Ìpín 79
Ìfihan tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, 12 Oṣù Kejì 1832.
1–4, Jared Carter ni a pè láti wàásù ìhìnrere nípasẹ̀ Olùtùnú náà.
1 Lõtọ́ ni mo wí fún ọ, pé ìfẹ́ inú mi ni pé kí ìránṣẹ́ mi Jared Carter ó lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè apá ìlà oòrùn, láti ibi kan sí ibi kan, àti láti ìlú nlá kan dé ìlú nlá kan, nínú agbára jíjẹ-oyè-àlùfáà èyí tí a ti fi yàn an, ní kíkéde àwọn ìhìn ayọ̀ ti ìdùnnú nlá, àní ìhìnrere àìlópin náà.
2 Èmi yíò sì rán Olùtùnú náà sórí rẹ̀, èyí tí yíò kọ́ ọ ní òtítọ́ àti ipa ọnà tí òun yíò lọ;
3 Àti níwọ̀nbí òun bá jẹ́ olõtọ́, èmi yíò dé e ní adé lẹ́ẹ̀kansíi pẹ̀lú àwọn ìtí.
4 Nítorínáà, jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀, ìránṣẹ́ mi Jared Carter, má sì ṣe bẹ̀rù, ni Olúwa rẹ wí, àní Jésù Krístì. Àmín.