Ìpín 50
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 9 Oṣù Karũn 1831. Ìtàn Joseph Smith sọ pé díẹ̀ nínú àwọn alàgbà kò ní òye ìfarahàn onírúurú àwọn ẹ̀mí káàkiri ní orí ilẹ̀ ayé àti pé ìfihàn yìí ni a fi fúnni ní ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀ pàtàkì lórì ọ̀rọ̀ náà. Ìfarajọ àwọn ìyanu ti ẹ̀mí ni ó wọ́pọ̀ lààrin àwọn ọmọ ìjọ, díẹ̀ nínú wọ́n sọ pé àwọn ngba àwọn ìṣípayá àti àwọn ìfihàn.
1–5, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí èké wà káàkiri ní ilẹ̀ ayé; 6–9, Ègbé ni fún àwọn àgàbàgebè àti àwọn tí a ké kúrò nínú ìjọ; 10–14, àwọn alàgbà yíò nílati wàásù ìhìnrere nípa Ẹ̀mí; 15–22, Àwọn oníwàásù ati àwọn olùgbọ́ nilò lati ni ìfiyé nípasẹ̀ Ẹ̀mí; 23–25 Èyíinì tí kò múni dàgbàsókè kìí ṣe ti Ọlọ́run; 26–28, Àwọn olõtọ́ ni wọ́n ní ohun gbogbo; 29–36, Àdúrà àwọn tí a ti sọ di mímọ́ ni a dáhùn; 37–46 Krístì ni Olùṣọ́ Àgùntàn Rere àti Òkúta Isráẹ́lì.
1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, kí ẹ sì fi etí sí ohun Ọlọ́run alààyè; àti pé ẹ fiyèsí àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n náà èyí tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin ti béèrè àti bí ẹ ṣe fi ohùn ṣọ̀kan nípa ọ̀rọ̀ ìjọ, àti ti àwọn ẹ̀mí tí wọ́n ti jade káàkiri ní orí ilẹ̀ ayé.
2 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí wà tí wọ́n jẹ́ àwọn ẹ̀mí èké, tí wọ́n ti jade lọ káàkiri ní ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ntan aráyé jẹ.
3 Àti pẹ̀lú pé Sátánì ti wá ọ̀nà láti tàn yín jẹ, kí òun lè bì yín ṣubú.
4 Kíyèsíi, èmi, Olúwa, ti bojúwò yín, mo sì ti rí àwọn ìríra nínú ìjọ tí ó njẹ́wọ́ orúkọ mi.
5 Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olõtọ́ tí wọ́n sì fi ara dà, bóyá ní yíyè tàbí ní kíkú, nítorí wọn yíò jogún ìyè ayérayé.
6 Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn atannijẹ àti àwọn àgàbàgebè, nítorí, báyìí ni Olúwa wí, èmi yíò mú wọn wá sí ìdájọ́.
7 Kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn àgàbàgebè pọ̀ lààrin yín, àwọn tí wọ́n ti tàn àwọn díẹ̀ jẹ, èyí tí ó ti fún ọ̀tá ní agbára; ṣùgbọ́n ẹ kíyèsíi gbogbo ìwọ̀nyí ni a ó gbà padà;
8 Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ni a ó wá rí tí a ó sì ké kúrò, bọ́yá ní yíyè tàbí ní kíkú, àní bí èmi ti fẹ́; ègbé sì ni fún àwọn tí a ké kúrò nínú ìjọ mi, nítorí àwọn yìí kan náà ni ayé ti borí.
9 Nítorínáà, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn ó kíyèsára bíbẹ́ẹ̀kọ́ òun yíò ṣe èyíinì tí kìí ṣe nínú òtítọ́ àti òdodo ní iwájú mi.
10 Àti nísisìyí ẹ wá, ni Olúwa wí, nípa Ẹ̀mí, fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí á sọ àsọyé pọ̀, kí ó ba lè yée yín;
11 Ẹ jẹ́ kí á sọ àsọyé àní bí ènìyàn kan ṣe nronú pẹ̀lú ẹlòmíràn ní ojúkojú.
12 Nísisìyí, nígbàtí ènìyàn bá sọ àsọyé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yío yé ènìyàn, nítorí òun ronú bí ènìyàn; àní bẹ́ẹ̀ni èmi, Olúwa, yío sọ àsọyé pẹ̀lú yín kí ó lè yée yín.
