Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 40


Ìpín 40

Ìfihàn tí a fi fún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ní Fayette, New York, 6 Oṣù Kíní 1831. Ṣaájú àkọsílẹ̀ ìfihàn yìí, ìtan ti Wòlíì náà sọ pé, “Bí James [Covel] ṣe kọ ọ̀rọ̀ Olúwa, tí òun sì padà sínú àwọn ìlàna ẹ̀kọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀, Olúwa fún èmi àti Sidney Rigdon ní ìfihàn yìí” (wo section 39).

1–3, Ìbẹ̀rù inúnibíni àti àwọn àníyàn ayé ní ó nfa ìkọ̀sílẹ̀ ìhìnrere.

1 Kíyèsíi, lõtọ́, ni mo wí fún yín, pé ọkàn ìránṣẹ́ mi James Covel ti yẹ níwájú mi, nítorí òun ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú mi pe òun yíò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

2 Àti pé òun gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú inú dídùn, ṣùgbọ́n lójúkanáà Sátánì dán an wò; àti pé ìbẹ̀rù inúnibíni àti àwọn àníyàn ayé mú kí òun kọ ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀.

3 Nítorínáà òun ré májẹ̀mú mi kọjá, ó sì jẹ́ ti èmi láti ṣe si i bí ó bá ṣe tọ́ ní ojú mi. Amin.