Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 108


Ìpín 108

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 26 Oṣù Kejìlá 1835. Ìpín yìí ni a gbà sí ìbéèrè ti Lyman Sherman, ẹnití a ti yàn tẹ́lẹ̀ bíi ọ̀kan nínú àwọn ãdọ́rin àti ẹnití ó ti wá sí ọ̀dọ̀ Wòlíì pẹ̀lú ìbéèrè kan fún ìfihàn lati sọ ojúṣe rẹ̀ di mímọ̀.

1–3 Lyman Sherman ni a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì; 4–5, Òun níláti jẹ́ kíkà mọ́ àwọn alàgbà tí wọn nṣíwájú ìjọ; 6–8, Òun ni a pè láti wàásù ìhìnrere àti láti mú àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ́kàn le.

1 Lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Lyman: A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, nítorípé ìwọ ti gba ohùn mi gbọ́ ní wíwá sí ìhín ní òwúrọ̀ yìí láti gba ìmọ̀ràn lati ọ̀dọ̀ ẹni náà tí èmi ti yàn.

2 Nítorínáà, jẹ́ kí ọkàn rẹ ó wà ní ìsinmi nípa ti ìdúró rẹ ní ti ẹ̀mí, kí o má sì ṣe takò ohùn mi mọ́.

3 Sì dìde sókè kí o sì kíyèsára síi láti àkókò yìí lọ ní ṣíṣe àkíyèsí àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ, èyítí ìwọ̀ ti jẹ́ àti tí o njẹ́, a ó sì bùkún ọ pẹ̀lú àwọn ìbùkún nlá.

4 Fi sùúrù dúró títí tí a ó pè àpéjọ ọ̀wọ̀ ti àwọn ìránṣẹ́ mi, nígbànáà ni a ó rántí rẹ pẹ̀lú àwọn alàgbà tèmi àkọ́kọ́, ìwọ yíò sì gba ẹ̀tọ́ nípa jíjẹ-oyè-àlùfáà pẹ̀lú ìyókù àwọn alàgbà mi tí èmi ti yàn.

5 Kíyèsíi, èyí ni ìlérí ti Bàbá sí ọ bí ìwọ bá tẹ̀síwájú ní jíjẹ́ olõtọ́.

6 A ó sì mú èyí ṣẹ ní orí rẹ ní ọjọ́ náà tí ìwọ yíò ní ẹ̀tọ́ láti wàásù ìhìnrere mi níbikíbi tí mo bá rán ọ, láti ìsisìyí lọ láti àkókò náà.

7 Nítorínáà, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le nínú gbogbo ọ̀rọ̀ sísọ rẹ, nínú gbogbo àwọn àdúrà rẹ, nínú gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ, àti nínú gbogbo àwọn ìṣe rẹ.

8 Sì kíyèsíi, àti wòó, èmi wà pẹ̀lú rẹ láti bùkún ọ àti láti gbà ọ títí láé. Àmín.