Ìpín 113
Àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè kan ní orí àwọn ìwé kíkọ ti Isaiah, tí a fi fúnni lati ọwọ́ Wòlíì Joseph Smith, ní, tàbí nítòsí Far West, Missouri, Oṣù Kejì 1838.
1–6, Kùkùté Jéssè, ọ̀pá náà tí ó nbọ̀ láti inú rẹ̀, àti gbòngbò Jesse ni a dámọ̀; 7–10, Àwọn ìyókù ti Síónì tí ó ti fọ́nká ní ẹ̀tọ́ sí oyè àlùfáà, a sì pè wọ́n láti padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa.
1 Ta ni Kùkùté Jesse tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ẹsẹ èkíní, èkejì, ẹ̀kẹta, ẹ̀kẹrin, àti ẹ̀karũn ti orí ìkọkànlá ìwé Isaiah?
2 Lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí: Krístì ni.
3 Kínni ọ̀pá tí a sọ̀ nípa rẹ̀ ní ẹsẹ èkíní orí ìkọkànlá ìwé Isaiah, èyítí yío wá láti inú Kùkùté Jesse?
4 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí: O jẹ́ ìránṣẹ́ kan ní ọwọ́ Krístì, ẹnití ó jẹ́ àtẹ̀lé ti Jesse ní apákan àti ti Efráimù bákannáà, tàbí ti ilé Josefù, orí ẹnití a gbé agbára púpọ̀ lé.
5 Kínni gbòngbò ti Jesse tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ẹsẹ ẹ̀kẹwã orí ìkọkànlá?
6 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí, ó jẹ́ àtẹ̀lé ti Jesse kan, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ́ ti Josẹ́fù, ẹnití oyè àlùfáà jẹ́ tírẹ̀ ní ti ẹ̀tọ́, àti àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìjọba náà, fún ọ̀págun kan, àti fún kíkójọ àwọn ènìyàn mi ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn.
7 Àwọn ìbéèrè láti ọwọ́ Elias Higbee: Kínni ìtumọ̀ tí a ní nípa àṣẹ nínú Isaiah, orí 52, ẹsẹ èkínní, èyítí ó sọ pé: gbé agbára rẹ wọ̀, ìwọ Síónì—àti pé àwọn ènìyàn wo ni Isaiah tọ́ka sí?
8 Ó tọ́ka sí àwọn wọnnì tí Ọlọ́run yíó pè ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, àwọn ẹnití yíó ní agbára oyè àlùfáà láti tún mú Síónì padà wá, àti ìrapadà Ísráẹ́lì; àti láti gbé agbára rẹ̀ wọ̀ jẹ́ láti gbé àṣẹ oyè àlùfáà wọ̀, èyítí òun, Síónì, ní ẹ̀tọ́ sí nípasẹ̀ ìdílé; bákannáà láti padà sí agbára èyítí òun ti sọnù.
9 Kínni a níláti mọ̀ nípa kí Síónì tú ara rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ìdè ti ọrùn rẹ̀; ẹsẹ èkejì?
10 A níláti ní òye pé àwọn ìyókù tí ó fọ́nká ni a gbà níyànjú láti padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa láti ibi tí wọ́n ṣubú sí; èyítí bí wọ́n bá ṣe é, ìlérí Olúwa ni pé òun yíò bá wọn sọ̀rọ̀, tàbí fún wọn ní ìfihàn. Wo àwọn ẹsẹ ìkẹfà, ìkeje, àti ìkẹjọ. Àwọn ìdè ọrùn rẹ̀ ni àwọn ègún Ọlọ́run ní orí rẹ̀, tàbí àwọn ìyókù Ísráẹ́lì ní ipò fífọ́nká wọn ní ààrin àwọn Kèfèrí.