Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 56


Ìpín 56

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 15 Oṣù Kẹfà 1831. Ìfihàn yìí bá Ezra Thayre wí fún àìgbọ́ràn rẹ̀ sí ìfihàn ìṣaájú (“àṣẹ” náà tí a tọ́ka sí ní ẹsẹ 8), èyítí Joseph Smith ti gbà fún un, ní pípàṣẹ fún Thayre nípa àwọn ojúṣe rẹ̀ lóri oko Frederick G. Williams, nibití ó ngbé. Bákannáà ìfihàn tí ó tẹ̀lé yìí fa igi lé ìpè Thayre láti rìn ìrìnàjò lọ sí Missouri pẹ̀lú Thomas B. Marsh (wo ìpín 52:22).

1–2, Àwọn Ẹni Mímọ́ gbọ́dọ̀ gbé àgbélèbú wọn kí wọ́n sì máa tẹ̀lé Olúwa lati lè jèrè ìgbàlà; 3–13, Olúwa npàṣẹ Òun sì npa á rẹ́, àwọn aláìgbọràn ni Ó sì ta nù; 14–17, Ègbé ni fún àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọn kò le ran aláìní lọ́wọ́, àti ègbé ni fún àwọn aláìní tí wọn kò ní ìrora ọkàn; 18–20, Alábùkúnfún ni àwọn aláìní tí ọkàn wọn mọ́, nítorí wọn yíò jogún ayé.

1 Ẹ fetísílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn tí ẹ̀ njẹ́wọ́ orúkọ mi, ni Olúwa Ọlọ́run yín wí; nítorí kíyèsíi, ìbínú mi ru sókè sí àwọn ọlọ́tẹ̀, wọn yíò sì mọ ipá mi àti ìbínú mi, ní ọjọ́ ìbẹ̀wò àti ìrunú sí orí àwọn orílẹ̀-èdè.

2 Àti pé ẹni tí kò bá gbé àgbélèbú rẹ̀ kí ó sì tẹ̀lé mi, àti kí òun pa àwọn òfin mi mọ́, òun kannáà ni a kì yíò gbàlà.

3 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, pàṣẹ; ẹnití kò bá gbọ́ràn ni a ó ké kúrò ní àkókò tí ó yẹ ní ojú mi, lẹ́hìn tí èmi ti pàṣẹ tí a sì ré àṣẹ náà kọjá.

4 Nítorínáà èmi, Olúwa, pàṣẹ mo sì pa á rẹ́, bí ó ṣe tọ́ ní ojú mi; gbogbo èyí ni yíó sì jẹ́ dídáhùn fún ní orí àwọn ọlọ́tẹ̀, ni Olúwa wí.

5 Nítorínáà, èmi pa àṣẹ tí mo fi fún àwọn ìránṣẹ́ mi Thomas B. Marsh àti Ezra Thayre rẹ́, èmi sì fi òfin titun fún ìránṣẹ́ mi Thomas, pé kí òun rin ìrìnàjò rẹ̀ kánkán lọ sí ilẹ̀ Missouri, àti pé kí ìránṣẹ́ mi Selah J. Griffin ó lọ pẹ̀lú rẹ̀ bákannáà.

6 Nítorí kíyèsíi, èmi pa àṣẹ èyí tí a fifún àwọn ìránṣẹ́ mi Selah J. Griffin àti Newel Knight rẹ́, nítorí ọrùn líle àwọn ènìyàn mi tí wọ́n wà ní Thompson, àti ìwà ọ̀tẹ̀ wọn.

7 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Newel Knight dúró ní ọ̀dọ̀ wọn; àti iye àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ lè lọ, tí wọ́n ní ìròbìnújẹ́ níwájú mi, kí á sì tọ́ wọn nípasẹ̀ rẹ̀ sí ilẹ̀ náà èyí tí èmi ti yàn.

