Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 8


Ìpín 8

Ìfihan tí a fi fúnni nípasẹ Wòlíì Joseph Smith sí Oliver Cowdery, ní Harmony, Pennyslvania, Oṣù Kẹrin 1829. Nínú ipa iṣẹ́ títúmọ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Oliver, tí ó ntẹ̀síwájú gẹ́gẹ́bí akọ̀wé, ní kíkọ àwọn ohun tí Wòlíì npè, ní ìfẹ́-inú pé kí a bùn òun ní ẹ̀bùn ìtumọ̀. Olúwa dáhùn sí ẹbẹ̀ ọkàn rẹ̀ nípa fífúnni ní ìfihàn yìí.

1–5 Ìfihàn máa nwá nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, 6–12, Ìmọ̀ nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run àti agbára láti lè túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ ìgbàanì nwá nípa ìgbàgbọ́.

1 Oliver Cowdery, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé dájúdájú bí Olúwa ti wà láàyè, ẹnití í ṣe Ọlọ́run àti Olùràpadà rẹ, àní bẹ́ẹ̀ dájú ni ìwọ yíò gba ìmọ̀ ohun-kohun tí ìwọ yíò bá bèerè nínú ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ọkàn òtítọ́, ní gbígbàgbọ́ pé ìwọ yíò gbà ìmọ̀ nípa àwọn àkọsílẹ̀ fífín ti àtijọ́, tí wọn jẹ́ ti igbàanì, tí wọn ní àwọn abala wọnnì lára ìwé mímọ́ mi nínú, nípa èyí tí a ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìṣípayá Ẹ̀mí mi.

2 Bẹ́ẹ̀ni, kíyèsíi, èmi yíò sọ fún ọ nínú ọkàn rẹ àti ní inú ẹ̀mí rẹ, lati ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí yíò wá sí orí rẹ àti èyí tí yíò máa gbé nínú ọkàn rẹ.

3 Nísisìyí, kíyèsíii èyí ni ẹ̀mí ìfihàn; kíyèsíi èyí náà ni ẹ̀mí nípasẹ̀ èyí tí Mósè fi mú àwọn ọmọ Israeli la Òkun Pupa kọjá ní orí ìyàngbẹ ilẹ̀.

4 Nítorínáà èyí ni ẹ̀bùn rẹ; ṣe àmúlò rẹ̀, àti pé alábùkúnfún ni ìwọ, nítorí èyí yíò gbà ọ́ sílẹ̀ ní ọwọ̀ àwọn ọ̀tá rẹ, nígbàtí, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, wọn yíò pa ọ́, kí wọn sì mú ọkàn rẹ wá sí ìparun.

5 Áà, rantí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kí o sì pa àwọn òfin mi mọ́. Rántí, èyí ni ẹ̀bùn rẹ.

6 Nísìsìyí èyí kìí ṣe gbogbo ẹ̀bùn rẹ; nítorí ìwọ tún ní ẹ̀bùn míràn, èyí tíí ṣe ẹ̀bùn Áárónì; kíyèsíi, èyí ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan fún ọ.

7 Kíyèsíi, kò sí agbára míràn, bíkòṣe agbára Ọlọ́run, tí ó lè mú kí ẹ̀bùn Áárónì yìí wà pẹ̀lú rẹ.

8 Nítorínáà, má ṣe iyè méjì, nítorí ẹ̀bùn Ọlọ́run ni; ìwọ yíò sì dìí mú ní ọwọ́ rẹ, láti ṣe àwọn iṣẹ́ yíyanilẹ́nu: àti pé kò sí agbára tí yíò lè gbàá kúrò ní ọwọ́ rẹ, nítorí iṣẹ́ Ọlọ́run ni.

9 Àti, nítorínáà, ohunkóhun tí ìwọ bá bèerè ní ọwọ́ mi pé kí èmi ó sọ fún ọ nípa ọ̀nà yìí, èyí ni èmi yíò fi fún ọ, ìwọ yíò sì ní ìmọ̀ nípa rẹ̀.

10 Rántí pé láì sí ìgbàgbọ́ ìwọ kò lè ṣe ohunkóhun, nítorínáà bèerè pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Má ṣe fi àwọn nkan wọ̀nyí ṣe eré; má ṣe bèerè fún èyí tí kò yẹ.

11 Béèrè kí ìwọ lè mọ̀ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, àti kí ìwọ baà lè túmọ̀ àti lati gba ìmọ̀ nínú gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ wọnnì èyítí a ti fi pamọ́, tí wọn jẹ́ mímọ́; àti gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ ni a ó ṣe fún ọ.

12 Kíyèsíi, èmi ni Ẹnití Ó ti sọ ọ́; àti pé èmi kannáà ni ó ti bá ọ sọ̀rọ̀ láti àtètèkọ́ṣe. Àmin.