Ìpín 112
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Thomas B. Marsh, ní Kirtland, Ohio, 23 Oṣù Keje 1837. Ìfihàn yìí ni a gbà ní ọjọ́ tí àwọn Alàgbà Heber C. Kimball àti Orson Hyde kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere sí Thomas B. Marsh nípa Àwọn Àpóstélì Méjìlá ti Ọ̀dọ́ Àgùtàn náà. Wòlíì ṣe àkọsílẹ̀ pé ìfihàn yìí ni a gbà ní ọjọ́ náà tí a kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere ní England. Thomas B. Marsh ni Ààrẹ ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá náà ní àkókò yìí.
1–10, Àwọn Méjìlá náà niláti ránṣẹ́ ìhìnrere kí wọ́n ó sì gbé ohùn ìkìlọ̀ sókè sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ènìyàn; 11–15, Wọ́n níláti gbé àgbélẽbú wọn, kí wọ́n ó tẹ̀lé Jésù, kí wọ́n ó sì bọ́ àwọn àgùtàn Rẹ̀; 16–20, Àwọn tí wọ́n bá gba Àjọ Ààrẹ Ìkínní gba Olúwa; 21–29, Òkùnkùn bo orí ilẹ̀ ayé, kìkì àwọn tí wọ́n bá sì gbàgbọ́ àti tí a rìbọmi ni a ó gbàlà; 30–34, Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Àwọn Méjìlá ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìgbà ìríjú náà ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò.
1 Lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí fún ìwọ ìránṣẹ́ mi Thomas: Èmi ti gbọ́ àwọn àdúrà rẹ; àti pé àwọn ìtọrẹ àánú rẹ ti gòkè wá bíi ìrántí ní iwájú mi, ní ìdúró fún àwọn wọnnì, àwọn arákùnrin rẹ, tí a ti yàn láti jẹ́rìí orúkọ mi àti láti rán an sí òkèrè láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn, àti tí a yàn nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi tí wọ́n jẹ́ ohun èlò.
2 Lõtọ́ ni mo wí fún ọ, àwọn ohun díẹ̀ ti wà nínú ọkàn rẹ àti pẹ̀lú rẹ èyítí èmi, Olúwa, kò ní inú dídùn sí.
3 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀nbí ìwọ ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ a ó gbé ọ ga; nítorínáà, gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a ti dárí jì ọ́.
4 Jẹ́kí ọkàn rẹ ó tújúká ní iwájú mi; ìwọ yíò sì jẹ́rìí orúkọ mi, kìí ṣe sí àwọn Kèfèrí nìkan, ṣùgbọ́n sí àwọn Júù bákannáà; ìwọ yíò sì rán ọ̀rọ̀ mi jade lọ sí àwọn òpin ilẹ̀ ayé.
5 Ìwọ jà, nítorínáà, ní òwòwúrọ̀; àti ní ọjọọjọ́ jẹ́kí ohùn ìkìlọ̀ rẹ ó jade lọ; àti nígbàtí alẹ́ bá dé máṣe jẹ́kí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé ó tòògbé, nítorí ti ọ̀rọ̀ rẹ.
6 Jẹ́kí ibùgbé rẹ ó jẹ́ mímọ̀ ní Síónì, másì ṣe ṣípò ilé rẹ padà; nítorí èmi, Olúwa, ní iṣẹ pàtàkì fún ọ láti ṣe, ní kíkéde orúkọ mi láàrin àwọn ọmọ ènìyàn.
7 Nítorínáà, di àmùrè rẹ fún iṣẹ́ náà. Jẹ́ kí bàtà kí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ pẹ̀lú, nítorí ìwọ ni a yàn, ipa ọ̀nà rẹ sì wà ní ààrin àwọn òkè, àti ní ààrin àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀.
8 Àti pé nípa ọ̀rọ̀ rẹ, púpọ̀ àwọn gíga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, àti nípa ọ̀rọ̀ rẹ, púpọ̀ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni a ó gbé ga.
