Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 25


Ìpín 25

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Harmony, Pennsylvania, Oṣù Keje 1830. (wo àkọlé ìpín 24). Ìfihàn yìí ṣípayá ìfẹ́ inú Olúwa sí Emma Smith, ìyàwó Wòlíì.

1–6, Emma Smith, obìnrin tí a yàn, ni a pè láti ṣe ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú fún ọkọ rẹ̀; 7–11 A pè é bákannáà láti kọ̀ ìwé, láti ṣe àsọyé àwọn ìwé mímọ́, àti láti yan àwọn orin; 12–14, Orin olódodo jẹ́ àdúrà sí Olúwa; 15–16, Àwọn ẹ̀kọ́ nípa ìgbọ́ràn tí ó wà nínú ìfihàn yìí jẹ́ àmúlò fún ẹni gbogbo.

1 Fetísílẹ̀ sí ohùn Olúwa Ọlọ́run rẹ, níwọ̀nbí mo ṣe nba ọ sọ̀rọ̀, Emma Smith, ọmọbìnrin mi; nítórí lõtọ́ ní mo wí fún ọ, gbogbo ẹnití ó bá gba ìhìnrere mi ni wọ́n jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin nínú ìjọba mi.

2 Ìfihàn kan ni èmi fún ọ nípa ìfẹ́ inú mi; àti pé bí ìwọ bá jẹ́ olõtọ́ tí ìwọ sì rìn ní ọ̀na ìwà mímọ́ níwájú mi, èmi yíò pa ẹ̀mí rẹ mọ́, ìwọ yíò sì gba ogún ìní ní Síónì.

3 Kíyèsíi, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, ìwọ sì jẹ́ obìnrin tí a yàn, ẹnití èmi ti pè.

4 Máṣe kùn nítorí àwọn ohun tí ìwọ kò tíì rí, nítorí a fi wọ́n pamọ́ fún ọ àti fún àwọn aráyé, èyítí ó jẹ́ ọgbọ́n nínú mi fún àkókò tí ó nbọ̀.

5 Àti pé ipò iṣẹ́ tí a pè ọ́ sí yíó jẹ́ fún ìtùnú sí ìránṣẹ́ mi, Joseph Smith Kékeré, ọkọ rẹ, nínú àwọn ìpọ́njú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìtura, nínú ẹ̀mí ọkàn tútù.

6 Àti pé ìwọ yíò lọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àkókò lílọ rẹ̀, ìwọ yíò sì jẹ́ akọ̀wé fún un, níwọ̀n ìgbatí kò bá sí ẹnití yíò kọ̀wé fún un, kí èmi lè rán ìránṣẹ́ mi, Oliver Cowdery, sí ibikíbi tí mo bá fẹ́.

7 Ati pé a ó yàn ọ́ ní abẹ́ ìgbọ́wọlé rẹ̀ láti sọ àsọyé àwọn ìwé mímọ́, àti láti gba ìjọ níyànjú, gẹ́gẹ́bí a ó ṣe fi fun ọ láti ọwọ́ Ẹ̀mí mi.

8 Nítorí òun yíò gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọ, ìwọ yíò sì gba Ẹ̀mí Mímọ́, ìwọ yíò sì fi àkókò rẹ fún ìwé kíkọ, àti fún gbígba ìmọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

9 Àti pé ìwọ kò nílò lati bẹ̀rù, nítorí ọkọ rẹ yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ nínú ìjọ; nítorípé sí wọn ni ìpè rẹ̀, kí a le fi ohun gbogbo hàn fún wọn, ohunkóhun tí èmi bá fẹ́, gẹ́gẹ́bí ìgbagbọ́ wọn.

10 Àti pé lõtọ́ ni mo wí fún ọ pé ìwọ yíò kó àwọn nkan ti ayé yìí sí ẹ̀gbẹ́ kan, ìwọ yíò sì lépa àwọn ohun tí ó dára jù.

11 Àti pé a ó fi fún ọ, bákannáà, láti ṣe àsàyàn àwọn orin mímọ́, gẹ́gẹ́bí a ó ṣe fi fún ọ, èyí tí ó jẹ́ dídùn inú mi, láti ní nínú ìjọ mi.

12 Nítorí ọkàn mi yọ̀ nínú orin àtọkànwá; bẹ́ẹ̀ni, orin àwọn olódodo jẹ́ àdúrà sí mi, àti pé ìdáhùn yíó wàá pẹ̀lú ìbùkún sí orí wọn.

13 Nítorínáà, gbé ọkàn rẹ sókè kí o sì yọ̀, kí ìwọ ó sì fi ara mọ́ àwọn májẹmú tí ìwọ ti ṣe.

14 Tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀mí ọkàn tutu, àti kí o sọ́ra fún ìgbéraga. Jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀ sí ọkọ rẹ, àti sí ògo náà tí yíò wá sí orí rẹ̀.

15 Pa àwọn òfin mi mọ́ láìdúró, adé ti òdodo ni ìwọ yíò sì gbà. Àti bí kò ṣe pé ìwọ bá ṣe èyí, ibití èmi wà ìwọ kì yíò lè wá.

16 Àti pé lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, pé ohùn mi ni èyí sí gbogbo ènìyàn. Amin.