Ìpín 22
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Manchester, New York, 16 Oṣù Kẹrin 1830. Ìfihàn yìí ni a fún Ìjọ ní àyọrísí ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti ṣe ìrìbọmi tẹ́lẹ̀, tí wọ́n fẹ́ láti ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìjọ láì tún ìrìbọmi ṣe.
1, Ìrìbọmi jẹ́ májẹ̀mú titun àti ti ayérayé; 2–4, Ìrìbọmi èyítí ó ní àṣẹ ni Olúwa fẹ́.
1 Ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín pé gbogbo awọn májẹ̀mú ti ìgbà láéláé ni mo ti mú kí á pa tì nínú ohun yìí; àti pé èyí ni májẹ̀mú titun kan ati ti ayérayé, àni irú èyí tí ó ti wà láti àtètèkọ́ṣe.
2 Nítorínáà, bí ó tilẹ̀ jẹ́pé a ri ènìyàn kan bọmi ní ìgbà ọgọ́rũn èyí kò já mọ́ nkan, nítorí ẹ̀yin kò lè wọlé sí ẹnu ọ̀nà híhá náà nípa òfin ti Mósè, tàbí nípa àwọn òkú iṣẹ́ yin.
3 Nítorípé ó jẹ́ ìtorí àwọn òkú iṣẹ́ yín ni mo ṣe mú kí májẹ̀mú ìkẹhìn yìí àti kí ìjọ yìí jẹ́ kíkọ́ sí mi, àní bíi ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì.
4 Nítorínáà, ìwọ wọlé sínú ní ẹnu ọ̀nà náà, bí èmi ṣe pàṣẹ, àti kí o máṣe lépa láti gba Ọlọ́run rẹ ní ìmọ̀ràn. Amin.