Ori 6
Jákọ́bù tún ìtàn àwọn Jũ sọ: Ìgbèkùn ti Bábílọ́nì àti àbọ̀dé; iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ìyà ìkànmọ́ àgbélẽbú ti Ẹní Mímọ́ Ísráẹ́lì; ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n rí gbà lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí; àti ìmúpadà sípò ọjọ́ ìkẹhìn ti àwọn Jũ nígbàtí wọ́n gbàgbọ́ nínú Messia. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù, arákùnrin Nífáì, èyí tí ó sọ sí àwọn ènìyàn Nífáì:
2 Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin àyànfẹ́ mi, èmi, Jákọ́bù, nítorítí Ọlọ́run ti pè mí, tí a sì yàn mí nípa ọ̀nà ètò mímọ́ rẹ̀, àti nítorítí a ti yà mí sí mímọ́ nípa ọwọ́ arákùnrin mi Nífáì, ẹni tí ẹ̀yin nwò bí ọba tàbí alãbò, àti ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé fún àìléwu, kíyèsĩ i ẹ̀yin mọ̀ pé èmi ti sọ àwọn ohun púpọ̀púpọ̀ fún yín.
3 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo tún bã yín sọ̀rọ̀; nítorí mo nĩfẹ́ fún àlãfíà ọkàn yín. Bẹ̃ni, àníyàn mi pọ̀ fún yín; ẹ̀yin tìkarãyín sì mọ̀ pé ó ti wà nígbà-gbogbo. Nítorí mo ti gbà yín níyànjú pẹ̀lú gbogbo ãpọn; mo sì ti kọ́ yín ní àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi; mo sì ti sọ̀rọ̀ sí yín nípa gbogbo àwọn ohun èyí tí a kọ, láti ẹ̀dá ayé.
4 Àti nísisìyí, kíyèsĩ i, èmi yíò sọ̀rọ̀ sí yin nípa àwọn ohun èyí tí mbẹ, àti èyí tí mbọ̀; nítorí-èyi, èmi yíò ka àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah sí yín. Wọ́n sì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí arákùnrin mi ti fẹ́ kí èmi kí ó sọ fún yín. Mo sì sọ̀rọ̀ sí yín fún ànfàní tiyín, kí ẹ́yin kí ó lè kọ́ ẹ̀kọ́ kí ẹ sì yin orúkọ Ọlọ́run yín lógo.
5 Àti nísisìyí, àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí èmi yíò kà jẹ́ àwọn èyí tí Isaiah sọ nípa gbogbo ará ilé Isráẹ́lì; nítorí-èyi, a lè fi wọ́n we yín, nítorí ẹyin jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì. Àwọn ohun púpọ̀ sì wà èyí tí a ti sọ nípasẹ̀ Isaiah èyí tí a lè fí wé yín, nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì.
6 Àti nísisìyí, ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ nã: Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsĩ i, èmi yíò gbe ọwọ́ mi sókè si àwọn Kèfèrí, èmi ó sì gbe ọ̀págún mi sókè sí àwọn ènìyàn; wọn yíò sì gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá ní apá wọn, a ó sì gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ ní èjìká wọn.
7 Àwọn ọba yíò jẹ́ àwọn baba olutọ́jú rẹ, àti àwọn ayaba wọn yíò sì jẹ́ àwọn ìyá olutọ́jú rẹ; wọn yíò tẹríba fún ọ ní ìdojúbolẹ̀, wọn ó sì lá erùpẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ; ìwọ yíò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa; nítorí ojú kì yíò ti àwọn tí ó bá dúró dè mí.
8 Àti nísisìyí èmi, Jákọ́bù, yíò sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Nítorí kíyèsĩ i, Olúwa ti fi hàn mí pé àwọn wọnnì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, láti ibi tí àwa ti wá, ni a ti pa tí a sì gbé lọ ní ìgbèkùn.
9 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa ti fi hàn sí mi pé kí wọ́n tún padà. Ó sì ti fi hàn sí mi pẹ̀lú pé Olúwa Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní ẹran ara; lẹ́hìn tí òun yíò sì fi ara rẹ̀ hàn, wọn yíò nà á, wọn ó sì kàn án mọ́ àgbélèbú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ angẹ́lì tí ó bámi sọ̀rọ̀.
