Ìpín 72
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 4 Oṣù Kejìlá 1831. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn alàgbà àti àwọn ọmọ ìjọ ti kó ara wọn jọ láti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ojúṣe wọn àti láti túbọ̀ ní òye síi nínú àwọn ìkọ́ni ti ìjọ. Ìpín yìí jẹ́ àkópọ̀ àwọn ìfihàn mẹ́ta tí a gbà ní ọjọ́ kan náà. Àwọn ẹsẹ 1 títí dé 8 sọ ìpè Newel K. Whitney di mímọ̀ bíi bíṣọ́ọ̀pù. Nígbànáà a pè é a sì ṣe ìlànà fún un, lẹ́hìn náà ni a gba àwọn ẹsẹ 9 títi dé 23, tí ó fúnni ní àfikún ọrọ̀ nípa àwọn ojúṣe bíṣọ́ọ̀pù. Lẹ́hìnnáà, àwọn ẹsẹ 24 títí dé 26 ni a fifúnni ní pípèsè àwọn òfìn nípa pípéjọpọ̀ sí Síónì.
1–8, Àwọn alàgbà niláti ṣírò iṣẹ́ ìríjú wọn fun bíṣọ́ọ̀pù; 9–15, Bíṣọ́ọ̀pù náà ni yíò máa pa ilé ìṣúra mọ́ tí yíò sì máa mójútó àwọn aláìní àti àwọn tálákà; 16–26, Àwọn Bíṣọ́ọ̀pù ni wọn níláti jẹ́rìí sí yíyẹ àwọn alàgbà.
1 Ẹ fetísílẹ̀, kí ẹ sì tẹ́tí sí ohùn Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ ti kó ara yín jọ papọ̀, tí ẹ jẹ́ àlùfáà gíga ìjọ mi, ẹ̀yin ẹnití a ti fi ìjọ̀ba àti agbára fún.
2 Nítorí lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí, ó jẹ́ títọ nínú mi pé kí á yan bíṣọ́ọ̀pù kan fún yín, tàbí ní ààrin yín, fún ìjọ ní apákan yìí ti ọgbà ajarà Olúwa.
3 Àti lõtọ́ nínú ohun yìí ẹ̀yin ti ṣe ìṣe ọgbọ́n, nítorítí Olúwa nbéèrè, ní ọwọ́ olúkúlùkù iríjú, lati ṣe ìṣirò iṣẹ́ ìríjú rẹ̀, ní àkókò yìí àti ní ayérayé.
4 Nítorí ẹni náà tí ó jẹ́ olõtọ́ àti ọlọgbọ́n ní àkókò yìí ni a ó kà yẹ láti jogún àwọn ibùgbé tí a ti pèsè sílẹ̀ fún un lati ọwọ́ Bàbá mi.
5 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn alàgbà ìjọ ní apákan yìí ti ọ̀gbà ajarà mi ni yíò ṣe ìṣirò iṣẹ́ ìríjú wọn fún bíṣọ́ọ̀pù, ẹni tí a ó yàn láti ọwọ́ mi ní apákan yìí ti ọgbà ajarà mi.
6 Àwọn nkan wọ̀nyí ni yíò wà ní àkọsílẹ̀, lati gbée fún bíṣọ́ọ̀pù ní Síónì.
7 Àti pé ojúṣe ti bíṣọ́ọ̀pù ni a ó sọ di mímọ̀ nípa àwọn òfin tí a ti fi fúnni, àti nípa ohùn ìpàdé àpéjọpọ̀ náà.
8 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney ni ẹni náà tí a ó yàn tí a ó sì ṣe ìlànà fún sí ipò agbára yìí. Èyí ni ìfẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, Olùràpadà yín. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amín.
9 Ọ̀rọ̀ Olúwa, ní àfikún sí òfin èyí tí a ti fi fúnni, èyi tí ó sọ ojúṣe bíṣọ́ọ̀pù di mímọ̀ ẹnití a ti ṣe ìlànà fún sí ìjọ ní apákan yìí ti ọ̀gbà ajarà, èyí tí ó jẹ́ oòtọ́ yìí—
10 Láti pa ilé ìṣúra Olúwa mọ́; láti gba owó ìjọ ní apákan yìí ti ọ̀gbà ajarà;
11 Láti ṣe ìṣirò àwọn alàgbà bí a ṣe pàṣẹ ní ìṣaájú; àti láti mójútó àwọn àìní wọn, àwọn ẹnití yíò san owó fún èyi tí wọ́n bá gbà, níwọ̀nbí wọ́n bá ní agbára lati san án;
12 Pé kí á lè ya èyí sọ́tọ̀ bákannáà fún ire ti ìjọ, fún àwọn aláìní àti àwọn tálákà.
13 Ẹni náà tí kò bá sì ní agbára láti san, ìṣirò kan ni a ó ṣe tí a ó sì fi lé bíṣọ́ọ̀pù ti Síónì lọ́wọ́, ẹni tí yíò san gbèsè náà lati inú èyí tí Olúwa bá fi sí ọwọ́ rẹ̀.