9 Ohùn rẹ yíò jẹ́ ìbáwí sí arúfin; àti ní ìbáwí rẹ, jẹ́ kí ahọ́n abanijẹ́ ó dẹ́kun ìṣe búburú rẹ̀.
10 Ìwọ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀; Olúwa Ọlọ́run rẹ yíò sì ṣíwájú rẹ nípa ọwọ́ rẹ̀, yíó sì fún ọ ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà rẹ.
11 Èmi mọ ọkàn rẹ, mo sì ti gbọ́ àwọn àdúrà rẹ nípa àwọn arákùnrin rẹ. Máṣe ṣe ojúṣàájú sí wọn nínú ìfẹ́ tayọ púpọ̀ àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ó wà fún wọn bíi fún ara rẹ; sì jẹ́kí ìfẹ́ rẹ ó di púpọ̀ sí gbogbo ènìyàn, àti sí gbogbo ẹnití ó fẹ́ràn orúkọ mi.
12 Kí o sì máa gbàdúrà fún àwọn arákùrin rẹ ti Méjìlá náà. Kìlọ̀ fún wọn gidigidi nítorí orúkọ mi, sì jẹ́kí a bá wọn wí fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti pé kí ìwọ jẹ́ olõtọ́ níwájú mi sí orúkọ mi.
13 Àti lẹ́hìn àwọn ìdẹwò wọn, àti ìpọ́njú púpọ̀, kíyèsíi, èmi, Olúwa, yíò ní ìmọ̀lára fún wọn, bí wọn kò bá sì sé àyà wọn le, àti tí wọn kò wa ọrùn wọn kì sí mi, a ó yí wọ̀n lọ́kàn padà, èmi yíò sì mú wọn lára dá.
14 Nísìsìyìí, mo wí fún ọ, ohun tí èmi bá sì wí fún ọ, mo wí fún gbogbo àwọn Méjìlá náà: Dìde kí o sì di àmùrè rẹ, gbé àgbélẽbù rẹ, tẹ̀lé mi, kí o sì bọ́ àwọn àgùtàn mi.
15 Ẹ máṣe gbé ara yín ga; ẹ máṣe ṣe ọ̀tẹ̀ sí ìránṣẹ́ mi Joseph; nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, èmi wà pẹ̀lú rẹ̀, ọwọ́ mi yíò sì wà ní orí rẹ̀; àti àwọn kọ́kọ́rọ́ èyítí mo ti fi fún un, àti bákannáà fún yín, ni a kì yíò gbà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ títí tí èmi yíò fi dé.
16 Lõtọ́ ni mo wí fún ọ, ìránṣẹ́ mi Thomas, ìwọ ni ẹni náà ẹnití èmi ti yàn láti ní àwọn kọ̀kọ̀rọ̀ ti ìjọba mi, bí ó ṣe jẹ́ ti àwọn Mẹ́jìlá náà, ní òkèrè láàrin àwọn orílẹ̀-èdè—
17 Pé kí ìwọ ó lè jẹ́ ìránṣẹ́ mi láti ṣí ìlẹ̀kùn ti ìjọba náà ní ibi gbogbo níbití ìránṣẹ́ mi Joseph, àti ìránṣẹ́ mi Sidney, àti ìránṣẹ́ mi Hyrum, kò lè dé;
18 Nítorí ní orí wọn ni mo ti gbé ẹrù gbogbo àwọn ìjọ lé fún ìgbà díẹ̀ kan.
19 Nítorínáà, ibikíbi tí wọn bá rán ọ, ìwọ lọ, èmi yíò sì wà pẹ̀lú rẹ; àti ní èyíkeyìí ibi tí ìwọ bá ti kéde orúkọ mi ìlẹ̀kùn àìtàsé ni a ó ṣí fún ọ, pé kí wọ́n ó lè gba ọ̀rọ̀ mi.
20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀rọ̀ mi gba mí, àti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí, gba àwọn wọnnì, Àjọ Ààrẹ Ìkínní, àwọn ẹnití èmi ti rán, àwọn ènití èmi ti fi ṣe àwọn olùdámọ̀ràn sí yín nítorí orúkọ mi.
