Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 85


Ìpín 85

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wolíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 27 Oṣù Kọkànlá 1832. Ìpín yìí ni ohun tí a fà yọ nínú ìwé kan tí Wòlíì kọ sí William W. Phelps, ẹni tí ó ngbé ní Independence, Missouri. Ó dáhùn àwọn ìbéèrè nípa àwọn Ẹni Mímọ́ wọnnì tí wọ́n ti ṣipò padà lọ sí Síónì ṣùgbọ́n tí wọn kò tíì tẹ̀lé àṣẹ láti ya àwọn ohun ìní wọn sọ́tọ̀ àti nítoríbẹ́ẹ̀ kò tíì gba àwọn ogún tiwọn gẹ́gẹ́bí ètò tí a fi lélẹ̀ nínú ìjọ.

1–5, Àwọn ogún ní Síónì ni a ó gbà nípasẹ̀ ìyàsí-mímọ́; 6–12, Ẹni nla ati alágbára kan ni yíò fún àwọn Ẹni Mímọ́ ní ogún wọn ní Síónì.

1 Ó jẹ́ ojúṣe akọ̀wé Olúwa, ẹnití òun ti yàn, láti ṣe ìpamọ́ ìwé ìtàn kan, àti àkọsílẹ̀ gbogbogbòò kan ti ìjọ nípa ohun gbogbo tí ó ṣẹ̀lẹ̀ ní Síónì, àti ti gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ya àwọn ohun ìní sí mímọ́, àti tí wọ́n gba àwọn ogún ní ọ̀nà tí ó bá òfin mu láti ọwọ́ bíṣọ́ọ̀pù;

2 Àti bákannáà irú ìgbésí ayé wọn, ìgbàgbọ́ wọn, àti àwọn iṣẹ́; àti bákannáà ní ti àwọn olùyapa tí yíyapa wọn jẹ́ lẹ́hìn gbígba àwọn ogún wọn.

3 Ó lòdì sí ìfẹ́ inú àti òfin Ọlọ́run pé àwọn wọnnì tí wọn kò gba ogún wọn nípa ìyàsí-mímọ́, ní ìbámu pẹ̀lú òfin rẹ̀, èyí tí òun ti fi fúnni, kí òun ó lè mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ san ìdámẹ́wàá, láti múra wọn sílẹ̀ ní ìdojúkọ ọjọ́ ẹ̀san àti ìjóná, kí wọn ó fi orúkọ wọn sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

4 Bóyá ìtàn ìdílé wọn kì yío jẹ́ pípamọ́, tàbí kí a níi níbití á ti lè ríi nínú èyíkéyìí àwọn àkọsílẹ̀ tàbí ìwé ìtàn ìjọ.

5 Àwọn orúkọ wọn ni a kì yíò rí, bóyá àwọn orúkọ àwọn bàbá wọn, tàbí àwọn orúkọ àwọn ọmọ tí a kọ sínú ìwé òfin Ọlọ́run, ni Olúwa àwọn Ọmọ ogun wí.

6 Bẹ́ẹ̀ni, báyìí ni ohùn jẹ́jẹ́ kékeré náà wí, èyí tí ó sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ la ààrin já tí ó sì wọnú ohun gbogbo, àti nígbàkúùgbà ó mú kí àwọn egungun mi ó gbọ̀n nígbàtí ó bá nṣe ìfarahàn, ní wíwí pé:

7 Yíò sì ṣe tí Èmi, Olúwa Ọlọ́run, yíò rán ẹni nlá ati alágbára kan, ní mímú ọ̀pá aládé agbára ní ọwọ́ rẹ̀, a wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ fún bíbora, ẹnití ẹnu rẹ̀ yíò sọ àwọn ọ̀rọ̀, àwọn ọ̀rọ̀ ayérayé; nígbàtí inú rẹ̀ yíò jẹ́ orisun òtítọ́, láti ṣe ilé Ọlọ́run létòlétò, àti láti ṣe ètò lẹ́sẹẹsẹ nípa ìpín, àwọn ogún ìní ti àwọn ẹni mímọ́ tí a rí orúkọ wọn, àti àwọn orúkọ àwọn bàbá wọn, àti ti àwọn ọmọ wọn, tí a fi sílẹ̀ nínú ìwé òfin Ọlọ́run;

8 Nigbàtí ọkùnrin náà, ẹnití Ọlọ́run pè tí ó sì yàn, tí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run dúró, yíò ṣubú nípasẹ̀ ọ̀pá ikú, gẹ́gẹ́bí igi tí a kọlù nípasẹ̀ títàn ọ̀pá mọ̀nàmọ́ná.

9 Àti gbogbo àwọn tí a kò rí ní kíkọ sínú ìwé ìrántí ni wọn kì yíò rí ogún kankan ní ọjọ́ náà, ṣùgbọ́n a ó ké wọn sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àti ìpín wọn ni a ó yàn fún wọn láàrin àwọn aláìgbàgbọ́, níbi tí ìpohùn-réré ẹkún àti ìpahín-keke gbé wà.

10 Àwọn nkan wọ̀nyìí ni èmi kò sọ ní ti ara mi; nítorínáà, bí Olúwa ṣe sọ̀rọ̀, òun yíò múu ṣẹ bákannáà.

11 Àwọn tí wọ́n sì jẹ́ ti Oyè Àlùfáà Gíga, àwọn tí a kò rí orúkọ wọn ní kíkọ nínú ìwé òfin náà, tàbí tí a rí pé wọ́n ti yapa kúrò, tàbí tí a ti ké wọn kúrò nínú ìjọ, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ti òye àlùfáà tí ó kéré, tàbí àwọn ọmọ ìjọ, ní ọjọ́ náà kì yíò rí ogún kan láàrin àwọn ẹni mímọ́ ti Ọ̀gá-ògo Jùlọ;

12 Nítorínáà, a ó ṣe sí wọn bíi ti àwọn ọmọ àlùfáà, bí a ó ṣe ríi ní kíkọ sílẹ̀ ní orí kejì àti àwọn ẹsẹ ìkọkànlélọ́gọ́ta àti ìkejìlélọgọ́ta ìwé Esra.