8 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ìránṣẹ́ mi Ezra Thayre gbọ́dọ̀ ronúpìwàdà nínú ìwà ìgbéraga rẹ́, àti ti ìmọ-tara-ẹni-nìkan rẹ̀, kí òun sì gbọ́ràn sí àwọn òfin ti tẹ́lẹ̀ tí èmi fi fún un nípa ibi tí ó ngbe.

9 Bí òun bá sì ṣe èyí, bí kì yío ṣe sí àwọn ìyapa tí a ó ṣe ní orí ilẹ̀ náà, a ó yàn án síbẹ̀síbẹ̀ láti lọ sí ilẹ̀ Missouri;

10 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ òun yíò gba owó èyítí ó ti san, yíò sì kúrò ní ibẹ̀, a ó sì kée kúrò nínú ìjọ mi, ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí;

11 Àti pé bí ọ̀run àti ilẹ̀ ayé bá tilẹ̀ kọjá lọ, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kì yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n yíò wá sí ìmúṣẹ.

12 Àti pé bí ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, bá gbọdọ̀ san owó náà, kíyèsíi, èmi, Olúwa, yíò san án fún un lẹ́ẹ̀kansíi ní orí ilẹ̀ Missouri, kí àwọn tí òun yíò gbà lè tún ní ẹ̀san gẹ́gẹ́bí ohun náà tí wọ́n ṣe;

13 Nítorí gẹ́gẹ́bí èyí tí wọ́n ṣe ni wọn yíò ṣe rí gbà, àní ní àwọn ilẹ̀ fún ogún ìní wọn.

14 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún àwọn ènìyàn mi—ẹ̀yin ní àwọn ohun púpọ̀ láti ṣe àti láti ronúpìwàdà lé lórí; nítorí kíyèsíi, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ti gòkè tọ̀mí wá, a kò sì dáríjì yín, nítorí ẹ̀yin lépa lati dámọ̀ràn ní àwọn ọ̀nà ti ara yín.

15 Àti pé ọkàn yín kò ní ìtẹ́lọ́rùn. Ẹ̀yin kò sì gbọ́ràn sí òtítọ́, ṣùgbọ́n ẹ ní inú dídùn nínú àìṣòdodo.

16 Ègbé ni fún yín ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, tí ẹ kò lè fi ohun ìní yín fún àwọn òtòṣì, nítorí àwọn ọrọ̀ yín yíò mú ìdíbàjẹ́ bá ẹ̀mí yín; èyí yíò sì jẹ́ ẹkún yín ní ọjọ́ ìbẹ̀wò, àti ti ìdájọ́, àti ti ìbínú: Ìkórè ti kọjá, ẹ̀ẹ̀rùn ti parí, a kò sí gba ọkàn mi là!

17 Ègbé ni fún yín ẹ̀yin òtòsì, tí ọkàn yín kò ní ìròbìnújẹ́, tí àyà yín kò sì ní ìrora, àti tí inú yín kò ní ìtẹ́lọ́rùn, àti tí ọwọ́ yín kò dúró ní mímú àwọn nkan ti ẹlòmíràn, tí ojú yín kún fún ojúkòkòrò, àti tí ẹ kìí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ tiyín!

18 Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún àwọn òtòṣì ọlọ́kàn mímọ́, tí ọkàn wọ́n ní ìròbìnújẹ́, àti tí àyà wọn ní ìrora, nítorí wọn yíò rí ìjọ̀ba Ọlọ́run tí ó nbọ̀ nínú agbára àti ògo nlá fún ìtúsílẹ̀ wọn; nítorí ọ̀rá ilẹ̀ náà yíò jẹ́ tiwọn.

19 Nítorí kíyèsíi, Olúwa yíò wá, àti èrè rẹ̀ yíò wà pẹ̀lú rẹ̀, òun yíò sì san fún olúkúlùkù, àwọn òtòṣì yíò sì yọ̀;

20 Àti àwọn ìran wọn yíò sì jogún ayé láti ìran dé ìran, láéláé àti láé. Àti nísisìyí èmi fi òpin sí sísọ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.