Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 34


Ìpín 34

Ìfihàn tí a fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Orson Pratt, ní Fayette, NewYork, 4 Oṣù Kọkànlá, 1830. Arákùnrin Pratt jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ní àkókò náà. A ti yíi lọ́kàn padà àti pé òun ti ṣe ìribọmi nígbàtí ó kọ́kọ́ gbọ́ ìwàásù ìhìnrere tí a ràpadà nípasẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin, Parley P. Pratt, ní ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ṣaájú àkókò yìí. Ìfihàn yìí ni a gbà nínú ilé Peter Whitmer Agbà.

1–4, Àwọn olódodo di ọmọ Ọlọ́run nípa Ètùtù; 5–9, Ìwàásù ìhìnrere npèsè ọ̀nà fún Bíbọ̀ Èkejì; 10–12, Ìsọtẹ́lẹ̀ máa nwá nípa agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́.

1 Ọmọ mi Orson, fetísílẹ̀ kí o sì gbọ́, kí o sì kíyèsíi ohun tí èmi, Olúwa Ọlọ́run, yíò sọ fún ọ, àní Jésù Krístì Olùràpadà rẹ.

2 Ìmọ́lẹ̀ náà àti ìyè ayé, ìmọ́lẹ̀ kan tí ó ntàn nínú òkùnkùn tí òkùnkùn náà kò sì leè borí rẹ̀.

3 Ẹnití Ó fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ tí Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbàá gbọ́ ó lè di ọmọ Ọlọ́run. Nítorínáà ìwọ ni ọmọ mi;

4 Àti pé ìbùkún ni fún ọ nítorípé ìwọ ti gbàgbọ́;

5 Àti pé ìbùkún púpọ̀ ni fún ọ nítorípé a pè ọ́ láti ọwọ́ mi láti wàásù ìhìnrere mi—

6 Láti gbé ohùn rẹ sókè gẹ́gẹ́bí ìró fèrè ogun kan, èyí tí ó gùn tí ó sì ní ariwo, àti pé kí ìwọ kígbe ironúpìwàdà sí ìran oníwà rúdurùdu àti alárékérekè kan, nípa títún ọ̀nà Olúwa ṣe fún bíbọ̀ rẹ̀ ẹ̀kejì.

7 Nítorí kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, àkókò náà ti kù sí dẹ̀dẹ̀ tí èmi yíò wá ní àwọsánmọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo nlá.

8 Àti pé ọjọ́ nla ni yíò jẹ́ nígbàtí èmi yíò padà wá, nítorí gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ni wọn yíò wárìrì.

9 Ṣùgbọ́n ṣaájú dídé ọjọ́ nla yìí, oòrùn yíò sókùnkùn, òṣùpá yíò sì di ẹ̀jẹ̀; àwọn ìràwọ̀ yíò sì kọ̀ láti fi dídán wọn hàn, àti pé àwọn kan yíò tilẹ̀ jábọ́, ìparun nlá sì dúró de àwọn ènìyàn búburú.

10 Nísisìyí, gbé ohùn rẹ sókè àti pé kí ìwọ má ṣe dásí, nítorí Olúwa Ọlọ́run ti sọ ọ̀rọ̀ náà; nítórináà sọ àsọtẹ́lẹ̀, àti pé a ó sì fi fún ọ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

11 Àti pé bí ìwọ bá jẹ́ olódodo, kíyèsíi, èmi wà pẹ̀lú rẹ títí tí Èmí yíò fi dé—

12 Àti pé lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún ọ, èmi nbọ̀ kánkán. Èmi ni Olúwa àti Olùràpadà rẹ. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.