Ìpín 57
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Síónì, Ìjọba Ìbílẹ̀ Jackson, Missouri, 20 Oṣù Keje 1831. Ní ìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa láti rin ìrìnàjò lọ sí Missouri, níbití Òun yío ti ṣe àfihàn “ilẹ̀ ìní rẹ” (ìpín 52), àwọn alàgbà ti rin ìrìnàjò láti Ohio lọ sí ààlà ìwọ̀ oòrùn ti Missouri. Joseph Smith fi inú rò ipò àwọn ará Lámánì òun sì béèrè pẹ̀lú ìyanu: “Nígbà wo ni aginjù yíò ní ìtànná bíi òdòdó? Nígbà wo ni a ó kọ́ Síónì nínú ògo rẹ̀, àti pé níbo ni tẹ́mpìlì Rẹ yíò dúró, sí èyítí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíò wá ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn?” Lẹ́hìn náà ó gba ìfihàn yìí.
1–3, Independence, Missouri, ni ibi náà fún Ìlú nlá Síónì àti tẹ́mpìlì náà; 4–7, Àwọn Ẹni Mímọ́ yíò ra àwọn ilẹ̀ wọn yíò sì gba àwọn ogún ìní wọn ní àgbègbè náà; 8–16, Sidney Gilbert yíò ṣe àgbékalẹ̀ ilé ìṣúra kan, William W. Phelps yíò jẹ́ atẹ̀wé, àti Oliver Cowdery yíò máa ṣe àyẹ̀wò àwọn nkan fún àtẹ̀jade.
1 Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, ni Oluwa Ọlọ́run yín wí, ẹ̀yin tí ẹ ti kó ara yín jọ pọ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn àṣẹ mi, ní ilẹ̀ yìí, èyí tí íṣe ilẹ̀ Missouri, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ tí èmi ti yàn àti tí mo ti yà sí mímọ́ fún kíkójọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
2 Nítorínáà, èyí ni ilẹ̀ ìlérí, àti ibi náà fún ìlú nlá Síónì.
3 Àti báyìí ni Olúwa Ọlọ́run yín wí, bí ẹ̀yin yíò bá gba ọgbọ́n, ọgbọ́n nìyí. Kíyèsíi, ibi tí à npè ní Independence nísisìyí ni ó jẹ́ ibi ààrin gbùngbùn; àti ọ̀gangan ibi kan fún tẹ́mpìlì ni ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní orí ìpín ilẹ̀ kan èyí tí kò jinnà sí ilé ẹjọ́.
4 Nítorínáà, ó jẹ́ ọgbọ́n pé kí ilẹ̀ náà jẹ́ rírà fún àwọn ẹni mímọ́, àti bákannáà gbogbo àwọn àyíká tí ó wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àní títí dé ibi ìlà tí ó ṣe tààrà lààrin àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí;
5 Àti bákannáà gbogbo àyíká tí ó wà níbi ààlà àwọn pápá, níwọ̀nbí àwọn ọmọ ẹ̀hìn mi bá ní agbára láti rà àwọ́n ilẹ̀. Kíyèsíi, èyí jẹ́ ọgbọ́n, pé kí wọ́n ó lè gbà á fún ogún ìní wọn ayérayé.
6 Ẹ sì jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert ó dúró sí ipò iṣẹ́ rẹ̀ èyí tí mo yàn án sí, láti gba àwọn owó, àti láti jẹ́ aṣojú fún ìjọ, láti ra ilẹ̀ ní gbogbo àwọn agbègbè yíká, níwọ̀nbí ó bá ti ṣeéṣe nínú òdodo, àti bí ọgbọ́n bá ṣe darí rẹ̀.
7 Àti pé ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Edward Partridge ó dúró sí ipò iṣẹ́ tí èmi ti yàn án sí, kí òun sì pín ogún ìní àwọn ènìyàn mímọ́ fún wọn, àní bí mo ti ṣe pàṣẹ; àti bákannáà àwọn wọnnì tí òun ti yàn láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un.
8 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert ó fi ìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ní ìhín yìí, kí òun sì ṣe àgbékalẹ̀ ilé ìṣúra kan, kí òun ó lè máa ta àwọn nkan ọjà láì sí ìtànjẹ, kí òun ó lè máa gba owó láti fi ra àwọn ilẹ̀ fún ire àwọn ènìyàn mímọ́, àti kí òun ó lè gba àwọn ohunkóhun tí àwọn ọmọ ẹ̀hìn bá nílò láti fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ nínú ogún ìní wọn.
9 Àti bákannáà ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Sidney Gilbert ó gba ìwé àṣẹ kan—kíyèsíi èyí jẹ́ ọgbọ́n, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kàá kí ó yé e—kí òun ó lè fí àwọn nkan ọjà ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn, àní nípa àwọn ẹni tí òun yío gbà bií àwọn akọ̀wé nínú iṣẹ́ rẹ̀.
10 Àti báyìí ni kí òun pèsè fún àwọn ẹni mímọ́ mi, kí ìhìnrere mi lè jẹ́ kíkéde sí àwọn tí wọ́n jókòó nínú òkùnkùn àti ní agbègbè àti òjìji ikú.
11 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi William W. Phelps ó fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ìhín yìí, kí a sì gbé òun kalẹ̀ gẹ́gẹ́bí atẹ̀wé fún ìjọ.
12 Sì wòó, bí àwọn aráyé bá gba àwọn ohun kíkọ rẹ̀—kíyèsíi èyí jẹ́ ọgbọ́n—ẹ jẹ́ kí òun ó gba ohunkóhun tí òun bá lè gbà ní ti òdodo, fún ire àwọn ènìyàn mímọ́.
13 Àti pé ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ mi Oliver Cowdery ó ṣe àtìlẹ́hìn fún un, àní gẹ́gẹ́bí èmi ṣe pàṣẹ, ní ibikíbi ti èmi bá yàn fún un, láti ṣe ẹ̀dà, àti láti ṣe àtúnṣe, àti lati yàn, kí ohun gbogbo ó lè jẹ́ títọ́ níwájú mi, gẹ́gẹ́bí a ó ṣe fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ lati ọwọ́ Ẹ̀mí nípasẹ̀ rẹ̀.
14 Àti báyìí ni kí á fi ẹsẹ̀ àwọn wọnnì tí èmi ti sọrọ̀ nípa wọn múlẹ̀ ní orí ilẹ̀ Síónì, ní kánkán bí ó ti lè yá tó, pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn, láti ṣe àwọn nkan wọnnì àní bí èmi ṣe sọ̀rọ̀.
15 Àti nísisìyí nípa ti ìkójọpọ̀—Ẹ jẹ́kí biṣọpù àti aṣojú ó ṣe àwọn ìgbáradì fún àwọn ẹbí tí a ti pàṣẹ fún láti wá sí orí ilẹ̀ yìí, ní àìpẹ́ bí ó ti lè ṣeéṣe, kí wọ́n sì fí ìdí wọn múlẹ̀ nínú ogún ìní wọn.
16 Àti sí ìyókù àwọn alàgbà àti àwọn ọmọ ìjọ a ó fi àwọn ìtọ́ni fún wọn síwájú lẹ́hìn wá. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.