Ìpín 129
Àwọn ìtọsọ́nà tí a gbà nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Nauvoo, Illinois, 9 Oṣù Kejì 1843, ní sísọ di mímọ̀ àwọn kọ́kọ́rọ́ pàtàkì mẹ́ta nípa ẹ̀yítí a lè fi dá ìṣẹ̀dá pípé ti àwọn ángẹ́lì olújíṣẹ́ àti ti àwọ̀n ẹ̀mí mọ̀ yàtọ̀.
1–3, Àwọn ara tí wọ́n ti jínde àti àwọn ara ti ẹ̀mí wà ní ọ̀run; 4–9, A fi àwọn kọ́kọ́rọ́ fúnni nípa èyítí a fi lè dá àwọn ìránṣẹ́ láti ìtayọ àṣọ ìkéle mọ̀.
1 Irú àwọn ẹ̀dá méjì ni wọ́n wà ní ọ̀run, orúkọ wọn ni: Àwọn ángẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti jínde, pẹ̀lú níní àgọ́ ara ti ẹran ara àti àwọn egungun—
2 Fún àpẹrẹ, Jésù wipe: Ẹ dì mí mú kí ẹ sì wòó, nítorí ẹ̀mí kò lí ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.
3 Lí ọ̀nà kejì: àwọn ẹ̀mí ti àwọn olõtọ́ ènìyàn tí a sọ di pípé, àwọn ẹnití a kò jí dìde, ṣùgbọ́n tí wọ́n jogún ògo kan náà.
4 Nígbàtí ìránṣẹ́ kan bá wá ní wíwí pé òun ní iṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, fi ọwọ́ rẹ fún un kí o sì béèrè pé kí òun bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.
5 Bí òun bá jẹ́ ángẹ́lì kan òun yíò ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yíò sì ní ìmọlára ọwọ́ rẹ̀.
6 Bí òun bá jẹ́ ẹ̀mí ti olõtọ́ ènìyàn tí a sọ di pípé òun yíò wá nínú ògo rẹ̀; nítorí èyíinì ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí òun fi lè fi ara hàn—
7 Béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí òun bọ ọwọ́ pẹ̀lú rẹ, ṣùgbọ́n òun kì yíò ṣípo padà, nítorítí ó lòdì sí ètò ti ọ̀run fún olõtọ́ ènìyàn láti tanni jẹ; ṣùgbọ́n òun yíò jẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ síbẹ̀.
8 Bí ó bá jẹ́ èṣù bíi ángẹ́lì ìmọ́lẹ̀, nígbàtí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ láti bọwọ́ pẹ̀lú rẹ òun yíò na ọwọ́ rẹ̀, ìwọ kì yíò sì ní ìmọlára kankan; nígbànáà ni ìwọ yío lè dá a mọ̀.
9 Ìwọ̀nyí ni àwọn kọ́kọ́rọ́ pàtàkì mẹ́ta nípa bí ìwọ ṣe lè mọ̀ bóyá èyíkéyìí ìpínfúnni jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.