13 Nítorínáà, èmi Olúwa béèrè ìbérè yìí lọ́wọ́ yín—kínni a yàn yín sí?
14 Láti wàásù ìhìnrere mi nípa Ẹ̀mí, àní Olùtùnú náà tí a rán wá láti kọ́ni ní òtítọ́.
15 Àti nígbà náà ni ẹ̀yin gba àwọn ẹ̀mí tí kò yée yín, ẹ̀yin sì gbà wọ́n pẹ̀lú èrò pé wọ́n jẹ́ ti Ọlọ́run; àti nínú èyí njẹ́ a dá yín láre bí?
16 Ẹ kíyèsíi ẹ̀yin yíó dáhùn ìbéèrè yìí fún ara yín; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi yíò ṣàánú fún yín; ẹni náà tí ó jẹ́ aláìlágbára lààrin yín ni a ó sọ di alágbára lẹ́hìnwá.
17 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí èmi bá yàn tí a sì rán jade láti wàásù ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà nípa Olùtùnú, nínú Ẹ̀mí òtítọ́, njẹ́ òun wàásù náà nípa Ẹ̀mí òtítọ́ tàbí nípa ọ̀nà míràn bí?
18 Àti bí ó bá sì jẹ́ nípa ọ̀nà míràn kìí ṣe ti Ọlọ́run.
19 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹni tí ó gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà, njẹ́ òun gbà á nípa Ẹ̀mí òtitọ́ tàbí nípa àwọn ọ̀nà míràn bí?
20 Bí ó bá jẹ́ nípa ọ̀nà míràn kìí ṣe ti Ọlọ́run.
21 Nitorínáà, kínni ṣe tí ẹ̀yin kò lè ní àgbọ́yé kí ẹ sì mọ̀, pé ẹni tí ó bá gba ọ̀rọ̀ náà nípa Ẹ̀mí òtítọ́ gbà á bí a ṣe wàásù rẹ̀ nípa Ẹ̀mí òtítọ́?
22 Nítorínáà, ẹni tí ó wàásù àti ẹni tí ó gbà á, ní àgbọ́yé ara wọn, àti pé àwọn méjèèjì ní ìdàgbàsókè síi, wọ́n sì jọ yọ̀ papọ̀.
23 Àti pé èyí tí kò bá múni dàgbàsókè kìí ṣe ti Ọlọ́run, òkùnkùn sì ni.
24 Èyí tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀; ẹni tí ó bá sì gba ìmọ́lẹ̀, àti tí ó tẹ̀síwájú nínú Ọlọ́run, gba ìmọ́lẹ̀ síi; ìmọ́lẹ̀ náà yíò sì máa mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú títí di ọjọ̀ pípé náà.
25 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi sì sọ̀ èyí kí ẹ̀yin ó lè mọ òtítọ́ náà, kí ẹ̀yin ó lè lé òkùnkùn kúrò láàrin yín;
26 Ẹni tí a bá yàn nípa ti Ọlọ́run tí a sì rán jade, òun náà ni a yàn lati jẹ́ gíga jùlọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ àti ìránṣẹ́ fún gbogbo ènìyàn.
27 Nítorínáà, òun jẹ́ olùní ohun gbogbo; nítorí ohun gbogbo wà ní abẹ́ àkóso rẹ̀, ní ọ̀run àti ní ayé, ìyè àti ìmọ́lẹ̀, Ẹ̀mí àti agbára, tí a rán jáde nípa ìfẹ́ Bàbá nípasẹ̀ Jésù Krístì, Ọmọ rẹ̀.
28 Ṣùgbọ́n kò sí ẹnikan tí ó ní ohun gbogbo bíkòṣe pé a sọ ọ́ di mímọ́ tí a sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.
29 Bí a bá sì sọ yín di mímọ́ tí a sì wẹ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin yíò béèrè ohunkóhun tí ẹ fẹ́ ní orúkọ Jésù a ó sì ṣe é.
30 Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí, a ó fi fún yín ohun tí ẹ̀yin bá béèrè; àti bí a ṣe yàn yín láti darí, àwọn ẹ̀mí yíò wà ní abẹ́ àkóso yín.
