Ìpín 87
Ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀ lorí ogun, tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní tàbí nítòsí Kirtland, Ohio, 25 Oṣù Kejìlá 1832. Ní àkókò yìí àwọn àríyànjiyàn ní United States ní orí òwò ẹrú àti South Carolina tí ó fagilé àwọn owó orí ti ìjọba àpapọ̀ gbòdekan. Ìtàn ti Joseph Smith sọ pé “àwọn ìfarahàn wàhálà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè” ti ndi “ohun tí ó hànde síi” sí Wòlíì “ju bí wọn ti wà tẹ́lẹ̀rí láti ìgbà tí Ìjọ ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ jáde nínú aginjù.”
1–4, A sọ àsọtẹ́lẹ ogun láàrin àwọn Ìpínlẹ̀ Àríwá àti àwọn Ìpínlẹ Gúsù; 5–8, Àwọn ìdààmú nlá yíò wá sí orí gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.
1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí nípa àwọn ogun tí yíò wá sí ìmúṣẹ láìpẹ́, bẹ̀rẹ̀ níbi ìṣọ̀tẹ̀ ti South Carolina, èyítí yíò yọrí ní ìgbẹ̀hìn sí ikú àti òṣì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹmí;
2 Àti pé àkókò náà yíò dé tí a ó tú ogun jade sí orí gbogbo àwọn orílẹ̀ ède, bẹ̀rẹ̀ láti ìhín yìí.
3 Nítorí kíyèsíi, àwọn Ìpínlẹ̀ Gúsù ni a ó pín ní ìdojúkọ àwọn Ìpínlẹ̀ Àríwá, àti pé àwọn Ìpínlẹ̀ Gúsù náà yíò pe àwọn orílẹ̀-èdè míràn, àní orílẹ̀-èdè ti Great Britain, bí a ṣe npèé, àwọn pẹ̀lú yíò sì ké pe àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ní ọ̀nà áti gbèjà ara wọn ní ìdojúkọ àwọn orílẹ̀-èdè míràn; àti nígbànáà ni a ó tú ogun sí orí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.
4 Yíò sì ṣe, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwọn ẹrú yíò sì dìde dojúkọ àwọn olúwa wọn, àwọn ẹnití a ó tò lẹ́sẹsẹ àti tí a ó báwí fún ogun.
5 Yiò sì ṣe pẹ̀lú pé àwọn ìyókù tí a fi sílẹ̀ ní orí ilẹ̀ náà ni wọn yíò tò lẹ́sẹsẹ fúnra wọn, wọn yíò sì bínú gidigidi, wọn yíò sì yọ àwọn Kèfèrí lẹ́nu pẹ̀lú ìyọlẹ́nu tí ó dunni púpọ̀.
6 Àti báyìí, pẹ̀lú idà àti nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀ àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé yíò ṣọ̀fọ̀; àti pẹ̀lú ìyàn, àti àjàkálẹ̀ àrùn, àti ilẹ̀ ríru, àti ààrá ti ọ̀run, àti pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná tí ó rorò àti tí ó hàn gbangba, ni a ó mú kí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ó ní ìmọ̀lára ìbínú, àti ìrunú, àti ọwọ́ ìbáwí Ọlọ́run Alágbára Jùlọ, títí tí ìparun tí a pàṣẹ rẹ̀ yíò fi ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìparí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;
7 Kí igbe àwọn ẹni mímọ́, àti ti ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́, ó lè dẹ́kun wíwá sí etí Olúwa ti Sábáótì, lati ilẹ̀ ayé, sí gbígba ẹ̀san lára àwọn ọ̀tá wọn.
8 Nítorínáà, ẹ dúró ní àwọn ibi mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ṣípò padà, títí tí ọjọ́ Olúwa yíò fi dé; nítori kíyèsíi, ó nbọ̀ kánkán, ni Olúwa wí. Àmín.