10 Lẹ́hìn tí wọ́n bá sì ti sé ọkàn wọn le tí wọn sì wa ọrùn wọn kì sí Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì, kíyèsĩ i, ìdájọ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì nì yíò wá sórí wọn. Ọjọ́ nã sì mbọ̀wá tí a ó lù wọ́n tí a ó sì pọ́n wọn lójú.
11 Nítorí-èyi, lẹ́hìn tí a bá darí wọn sí ìhín àti sí ọ̀hún, nítorí báyĩ ni angẹ́lì nã wí, púpọ̀ ni a ó pọ́n lójú ní ẹran ara, a kò sì ní jẹ́ kí wọ́n parun, nítorí ti àwọn àdúrà olódodo; a ó tú wọn ká, a ó sì lù wọ́n, a ó sì kórìra wọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa yíò ni ãnú sí wọn, pé nígbàtí wọ́n yíò bá wá sí ìmọ̀ Olùràpadà wọn, a ó tún kó wọn jọ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn.
12 Alábùkún-fún sì ni àwọn Kèfèrí, àwọn nípa ẹni tí wòlĩ nì ti kọ̀wé; nítorí kíyèsĩ i, bí ó bá rí báyĩ í pé wọn yíò ronúpìwàdà kí wọ́n má sì ṣe bá Síónì jà, kí wọn sì máṣe pa ara wọn pọ̀ mọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, a ó gbà wọ́n là; nítorí Olúwa Ọlọ́run yíò mú àwọn májẹ̀mú rẹ̀ ṣẹ èyí tí ó ti ṣe sí àwọn ọmọ rẹ̀; fún ìdí èyí sì ni wòlĩ nì ti kọ àwọn ohun wọ̀nyí.
13 Nítorí-èyi, àwọn tí ó bá bá Síónì àti àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa jà yíò lá erùpẹ̀ ẹsẹ̀ wọn; àwọn ènìyàn Olúwa kì yíò sì tijú. Nítorí àwọn ènìyàn Olúwa ni àwọn wọnnì tí ó dúró fún un; nítorí síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n dúró fún bíbọ̀ Messia náà.
14 Sì kíyèsĩ i, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ nì, Messia nã yíò tún mú ara rẹ̀ ní ìgbà èkejì láti gbà wọ́n padà; nítorí-èyi, òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí wọn ní agbára àti ògo nlá, sí ìparun àwọn ọ̀tá wọn, nígbàtí ọjọ́ nã bá dé tí wọn yíò gbàgbọ́ nínú rẹ̀; òun kì yíò sì pa ẹnikẹ́ni run tí ó bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
15 Àwọn tí kò bá sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ ni a ó parun, àti nípasẹ̀ iná, àti nípasẹ̀ ẹ̀fũfùlíle, àti nípasẹ̀ ìsẹ̀lẹ̀, àti nípasẹ̀ ìta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti nípasẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn, àti nípasẹ̀ ìyàn. Wọn yíò sì mọ̀ pé Olúwa ni Ọlọ́run, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì.
16 Nítorí a ha lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára bí, tàbí àwọn ondè lọ́wọ́ àwọn ẹni tí ó tọ́ fún?
17 Sùgbọ́n báyĩ ni Olúwa wí: A ó tilẹ̀ gba àwọn ondè kúrò lọ́wọ́ alágbára, a ó sì gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn ẹni-ẹ̀rù; nítorí Ọlọ́run Alágbára yíò gba àwọn ènìyàn májẹ̀mú rẹ̀ là. Nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Èmi yíò bá wọn jà tí ó bá bá yín jà—
18 Èmi yíò sì bọ́ àwọn tí ó ni ọ́ lára, pẹ̀lú ẹran ara wọn; wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmuyó bí ọtí-wáínì dídùn; gbogbo ẹran ara yíò sì mọ̀ pé èmi Olúwa ni Olùgbàlà rẹ àti Olùràpadà rẹ, Ẹni Alágbára ti Jákọ́bù.