Ìkéde Lábẹ́ Àṣẹ 2
Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni pé “ẹni gbogbo rí bákannáà sí Ọlọ́run,” nínú rẹ̀ ni “dúdú àti funfun, òndè àti òmìnira, akọ àti abo” (2 Néfì 26:33). Jákèjádò ìtàn ti Ìjọ, àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà àti àṣà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni a ti rìbọmi tí wọ́n sì ti gbé bíi ọmọ Ìjọ ní tòótọ́. Ní ìgbà ayé Joseph Smith, àwọn ọkùnrin aláwọ̀ dúdú ọmọ Ìjọ díẹ̀ jẹ́ yíyàn sí oyè-àlufáà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn rẹ̀, àwọn olùdarí Ìjọ dáwọ́ dúró ní fífi oyè-àlùfáà sí orí àwọn ọkùnrin aláwọ̀ dúdú tí wọ́n jẹ́ àtẹ̀lé ìran Áfírikà. Àwọn àkọsílẹ̀ Ìjọ kò fi òye kedere sílẹ̀ sí ìṣẹ̀dálẹ̀ ìṣe yìí. Àwọn olùdarí Ìjọ gbàgbọ́ pé wọ́n nílò ìfihàn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe àyípadà ìṣe yìí wọn sì fi tàdúràtàdúrà wá ìtọ́ni. Ìfihàn náà wá sí Ààrẹ Ìjọ Spencer W. Kimball ó sì jẹ́ fífi múlẹ̀ sí àwọn olùdarí Ìjọ mĩràn ninú Témpìlì ti Salt Lake ní 1 Oṣù Kẹfà 1978. Ìfihàn náà ṣe àmúkúrò gbogbo ìdènà tí ó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà, tí ó ti fi ìgbàkan jẹ́ mímúlò sí ọ̀rọ̀ oyè-àlùfáà.
Sí Ẹnití Ó Lè Kàn:
Ní 30 Oṣù Kẹsãn 1978, ní Ìpàdé Gbogbogbò Ẹlẹ́ẹ̀mejì Lọ́dún ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a gbé ìwọ̀nyí kalẹ̀ láti ọwọ́ Ààrẹ N. Eldon Tanner, Olùdámọ̀ràn Akọ́kọ́, nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ:
Ní ibẹ̀rẹ̀ Oṣù Kẹfà ti ọdún yìí, Àjọ Ààrẹ Ìkínní kéde pé ìfihàn kan jẹ́ gbígbà nípasẹ̀ Ààrẹ̀ Spencer W. Kimball ti ó nawọ́ àwọn ìbùkún oyè àlùfáà àti ti tẹ́mpìlì sí gbogbo ọkùnrin ọmọ ìjọ tí wọ́n yẹ. Ààrẹ Kimball ti sọ pé kí èmi ó gba ìpàdé àpapọ̀ náà ní ìmọ̀ràn pé lẹ́hìn tí òun ti gba ìfihàn yìí, èyítí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́hìn àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ nínú àwọn yàrá mímọ́ inú tẹ́mpìlì mímọ́, òun gbe e kalẹ̀ fún àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀, àwọn ẹnití wọ́n tẹ́wọ́gbà á tí wọ́n sì fi ọwọ́ sí i. Nígbànáà a gbé e kalẹ̀ fún Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, àwọn ẹnití wọ́n fi ọwọ́ sí i ní ìfohùnṣọ̀kan, àti lẹ́hìnnáà a gbée kalẹ̀ sí gbogbo àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò mĩràn, tí àwọn bákánnàá fi ọwọ́ sí i ní ìfohùnṣọ̀kan.
Ààrẹ Kímball ti sọ pé kí èmi ó ka ìwé yìí nísisìyí:
8 Oṣù Kẹfà, 1978
Sí gbogbo olóye àlùfáà gbogbogbò àti ti agbègbè tí wọ́n di ipò mú ní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹ̀hìn jákèjádò àgbáyé:
Ẹ̀yin Arákùnrin Ọ̀wọ́n:
Bí a ṣe ti rí ìtànkálẹ̀ iṣẹ́ Olúwa ní orí ilẹ̀ ayé, a ti fi ìmoore hàn pé àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ti dáhùn sí ọ̀rọ̀ ìhìnrere tí a mú padàbọ̀ sípò, wọ́n sì ti darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní iye tí ó npọ̀ síi sáá. Èyí, ní ìyọrísí, ti mísí wa pẹ̀lú ìfẹ́ inú láti nawọ́ gbogbo ànfàní àti àwọn ìbùkún èyítí ìhìnrere nfúnni sí olúkúlùkù ọmọ ìjọ tí wọ́n yẹ.