14 Àti àwọn iṣẹ́ ti àwọn olõtọ́ tí wọ́n ṣiṣẹ́ nínú àwọn ohun ti ẹ̀mí, nípa ṣíṣe ìpínfúnni ìhìnrere àti àwọn ohun ti ìjọba náà sí ìjọ, àti sí aráyé, yíò dáhùn fún gbèsè náà sí bíṣọ́ọ̀pù ní Síónì;
15 Báyìí ni ó jade wá láti inú ìjọ, nítorí gẹ́gẹ́bí òfin olúkúlùkù ènìyàn tí ó bá wá sí Síónì gbọ́dọ̀ fi gbogbo àwọn nkan lélẹ̀ níwájú bíṣọ́ọ̀pù ní Síónì.
16 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé bí olúkúlùkù alàgbà ní apákan yìí ti ọgbà ajarà ṣe gbọ́dọ̀ fún bíṣọ́ọ̀pù ní ìṣirò iṣẹ́ ìríjú rẹ̀ ní apákan yìí ọgbà ajarà—
17 Ìwé ẹ̀rí kan láti ọwọ́ onídajọ́ tàbí bíṣọ́ọ̀pù ní apákan yìí ti ọgbà ajàrà náà, sí bíṣọ́ọ̀pù ní Síónì, láti ṣe olúkúlùkù ènìyàn ní ìtẹ́wọ́gbà, àti ní ìdáhùn sí ohun gbogbo, fún ogún ìní kan, àti lati jẹ́ gbígbà bíi ọlọgbọ́n ìríjú àti olõtọ́ òṣìṣẹ́.
18 Bí bẹ́ẹ̀kọ́ òun kì yíò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà sí bíṣọ́ọ̀pù ní Síónì.
19 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù alàgbà tí yíò ṣe ìṣirò fún bíṣọ́ọ̀pù ti ìjọ ní apákan yìí ti ọgbà ajarà náà ó gba ìkaniyẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọ tàbí àwọn ìjọ, ní ibi tí òun ti nṣiṣẹ́, kí ó lè mú kí òun fúnrarẹ̀ àti àwọn ìṣirò rẹ̀ ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà nínú ohun gbogbo.
20 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ mi tí a ti yàn bíi àwọn ìríjú ní orí àwọn àníyàn àròbájọ nípa ìjọ̀ mi ó ní ẹ̀tọ́ sí ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ bíṣọ́ọ̀pù tàbí àwọn bíṣọ́ọ̀pù nínú ohun gbogbo—
21 Kí àwọn ìfihàn náà lè jẹ́ títẹ̀ jade, kí wọ́n ó sì jáde lọ sí àwọn òpin ilẹ̀ ayé; kí àwọn pẹ̀lú ó lè gba owó èyí tí yíò jẹ́ ànfàní fún ìjọ nínú ohun gbogbo.
22 Kí àwọn bákannáà le mú kí àwọn fúnrawọn jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà nínú ohun gbogbo, kí a sì ṣírò wọn bíi ọlọgbọ́n ìríjú.
23 Àti nísisìyí, kíyèsíi, èyi yíò jẹ́ àpẹrẹ kan fún gbogbo ìtànkálẹ̀ àwọn ẹka ijọ mi, ní èyíkéèyí ilẹ̀ tí a ó gbé wọn kalẹ̀ sí. Àti nísisìyí èmi mú àwọn ọ̀rọ̀ mi wá sí òpin. Amín.
24 Àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ ní àfikún sí àwọn òfin ti ìjọba náà, nípa àwọn ọmọ ìjọ—àwọn tí a ti yàn nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti gòkè lọ sí Síónì, àti àwọn tí wọ́n ní ànfààní láti gòkè lọ sí Síónì—
25 Ẹ jẹ́ kí wọ́n ó mú ìwé ẹ̀rí kan lọ sí ọ̀dọ̀ bíṣọ́ọ̀pù láti ọ̀wọ́ alàgbà mẹ́ta nínú ìjọ, tàbí ìwé ẹ̀rí kan láti ọwọ́ bíṣọ́ọ̀pù;
26 Bí bẹ́ẹ̀kọ́ ẹni náà tí yíò gòkè lọ sí ilẹ̀ Síónì ni a kì yíò ṣírò bíi ọlọgbọ́n ìríjú. Èyí jẹ́ àpẹrẹ bákannáà. Amín.