Ìpín 59
Ìfihan tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Síónì, Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, 7 Oṣù Kẹjọ 1831. Ṣaájú àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ti ìfihàn yìí, a ya ilẹ̀ náà sí mímọ́, bí Olúwa ti darí, àti ilẹ̀ fún tẹ́mpìlì ní ọjọ́ iwájú ni a yà sọ́tọ̀. Ní ọjọ́ tí a gba ìfihàn yìí, Polly Knight, ìyàwó Joseph Knight Àgbà, kú, àkọ́kọ́ ọmọ Ìjọ tí ó kú ní Síónì. Àwọn ọmọ ìjọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ka ìfihàn yí kún bíi “fífún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní òfin bí a ti npa ọjọ́ ìsinmi mọ́ ati bí a ti ngba ààwẹ̀ àti àdúrà.”
1–4, Àwọn olõtọ́ Ẹni Mímọ́ ní Síónì ni a ó bùkún fún; 5–8, Wọ́n níláti ní ìfẹ́ àti kí wọ́n ó sin Olúwa kí wọn ó sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́; 9–19, Nípa pípa ọjọ́ Olúwa mọ́ ní mímọ́, àwọn Ẹni Mímọ́ ni a bùkún ní ti ara àti ní ti ẹ̀mí; 20–24, Àwọn olódodo ni a ṣe ìlérí àlãfíà fún ní ayé yìí àti ìyè ayérayé ni ayé tí ó nbọ̀.
1 Kíyèsi, ìbùkún, ni Olúwa wí, ni fún awọn tí wọn wá sí orí ilẹ́ yì pẹ̀lú àfojúsùn sí ogo mi nìkan, gẹ́gẹ́bí àwọn àsẹ mi.
2 Nítorí àwọn tí wọn wà láàyè yíò jogún ayé, àti àwọn tí wọ́n kú yíò sinmi nínú gbogbo làálàá wọn iṣẹ́ wọn yíò sì máa tọ̀ wọ́n lẹ́hìn; wọn yíò sì gba adé kan nínú ilé Bàbá mi, èyí tí mo ti pèsè fún wọn.
3 Bẹ́ẹ̀ni, ìbùkún ni fún àwọn ẹnití ẹsẹ̀ wọn dúró ní orí ilẹ̀ Síonì, ẹnití ó ti gbọ́ràn sí ìhìnrere mi; nítorí wọn yíò gba àwọn ohun dáradára ti ilẹ̀ ayé fún èrè wọn, yíò sì mú jade wá nínú agbára rẹ̀.
4 A ó sì dé wọn ní adé bákannáà pẹ̀lú àwọn ìbùkún láti òkè wá, bẹ́ẹ̀ni, àti pẹ̀lú àwọn àṣẹ tí kìí ṣe díẹ̀, ati pẹ̀lú àwọn ìfihàn ní àkókò wọn—àwọn tí wọ́n jẹ́ olódodo àti aláápọn níwájú mi.
5 Nítorínáà, èmi fún wọn ní òfin kan, tí ó sọ báyìí: Kí ìwọ kí ó fẹ́ràn Oluwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, pẹ̀lú gbogbo ipá rẹ, iyè rẹ, àti okun rẹ; àti ní orúkọ Jésù Krístì ni ìwọ yíò sìn ín.
6 Kí ìwọ kí ó fẹ́ràn ọmọnikéjì rẹ bí ara rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè; tàbí ṣe panságà, tàbí pàniyàn, tàbí ṣe ohunkóhun tí ó dàbí rẹ̀.
7 Ìwọ yío dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ nínú ohun gbogbo.
8 Ìwọ yío rúbọ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ nínú òdodo, àní èyíinì ti ìròbìnújẹ́ ọkàn àti ìrora àyà.