21 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, pé ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá rán ní orúkọ mi, nípa ohùn àwọn arákùnrin yín, àwọn Méjìlá náà, tí ẹ̀yin ti kà yẹ tí ẹ sì fi àṣẹ fún, yíò ní agbára láti ṣí ìlẹ̀kùn ìjọba mi sí èyíkéyìí orílẹ̀-èdè ní ibikíbi tí ẹ̀yin bá rán wọn lọ—
22 Níwọ̀nbí wọn bá rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú mi, tí wọ́n sì dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, àti tí wọ́n fi etí sílẹ̀ sí ohùn ti Ẹ̀mí mi.
23 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé, àti òkùnkùn biribiri ní ọkàn àwọn ènìyàn, gbogbo ẹran ara sì ti díbàjẹ́ ní iwájú mi.
24 Kíyèsíi, ẹ̀san nbọ̀ kánkán sí orí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé, ọjọ́ ti ìbínú, ọjọ́ ti ìjóná, ọjọ́ ti ìsọdahoro, ti ẹkún, ti ọ̀fọ̀, àti ti ìpòhùnréré ẹkún; àti bíi ìjì yíò dé sí orí gbogbo ilẹ̀ ayé, ni Olúwa wí.
25 Àti ní orí ilé mi ni yíò ti bẹ̀rẹ̀, láti ilé mi ni yíò sì ti jade lọ, ni Olúwa wí;
26 Ní àkọ́kọ́ ní ààrin àwọ̀n wọnnì láàrin yín, ní Olúwa wí, tí wọ́n ti jẹ́wọ́ mímọ̀ orúkọ mi tí wọn kò sì tíì mọ̀ mí, àti tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ òdì sími ní ààrin inú ilé mi, ni Olúwa wí.
27 Nítorínáà, ẹ ríi wipe ẹ kò yọ ara yín lẹ́nu nípa àwọn ọ̀rọ̀ ti ìjọ mi ní ìhín yìí, ni Olúwa wí.
28 Ṣùgbọ́n ẹ sọ ọkàn yín di mímọ́ ní iwájú mi; àti nígbànáà ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ sì wàásù ìhìnrere mi sí olúkúlùkù ẹ̀dá tí kò tíì gbà á;
29 Ẹnití ó bá sì gbàgbọ́ tí a sì rìbọmi ni a ó gbàlà, ẹnití kò bá sì gbàgbọ́, tí a kò sì rìbọmi, ni a ó dá lẹ́bi.
30 Nítorí sí yín, ẹ̀yin Méjìlá náà, àti àwọn wọnnì, Àjọ Ààrẹ Ìkínní, àwọn ẹni tí a yàn pẹ̀lú yín láti jẹ́ àwọn olùdámọ̀ràn àti àwọn olùdarí yín, ni a fi agbára oyè àlùfáà yìí fún, fún àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn àti fún ìgbà ìkẹhìn, ní èyítí í ṣe ìgbà ìríjú kíkún ti àwọn àkókò náà,
31 Agbára èyítí ẹ̀yin ní, ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ti gba ìgbà ìríjú kan, ní èyíkeyìí àkókò láti ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá;
32 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, àwọn kọ́kọ́rọ́ ti ìgbà ìríjú, èyítí ẹ̀yin ti gbà, ti sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ àwọn bàbá, àti èyítí ó kẹ́hìn nínú gbogbo rẹ̀, ní rírán sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run sí yín.
33 Lõtọ́ ni mo wí fún yín, kíyèsíi bí ìpè yín ti tóbi tó. Ẹ wẹ ọkàn yín mọ́ àti àwọn aṣọ yín, bíbẹ́ẹ̀kọ́ ẹ̀jẹ̀ ìran yìí ni a ó béèrè lọ́wọ́ yín.
34 Ẹ jẹ́ olõtọ́ títí tí èmi yíò fi dé, nítorí èmi nbọ̀ kánkán; èrè mi sì nbẹ pẹ̀lú mi láti san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ rẹ̀ yíò ti rí. Èmi ni Álfà àti Òmégà. Àmín.