31 Nítorínáà, yíò sì ṣe, pé bí ẹ̀yin bá kíyèsí ìfarahàn ẹ̀mí kan tí kò yée yín, tí ẹ̀yin kò sì gba ẹ̀mí náà, ẹ̀yin yíò béèrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ Jésù; àti bí òun kò bá sì fi ẹ̀mí náà fún yín, nígbà náà ni ẹ̀yin yíò mọ̀ pé kìí ṣe ti Ọlọ́run.
32 A ó sì fi agbára fún yín ní orí ẹ̀mí náà; ẹ̀yin yíò sì kéde lòdì sí ẹ̀mí náà ní ohùn rara wípé kìí ṣe ti Ọlọ́run—
33 Kìí ṣe nípa fífi ẹ̀sùn kàn, kí ó má baà borí yín, tàbí pẹ̀lú yíyangàn tàbí yíyọ ayọ̀, bíbẹ́ẹ̀kọ́ òun yío gbáa yín mú nípa rẹ̀.
34 Ẹni tí ó bá gba láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí òun kà á sí ti Ọlọ́run; àti kí òun sì dunnú pé a ka òun sí ti Ọlọ́run ní yíyẹ láti gbà.
35 Àti nípa gbígbọràn àti ṣíṣe àwọn nkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin ti gbà, àti èyí tí ẹ̀yin ó gbà lẹ́hìnwá—àti ìjọba náà ni a fifún yín láti ọwọ́ Bàbá, àti agbára láti borí ohun gbogbo èyí tí a kò yàn láti ọwọ́ rẹ̀—
36 Ẹ sì kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ìbùkún ni fún ẹ̀yin tí ẹ ngbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí láti ẹnu ìránṣẹ́ mi, nítorí a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.
37 Ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Joseph Wakefield, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi, àti ìránṣẹ́ mi Parley P. Pratt ó jade lọ sí ààrin àwọn ìjọ kí wọ́n sì fún wọn lókun pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú;
38 Àti bákannáà ìránṣẹ́ mi John Corrill, tàbí iye àwọ́n ìránṣẹ́ mi tí a ti yàn sí ipò iṣẹ́ yìí, ẹ sì jẹ́ kí wọ́n ó ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajàrà; kí ẹnikẹ́ni ó má sì ṣe dí wọn lọ́wọ́ ní ṣíṣe èyí tí èmi ti yàn fún wọn—
39 Nítori-èyí, nínú ohun yìí ni a kò dá ìránṣẹ́ mi Edward Partridge láre; bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí òun ronúpìwàdà a ó sì dárí jì í.
40 Ẹ kíyèsíi, ẹ̀yin jẹ́ ọmọdé ẹ̀yin kò sì lè gba ohun gbogbo mọ́ra nísisìyí; ẹ̀yin gbọ́dọ̀ dàgbà nínú oore ọ̀fẹ́ àti nínú ìmọ̀ ti òtítọ́.
41 Ẹ má ṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọdé, nítorí ti èmi ni ẹ̀yin í ṣe, èmi sì ti borí ayé, ẹ̀yin sì jẹ́ ara àwọn tí Bàbá mi ti fi fún mi;
42 Àti pé kì yíò sí ọ̀kankan nínú àwọn tí Bàbá mi ti fi fúnmi tí yíò sọnù.
43 Àti Bàbá àti èmi jẹ́ ọ̀kan. Èmi wà nínú Bàbá àti Bàbá nínú mi; àti níwọ̀nbí ẹ̀yin ti gbà mí, ẹ̀yin wà nínú mi àti èmi nínú yín.
44 Nítorínáà, èmi wà ní ààrin yín, èmi sì ni olùṣọ́ àgùtàn rere, àti òkúta Isráẹlì. Ẹni tí ó bá kọ́lé sí orí àpáta yìí kì yíò ṣubú láé.
45 Àti pé ọjọ́ náà dé tán tí ẹ̀yin yíò gbọ́ ohùn mi àti tí ẹ ó rí mi, tí ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni.
46 Ẹ máa sọ́nà, nítorínáà, kí ẹ̀yin ó lè ṣetán. Àní bẹ́ẹ̀ ni. Amin.