Ìpín 91
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 9 Oṣù Kejì 1833. Wòlíì náà ní àkókò yìí nṣiṣẹ́ ní orí ṣíṣe ìtumọ̀ Májẹ̀mú Láéláé. Ní dídé abala náà ti àwọn ohun kíkọ àtijọ́ tí wọ́n npè ní Apokrífà, ó béèrè lọ́wọ́ Olúwa ó sì gba ìtọ́sọ́nà yìí.
1–3, Apokrífà náà ni a túmọ̀ ní pípé jùlọ ṣùgbọ́n ó ní ọpọ̀lọpọ̀ àwọn àfikún nípa ọwọ́ àwọn ènìyàn tí wọn kò jẹ́ òtítọ́; 4–6, Ó ṣe ànfàní fún àwọn tí a fi òye yé nípasẹ̀ Ẹ̀mí.
1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín nípa Apokrífà náà—Àwọn ohun púpọ̀ ni ó wà nínú rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ òtítọ́, àti pé a túmọ̀ rẹ̀ ní pípé jùlọ;
2 Àwọn ohun púpọ̀ ni ó wà nínú rẹ̀ tí kìí ṣe òtítọ́, èyítí wọ́n jẹ́ àfikún nípa ọwọ́ àwọn ènìyàn.
3 Lõtọ́, ni mo wí fún yín, pé kò ṣe dandan pé kí Apokrífà jẹ́ títúmọ̀.
4 Nítorínáà, ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á, ẹ jẹ́ kí òun ó ní òye, nítorí Ẹ̀mí nṣe ìṣípayá òtítọ́;
5 Àti ẹnikẹ́ni tí Ẹ̀mi bá fi òye yé yíò gba ànfààní lati ibẹ̀;
6 Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà nípa Ẹ̀mí, kì yíò lè ní ànfààní. Nítorínáà kò ṣe dandan pé kí ó jẹ́ títúmọ̀. Amín.