Àwọn Ìwé Mímọ́
2 Nífáì 17


Ori 17

Efráímù àti Síríà gbogun ti Júdà—Krístì ni a ó bí láti ọwọ́ wúndíá kan. Fi Isaiah 7 wé é. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe ní àwọn ọjọ́ Áhásì ọmọkùnrin Jótámù, ọmọkùnrin Ussíàh, ọba Júdà, tí Résínì, ọba Síríà, àti Pékà ọmọkùnrin Remalíàh, ọba Isráẹ́lì, gòkè lọ síhà Jerúsálẹ́mù láti jà á ní ogun, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀.

2 A sì sọ fún ilé Dáfídì, pe: Síríà bá Efráímù dìmọ̀lú. Ọkàn rẹ̀ sì mì, àti ọkàn àwọn ènìyàn rẹ̀, bí igi igbó ti í mì nípa ẹ̀fũfù.

3 Nígbànã ni Olúwa wí fún Isaiah: Jáde lọ nísisìyí láti pádè Áhásì, ìwọ àti Ṣeájáṣúbù ọmọ kùnrin rẹ, ní ìpẹ̀kun ojú ìṣàn ìkùdù ti apá òkè ní òpópó papa afọṣọ;

4 Sì sọ fún un: Kíyèsára, kí o sì gbé jẹ́; má bẹ̀rù, bẹ̃ni kí o máṣe jáya nítorí ìrù méjì igi íná tí nrú ẽfín wọ̀nyí, nítorí ìbínú mímúna Résínì pẹ̀lú Síríà, àti ti ọmọkùnrin Remalíàh.

5 Nítorí Síríà, Efráímù, àti ọmọkùnrin Remalíàh, ti gbìmọ̀ ibi sí ọ, wípé:

6 Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ sí Júdà kí á sì bã nínú jẹ́, ẹ sì jẹ́ kí á ṣe ihò nínú rẹ̀ fún ara wa, kí a sì gbé ọba kan kalẹ̀ lãrín rẹ̀, bẹ̃ni, ọmọ Tábéálì.

7 Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kì yíò dúró, bẹ̃ni kì yíò ṣẹ.

8 Nítorí orí Síríà ni Damáskù, àti orí Damáskù, Résínì; nínú ọdún márun lé lọgọta ni a ó fọ́ Efráímù tí kì yíò sì jẹ́ ẹ̀yà ènìyàn kan mọ́.

9 Orí Efráímù sì ni Samáríà, orí Samáríà sì ni ọmọ kùnrin Remalìàh. Bí ẹ̀yin kì yíò bá gbàgbọ́ lótitọ́ a kì yíò fi ìdí yín múlẹ̀.

10 Pẹ̀lú-pẹ̀lú, Olúwa tún sọ fún Áhásì, wípé:

11 Bèrè àmì kan lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ; bèrè rẹ̀ ìbá à jẹ́ ní ọ̀gbun, tabí ní ibi gíga jùlọ.

12 Ṣùgbọ́n Áhásì wípé: Èmi kì yíò bere, bẹ̃ni èmi kì yíò dán Olúwa wò.

13 Òun sì wípé: Ẹ gbọ́ nísisìyí A! ará ilé Dáfídì; ṣé ohun kékeré ni fún yín láti dá ènìyàn lágara, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó ha sì dá Ọlọ́run mi lágara pẹ̀lú bí?

14 Nítorínã, Olúwa tìkararẹ̀ yíò fún yín ní àmì kan—Kíyèsĩ i, wúndíá kan yíò lóyún, yíò sì bí ọmọkùnrin kan, yíò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Immánúẹ́lì.

15 Òrí-àmọ́ àti oyin ni yíò ma jẹ, kí ó lè mọ̀ láti kọ ibi àti láti yan ire.

16 Nítorí kí ọmọ nã tó lè mọ̀ láti kọ ibi kí ó sì yan ire, ilẹ̀ ti ìwọ kórìra yíò di ìkọ̀sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọba rẹ̀ méjẽjì.

17 Olúwa yíò mú wá sórí rẹ, àti sórí àwọn ènìyàn rẹ, àti sórí ilé bàbá rẹ, àwọn ọjọ́ tí kò tí ì wá láti ọjọ́ tí Efráímù ti lọ kúrò lọ́dọ̀ Júdà, ọba Assíríà.

18 Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã tí Olúwa yíò fẹ́ ẽmí sí eṣinṣin tí ó wà ní apá ìpẹ̀kun Égíptì, àti sí oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Assíríà.

19 Wọn yíò sì wá, gbogbo wọn yíò sì bà sínú àfonífojì ijù, àti sínú pàlàpálá òkúta, àti sí órí gbogbo ẹ̀gún, àti sí órí ewéko gbogbo.

20 Ní ọjọ́ kannã ni Olúwa yíò fa-irun pẹ̀lú abẹ tí a yá, ti àwọn ti ìhà kejì odò nì, ti ọba Assíríà, orí, àti irun ẹsẹ̀; yíò sì run irùgbọ̀n pẹ̀lú.

21 Yíò sì ṣe ní ojọ́ nã, ènìyàn kan yíò sì tọ́ ọmọ màlũ kan àti àgùtàn méjì;

22 Yíò sì ṣe, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọ́n yíò mú wá, yíò jẹ òrí-àmọ́; nítorí òrí-àmọ́ àti oyin ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá kù ní ãrin ilẹ̀ nã yíò ma jẹ.

23 Yíò sì ṣe ní ọjọ́ nã, ibi gbogbo yíò dí, ibi tí ẹgbẹ̀rún àjàrà tí wà fún ẹgbẹ̀rún owó fàdákà, èyí tí yíò di ti ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún.

24 Pẹ̀lú ọfà àti ọrún ni ènìyàn yíò wá ibẹ̀, nítorípé gbogbo ilẹ̀ nã yíò di ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún.

25 Àti gbogbo òkè kékèké tí a ó fi ọkọ́ tu, ẹ̀rù ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún kì yíò de ibẹ̀; ṣùgbọ́n yíò jẹ́ fún dída màlũ lọ, àti títẹ̀mọ́lẹ̀ àwọn ẹran kékèké.