹ̀yin nsẹ́ àwọn wòlĩ àti òfin nã.

29 Àti nísisìyí kíyèsĩ i, mo wí fun yín pé ọ̀nà tí ó tọ́ ni láti gbàgbọ́ nínú Krístì, kí á má sì ṣe sẹ́ ẹ; Krístì sì ni Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nítorí-èyi ẹ̀yin kò lè ṣe àìwólẹ̀ níwájú rẹ̀, kí ẹ sì sìn ín pẹ̀lú gbogbo agbára, iyè, àti ipá yín, àti gbogbo ọkàn yín; bí ẹ̀yin bá sì ṣe èyí a kì yíò sọ yín sóde bí ó ti wù kí ó rí.

30 Àti, níwọ̀n bí yíò ti jẹ́ títọ́, ẹ̀yin kò lè ṣe àìpa ìṣe àti ìlànà Ọlọ́run mọ́ títí a ó fi mú òfin nã ṣẹ èyí tí a fi fún Mósè.