Ìpín 55
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wólĩ Joseph Smith sí William W. Phelps, ní Kirtland, Ohio, 14 Oṣù Kẹfà 1831. William W. Phelps, atẹ̀wé kan, àti àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Kirtland, Wòlíì sì wá ojú Olúwa fún ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
1–3, William W. Phelps ni a pè tí a sì yàn láti ṣe ìrìbọmi, láti jẹ́ yíyàn bí alàgbà, àti lati wàásù ìhìnrere; 4, Bákannáà òun yíò kọ ìwé fún àwọn ọmọdé ní àwọn ilé ìwé ti Ìjọ; 5–6, Òun nílati rin ìrìnàjò lọ sí Missouri, ní ibi tí yíò jẹ́ agbègbè àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.
1 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Wílliam, bẹ́ẹ̀ni, àní Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni a pè tí a sì yàn; àti lẹ́hìn tí a bá rì ọ́ bọmi pẹ̀lú omi, èyí tí ó jẹ́ pé bí ìwọ̀ bá ṣe é pẹ̀lú àfojúsùn ògo mi nìkan, ìwọ yíò ní ìwẹ̀nùmọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ nípa gbígbé ọwọ́ léni.
2 Àti pé nígbànáà ni a ó yàn ọ́ láti ọwọ́ ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, láti di alàgbà fún ìjọ yìí, láti wàásù ironúpìwàdà àti ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nípa ìrìbọmi ní orúkọ Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.
3 Àti ní orí ẹnikẹ́ni tí ìwọ bá gbé ọwọ́ rẹ lé, tí wọ́n bá jẹ́ oníròbìnújẹ́ ọkàn níwájú mi, ìwọ yíò ní agbára láti fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún wọn.
4 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, a ó yàn ọ́ láti ṣe àtìlẹ́hìn fún ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery láti ṣe iṣẹ́ ìwé títẹ̀, àti ṣíṣe àṣàyàn àti kíkọ àwọn ìwé fún àwọn ilé ìwé nínú ìjọ yìí, kí àwọn ọmọdé kékèké pẹ̀lú lè máa gba ẹ̀kọ́ níwájú mi bí ó ṣe jẹ́ inú dídùn sí mi.
5 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, nítorí èyí ni ìwọ yíò ṣe rin ìrìnàjò pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi Joseph Smíth Kekeré, àti Sidney Rigdon, kí á lè fi ẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀ ní ilẹ̀ ìní rẹ láti ṣe iṣẹ́ yìí.
6 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Joseph Coe bákannáà rin ìrìnàjò rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Àwọn ìyókù ni a ó sọ di mímọ̀ lẹ́hìnwá, àní bí èmi ṣe fẹ́. Amin.