9 Ati kí ìwọ ó lè pa ara rẹ mọ́ ní kíkún síi láìní àbàwọ́n kúrò nínú ayé, ìwọ yíó lọ sí ilé àdúrà kí o sì rúbọ ounjẹ alẹ́ Olúwa ní ọjọ́ mímọ́ mi;
10 Nítorí lõtọ́ èyí ni ọjọ́ tí a yàn fún ọ láti sinmi nínú àwọn làálàá rẹ, àti lati fi ìfọkànsìn rẹ fún Ọ̀ga Ogo.
11 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ ìwọ yío rú ẹbọ àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ nínú òdodo ní gbogbo ọjọ́ àti gbogbo àkókò.
12 Ṣùgbọ́n ránti pé nínú èyí, ọjọ́ Olúwa, ìwọ yío rú ẹbọ-ọrẹ rẹ àti oúnjẹ Olúwa rẹ sí Ogá Ogo, ní jíjẹ́wọ́ àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ fún àwọn arákùnrin rẹ, àti níwajú Olúwa.
13 Àti ní ọjọ́ yìí ìwọ kì yío ṣe ohun kankan mìíràn, kàn jẹ́kí ounjẹ rẹ jẹ́ èyí tí ìwọ pèsè pẹ̀lú ọkàn kanṣoṣo kí ààwẹ̀ rẹ lè jẹ́ pípé, tàbí, ní ọ̀nà míràn, kí ayọ̀ rẹ lè kún.
14 Lõtọ́, èyí jẹ́ ààwẹ̀ gbígbà àti àdúrà, tàbí ní ọ̀nà míràn, ayọ̀ yíyọ̀ àti àdúrà.
15 Àti níwọ̀nbí ìwọ bá ṣe àwọn ohun wọ̀nyí pẹ̀lú ìdúpẹ́, pẹ̀lú ọkàn àti ìwò ìdùnnú, kìí ṣe pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹ̀rín, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni èyí, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkan ayọ̀ ati ìwò ìdùnnú—
16 Lõtọ́ ni mo wí, pé níwọnbí ìwọ bá ṣe èyí, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti ilẹ̀ náà jẹ́ tìrẹ, àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àti àwọn ti ó ngun orí igi àti àwọn tí ó nrìn ní orí ilẹ̀;
17 Bẹ́ẹ̀ni, àti ewéko ìgbẹ́, àti àwọn ohun dáradára tí ó njáde láti inú ilẹ̀, bóyá fún oúnjẹ tàbí fún aṣọ, tàbí fún àwọn ilé, tàbí fún àwọn àká, tàbí fún àwọn oko igi eléso, tàbí fún àwọn ọgbà, tàbí fún àwọn ọgbà àjàrà;
18 Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo ohun tí ó njade láti inú ilẹ̀, ní àkókò wọn, ni a dá fún ànfàní àti fún ìlò èniyàn, láti fún ojú ní ìdùnnú àti ọkàn ní ayọ̀;
19 Bẹ́ẹ̀ni, fún oúnjẹ àti fún aṣọ, fún ìtọ́wò àti fún òórùn, láti fún ara ní okun àti láti mú ọkàn jí pépé.
20 Ó sì dùn mọ́ Ọlọ́run nínú pé òun ti fi gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí fún enìyàn; nítorí fún ìdí èyí ni a ṣe dá wọn lati jẹ́ lílò, pẹ̀lú ìdájọ́, kìí ṣe ní àpọ̀jù, tàbí nípa ìrẹ́jẹ.
21 Àti nínú ohunkóhun kọ́ ni ènìyàn ti ṣẹ Ọlọ́run, tàbí kí ìbínú rẹ̀ gbóná sí ẹnìkẹ́ni, bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọn kò jẹ́wọ́ agbára rẹ̀ nínú ohun gbogbo, àti tí wọn kò gbọ́ràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀.
22 Kíyèsíi, èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti àwọn Wòlíì; nísisìyí, ẹ máṣe yọmí lẹ́nu mọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí.
23 Ṣùgbọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ pé ẹni tí ó bá ṣe àwọn iṣẹ́ òdodo yíò gba èrè rẹ̀, àní àlãfíà ní ayé yìí, àti ìyè ayérayé ni ayé tí nbọ̀.
24 Èmi, Olúwa, ti sọ ọ́, Ẹ̀mí sì jẹ́rìí àkọsílẹ̀. Amin.