Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 44


Ìpín 44

Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ní Kirtland, Ohio, ní abala tí ó kẹ́hìn nínú Oṣù Kejì 1831. Ní ìgbọ́ràn sí àwọn ìlànà tí a gbé jáde níhĩn yìí, ìjọ yan ìpadé àpéjọpọ̀ kan lati jẹ́ ṣíṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù Kẹfà tí ó tẹ̀lée.

1–3, Àwọn alàgbà ni yíò kó ara wọn jọ́ ní ìpàdé àpéjọpọ̀; 4–6, Wọ́n yíò ṣe ètò ní ìbámu sí àwọn òfin ti ilẹ̀ náà wọn yíò sì ṣe ìtọ́jú àwọn talakà.

1 Ẹ kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún yín ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi, ó jẹ́ yíyẹ nínú mi pé kí á pe àwọn alàgbà ìjọ mi papọ̀, láti ìlà oòrùn ati lati ìwọ̀ rẹ̀, àti láti àríwá àti láti gúúsù, nípasẹ̀ ìwé kíkọ tàbí ní àwọn ọ̀nà míràn.

2 Àti yíò sì ṣe, pé níwọ̀nbí wọ́n bá jẹ́ olõtọ́, àti tí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú mi, èmi yíò tú Ẹ̀mí mi sí orí wọn ní ọjọ́ náà tí wọ́n bá kó ara wọn jọ papọ̀.

3 Àti yíò sì ṣe pé wọn yíò jade lọ sínú àwọn agbègbè yípo, wọ́n yíò sì wàásù ironúpìwàdà sí àwọn ènìyàn náà.

4 Púpọ̀ ní a ó sì yí lọ́kàn padà, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yíò gba agbára láti ṣe ètò ara yín gẹ́gẹ́bí àwọn òfin ti ènìyàn;

5 Pé kí àwọn ọ̀tá yín má baà ní agbàra ní orí yín; kí ẹ̀yin ó lè jẹ́ pípamọ́ nínú ohun gbogbo; kí a lè mú kí ó ṣeéṣe fún yín láti pa àwọn òfin mi mọ́; kí olúkúlùkù ìdè ó lè já nípa èyí tí ọ̀tá nlépa láti pa àwọn ènìyàn mi run.

6 Ẹ kíyèsíi, mo wí fún yín, pé ẹ gbọ́dọ̀ bẹ àwọn talakà ati aláìní wò kí ẹ sì mójútó ìrọ̀rùn wọn, kí á lè pa wọ́n mọ́ títí tí a ó fi ṣe ohun gbogbo ní ìbámu sí òfin mi èyí tí ẹ̀yin ti gbà. Amin.