Ìpín 54
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Newel Knight, ní Kirtland, Ohio, 10 Oṣù Kẹfà 1831. Àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ngbé ní Thompson, Ohio, kò fi ohùn ṣọ̀kan ní orí ìbéèrè tí ó nííṣe pẹ̀lú yíya ohun ìní sí mímọ́ fún Olúwa. Ìwà ìmọ ti ara ẹni nìkan àti ojúkòkòrò fi ara hàn. Ní àtẹ̀lé iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn Shakers (wo àkọlé sí ìpín 49), Leman Copley ti sẹ́ májẹ̀mú rẹ̀ lati fi ilẹ̀ oko nlá rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ibi ogún ìní fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọn ndé láti Colesville, New York. Gẹ́gẹ́bíi àyọrísí, Newel Knight (olùdarí àwọn ọmọ ìjọ tí wọn ngbé ní Thompson) àti àwọn alàgbà míràn wá si ọ̀dọ̀ Wòlíì láti béèrè bí wọn yíò ṣe tẹ̀síwájú. Wòlíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa ó sì gba ìfihàn yìí, èyítí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ ìjọ ní Thompson lati fi oko Leman Copley sílẹ̀ kí wọn ó sì rin ìrìnàjò sí Missouri.
1–6, Àwọn Ẹni Mímọ́ gbọ́dọ̀ pa májẹ̀mú ìhìnrere mọ́ láti jèrè àánú; 7–10 Wọ́n gbọ́dọ̀ ní sùúrù nínú ìpọ́njú.
1 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí, àní Álfà àti Òmégà, ìbẹrẹ̀ àti òpin, àní ẹni náà tí a kàn mọ́ àgbélẽbú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé—
2 Kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Newel Knight, ìwọ yíò dúró ṣinṣin ní ipò iṣẹ́ èyí tí èmi ti yàn ọ́ sí.
3 Bí àwọn arákùnrin rẹ bá sì fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, ẹ jẹ́ kí wọ́n ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti pé kí wọ́n rẹ ara wọ́n sílẹ̀ ní tòótọ́ ní iwájú mi kí wọ́n sì ní ìròbìnújẹ́.
4 Àti pé bí májẹ̀mú tí wọ́n dá pẹ̀lú mi tí di rírékọjá, àní bẹ́ẹ̀ ni ó ti di òfo àti aláìlágbára.
5 Àti pé ègbé ni fún ẹni náà tí ẹ̀ṣẹ̀ yìí tí ọwọ́ rẹ̀ wá, nítorí ìbá sàn fún un kí òun rì sí ibi jíjìn nínú òkun.
6 Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún àwọn tí wọ́n ti pa májẹ̀mú mọ́ tí wọ́n sì kíyèsí òfin, nítorítí wọn yíò rí àánú gbà.
7 Àti nísisìyí, ẹ dìde kí ẹ sì sá kúrò ní orí ilẹ̀ náà, bí bẹ́ẹ̀kọ́ kí àwọn ọ̀tá yín má baà kọlù yín; àti pé ẹ rin ìrìnàjò yín, kí ẹ sì yan ẹni tí ẹ bá fẹ́ lati jẹ́ olórí fún yín, tí yíò sì máa san owó fún yín.
8 Àti pé báyìí ni ẹ̀yin yíò rin ìrìnàjò yín lọ sí àwọn agbègbè ìhà ìwọ̀ oòrùn, lọ sí ìlẹ̀ Missouri, sí igun ààlà àwọn ará Lámánì.
9 Lẹ́hìn tí ẹ bá sì ti parí rírìn ìrìnàjò, kíyèsíi, mo wí fún yín, kí ẹ̀yin ó lépa lati wá nkan ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn, títí tí èmi yíò fi pèsè ibi kan fún yín.
10 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, ẹ ní sùúrù nínú ìpọ́njú títí tí èmi yíò fi dé; àti, ẹ kíyèsíi, èmi nbọ̀ kánkán, èrè mi sì nbẹ pẹ̀lú mi, àwọn tí wọ́n sì ti ṣe àfẹ́rí mi ní kùtùkùtù yíò rí ìsinmi fún ọkàn wọn. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amín.