Ori 16
Isaiah rí Olúwa—A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Isaiah jì í—A pè é láti sọ tẹ́lẹ̀—Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìkọ̀sílẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ Krístì láti ọwọ́ àwọn Jũ—Ìyókù kan yíò padà—Fi Isaiah 6 wé e. Ní ìwọ̀n ọdún 559 sí 545 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Ní ọdún tí ọba Ussíàh kú, èmi rí Olúwa jóko lórí ìtẹ́ kan, tí ó ga tí ó sì gbé sókè, ìṣẹ́tì aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún tẹ́mpìlì.
2 Lókè rẹ̀ ni séráfù dúró; ọ̀kọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà; pẹ̀lú méjì ó bò ojú rẹ̀, pẹ̀lú méjì ó sì bò ẹsẹ̀ rẹ̀, pẹ̀lú méjì ó sì fò.
3 Ìkíní sì ké sí èkejì, ó wípé: Mímọ́, mímọ́, mímọ́, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.
4 Àwọn òpó ilẹ̀kùn sì mì nípa ohùn ẹni tí ó ké, ilé nã sì kún fún ẽfín.
5 Nígbànã ni mo wípé: Ègbé ni fún mi! nítorí mo gbé; nítorí tí mo jẹ́ ẹni-aláìmọ́ ètè; mo sì ngbé lãrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè; nítorí tí ojú mi ti rí Ọba nã, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun.
6 Nígbànã ni ọ̀kan nínú àwọn séráfù nã fò wá si ọ́dọ̀ mi, ó ní ẹyin-iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú láti orí pẹpẹ wá;
7 Ó sì fi kàn mí ní ẹnu, ó sì wípé: Kíyèsĩ i, èyí ti kan ètè rẹ; a mú àìṣedẽdé rẹ kúrò, a sì fọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.
8 Èmi sì gbọ́ ohùn Olúwa pẹ̀lú tí ó wípé: Tani èmi ó rán, àti tani yíò lọ fún wa? Nígbànã ni èmi wípé: Èmi nìyí; rán mi.
9 Òun sì wípé: Lọ kí o sì wí fún àwọn ènìyàn yí—Ẹ gbọ́ nítõtọ́, ṣùgbọ́n òye kò yé wọn; ẹ̀yin sì rí nítõtọ́, ṣùgbọ́n wọn kò wòye.
10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn yí kí ó sébọ́, sì mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dì wọ́n ní ojú—kí wọn kí ó má bá ríran pẹ̀lú ojú wọn, kí wọn má bá sì gbọ́ pẹ̀lú etí wọn, kí wọn má bá sì mọ̀ pẹ̀lú ọkàn wọn, kí a má bá sì yí wọn padà kí a má bá sì mú wọn ní ara dá.
11 Nígbànã ni èmi wípé: Olúwa, yíò ti pẹ́ tó? Ó sì wípé: Títí àwọn ìlú nlá yíò fi di ahoro ní àìsí olùgbé, àti àwọn ilé ní àìsí ènìyàn, àti ilẹ̀ yíò di ahoro pátápátá;
12 Tí Olúwa yíò sì ṣí àwọn ènìyàn nã kúrò lọ réré, nítorí ìkọ̀sílẹ̀ nlá yíò wà ní inú ilẹ̀ nã.
13 Sùgbọ́n síbẹ̀ ìdámẹ́wa yíò wà, wọn yíò sì padà, yíò sì di rírún, bí igi téílì, àti bí igi óákù èyí tí ọpá wà nínú wọn nígbàtí ewé wọn bá rẹ̀; bẹ̃ni èso mímọ́ nã yíò jẹ́ ọpá nínú rẹ̀.