Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 30


Ìpín 30

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí David Whitmer, Peter Whitmer Kékeré, àti John Whitmer, ní Fayette, New York, Oṣù Kẹsãn 1830, lẹ́hìn ìpàdé àpapọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta ní Fayette, ṣùgbọ́n kí àwọn alàgbà ìjọ tó pínyà. Ní ìpilẹ̀sẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a tẹ̀ jade gẹ́gẹ́bí ìfihàn mẹ́ta; a pa wọ́n pọ̀ di ìpín kan lati ọwọ́ Wòlíì fún àtúntẹ̀ ìwé Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ti 1835.

1–4, David Whitmer gba ìbawí fún kíkùnà láti sìn pẹ̀lú aápọn; 5–8, Peter Whitmer Kékeré ni yíò bá Olíver Cowdery lọ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì; 9–11, John Whitmer ni a pè láti wàásù ìhìnrere.

1 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, David, pé ìwọ ti bẹ̀rù ènìyàn ìwọ kò sì gbékẹ̀ lé mi fún okun bí ó ṣe yẹ.

2 Ṣùgbọ́n ọkàn rẹ ti wà nínú àwọn ohun ti ayé ju àwọn ohun tèmi, Ẹnití ó dá ọ, àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ èyí tí a pè ọ́ sí; àti pé ìwọ̀ kò fi iyè sí Ẹ̀mí mi, àti sí àwọn wọnnì tí a fi ṣe olórí fún ọ, ṣùgbọ́n a ti yí ọ lọ́kàn padà lati ọwọ́ àwọn tí èmi kò pàṣẹ fún.

3 Nítorínáà, a fi ọ́ sílẹ̀ láti béèrè fún ara rẹ ní ọwọ́ mi, àti kí o sì ṣe àṣàrò ní orí àwọn ohun tí ìwọ ti gbà.

4 Àti pé ìbugbé rẹ yío wà ní ilé bàbá rẹ, títí tí èmi yíò fi fún ọ ní àwọn òfin síwáju síi. Ìwọ yíò sì máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ìjọ, àti níwájú gbogbo ènìyàn ayé, àti ní àwọn agbègbè yíká. Amin.

5 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, Peter, pé ìwọ yíò rin ìrìnajò rẹ pẹ̀lú arákùnrin rẹ Oliver; nítorí àkókò náà ti dé tí ó yẹ ní ojú mi pé kí iwọ ó la ẹnu rẹ láti kéde ìhìnrere mi; nítorínáà, má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n fi iyè sí àwọn ọ̀rọ̀ mi àti ìmọ̀ràn arákùnrin rẹ, èyí tí òun yíò fún ọ.

6 Àti pé kí á pọ́n ọ lójú nínú gbogbo àwọn ìpọ́njú rẹ̀, nígbàgbogbo kí ìwọ máa gbé ọkàn rẹ sókè sími nínú àdúrà àti ìgbàgbọ́, fún ìtúsílẹ̀ rẹ̀ àti ti ìwọ; nítorí èmi ti fi agbára fún un láti kọ́ ìjọ mi lààrin àwọn ará Lámánì.

7 Àti pé kò sí ẹnikẹ́ni tí èmi ti yàn lati jẹ́ olùbádámọ̀ràn rẹ̀ lé e lóri nínú ìjọ, nípa àwọn ohun ti ìjọ, bí kò ṣe arákùnrin rẹ̀, Joseph Smith Kékeré.

8 Nítorínáà, fi iyè sí àwọn ohun wọ̀nyí kí o sì jẹ́ aláápọn ní pípa àwọn òfin mi mọ́, a ó sì bùkún ọ pẹ̀lú ayérayé. Àmín.

9 Kíyèsíi, mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi John, pé ìwọ yíò bẹ̀rẹ̀ láti àkókò yìí lọ láti máa kéde ìhìnrere mi, pẹ̀lú ohùn fèrè.

10 Àti pé iṣẹ́ ṣíṣe rẹ yíò wà ní ibùgbé arákùnrin rẹ Philip Burroughs, àti ní agbègbè náà yíká, bẹ́ẹ̀ni, ní gbogbo ibití a ti lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, títí tí èmi yíò fi pàṣẹ fún ọ láti lọ kúrò níbẹ̀.

11 Àti pé gbogbo iṣẹ́ ṣíṣe rẹ yíò wà ní Síónì, pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, láti ìsisìyí lọ; bẹ́ẹ̀ni, ìwọ yíò máa la ẹnu rẹ nígbà gbogbo sí ipa ọ̀nà mi, láì bẹ̀rù ohun tí ènìyàn lè ṣe, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ. Amin.