Ní mímọ̀ nipa àwọn ìlérí tí a ti ṣe nípasẹ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ààrẹ Ìjọ tí wọ́n ti ṣaájú wa, pé ní àkókò kan, nínú ètò ayérayé ti Ọlọ́run, gbogbo àwọn arákùnrin wa tí wọ́n yẹ lè gba oyè-àlùfáà, àti ní jíjẹ́rìísí ìsòtítọ́ ti àwọn wọnnì láti ọ̀dọ̀ àwọn tí a ti dá oyè-àlùfáà dúró, a ti bẹ̀bẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ àti pẹ̀lú ìtara fún ànfàní àwọn wọ̀nyí, àwọn olõtọ́ arákùnrin wa, ní lílo ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí nínú Yàrá Òkè ti Tẹ́mpìlì ní bíbẹ Olúwa fún ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá.
Òun ti gbọ́ àwọn àdúrà wa, àti nípa ìfihàn Ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ pé ọjọ́ náà tí a ti ṣèlérí rẹ̀ nígbà pípẹ́ ti dé nígbàtí olukúlùkù olõtọ́, ènìyàn yíyẹ nínú Ìjọ yío lè gba oyè àlùfáà mímọ́, pẹ̀lú agbára láti ṣe iṣẹ́ àṣẹ àtọ̀runwá rẹ̀, kí ó sì gbádùn gbogbo ìbùkún tí ó nṣàn wá láti ibẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùfẹ́ rẹ̀, nínú èyítí àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wà. Bẹ́ẹ̀gẹ́gẹ́, gbogbo ọkùnrin ọmọ Ìjọ tí wọ́n bá yẹ lè jẹ́ yíyàn sí oyè- àlùfáà láì ka ẹ̀yà tàbí àwọ̀ sí. Àwọn aṣíwájú olóyè àlùfáà ti gba ìkọ́ni láti tẹ̀lé ìgbésẹ̀ ti fífi ara balẹ̀ ṣe ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò ti gbogbo àwọn ọmọ ìjọ fún ìfi-òróró-yàn sí bóyá Oyè-àlùfáà ti Áárónì tàbí ti Melkisédekì láti ríi dájú pé wọ́n kún ojú àwọn òṣùnwọ̀n tí a gbékalẹ̀ fún ìkàyẹ.
A kéde pẹ̀lú àròjìnlẹ̀ pé Olúwa ti sọ ìfẹ́ inú rẹ̀ di mímọ̀ nísisìyí fún bíbùkún gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ayé àwọn tí wọ́n bá fetísílẹ̀ sí ohùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí a fi àṣẹ fún, àti tí wọ́n múra ara wọn sílẹ̀ láti gba gbogbo ìbùkún ìhìnrere náà.
Tiyín nítòótọ́,
Spencer W. Kimball
N. Eldon Tanner
Marion G. Romney
Àjọ Ààrẹ Ìkínní
Ní mímọ Spencer W. Kimball bíi wòlíì, aríran, àti olùfihàn, àti ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, a dáa lábã pé àwa bíi àpéjọ kan tí ó ní àṣẹ tẹ́wọ́gba ìfihàn yìí bí ọ̀rọ̀ àti ìfẹ́ inú Olúwa. Gbogbo ẹnití ó bá fi ara mọ́ọ jọ̀wọ́ fi-hàn nípa gbígbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ sókè. Ẹnikẹ́ni tí ó lòdì nípasẹ̀ àmì kannáà.
Ìbò náà láti ṣe ìmúdúró àbá tí ó wà lókè yìí jẹ́ ìfohùnṣọ̀kan ní fífaramọ́.
Ìlú Nlá Salt Lake, Utah, 30 Oṣù Kẹsãn, 1978.