Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 77


Ìpín 77

Ìfihàn tí a fún Wòlíì Joseph Smith, ní Hiram, Ohio, ní nkan bíi Oṣù Kejì 1832. Ìtàn Joseph Smith sọ pé, “Ní àṣepọ̀ pẹ̀lú títúmọ̀ àwọn Ìwé Mímọ́, mo gba àlàyé tí ó tẹ̀lé yí nípa Ìfihàn ti Jòhánnù Mímọ́.”

1–4 Àwọn ẹranko ní ẹ̀mí wọn yíò sì gbé ní ìdùnnú ayérayé; 5–7, Àyé yìí ní àkókò ti ara tí yíò fi wà fún Ẹ̀gbèrún méje ọ̀dún; 8–10, Onírúurú àwọn ángẹ́lì mú ìhìnrere padàbọ̀sípò wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ori ilẹ̀ ayé; 11, Fífi èdídí di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà; 12–14, Krístì yíò dé ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rún keje ọdún náà; 15, Àwọn Wòlíì méjì ni a ó gbé dìde fún orílẹ̀-èdè àwọn Júù.

1 Ìbéèrè: Kínni òkun dígí èyí tí Jòhánnù sọ nípa rẹ̀ ní orí 4, àti ẹsẹ 6 nínú Ìwé Ìfihàn?Ídáhùn: Ìlẹ̀ Ayé ni, ní ipò yíyàsí mímọ́, àìkú, àti ayérayé rẹ̀.

2 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa àwọn ẹranko mẹ́rin, tí a sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú ẹsẹ kannáà?Ìdáhùn: Wọ́n jẹ́ ọ̀rọ̀ àpẹrẹ, èyí tí Olùfihàn lò, Jòhánnù, ní ṣíṣe àpẹ̀júwe ọ̀run, párádisè Ọlọ́run, ìdùnnú ti ènìyàn, àti ti àwọn ẹranko, àti ti àwọn ohun tí ó nrákòrò, àti àwọn ẹyẹ inú afẹ́fẹ́; èyíinì tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí tí ó wà ní ìrí èyíinì tí ó jẹ́ ti ara; àti èyíinì tí ó jẹ́ ti ara ní ìrí èyíinì tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí; ẹ̀mí ti ènìyàn ní ìrí ẹni tirẹ̀, bí ẹ̀mí ti ẹranko bákannáà, àti olúkúlùkù ẹ̀dá míràn tí Ọlọ́run ti dá.

3 Ìbéèrè: Njẹ́ àwọn ẹranko mẹ́rin náà dá dúró ní orí àwọn ẹranko kọ̀ọ̀kan pàtó, tàbí wọ́n nṣojú fún onírúurú àwọn ẹgbẹ́ tàbí ọ̀wọ́?Ìdáhùn: Wọ́n dá dúró ní orí àwọn ẹranko mẹ́rin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, èyí tí a fi hàn fún Jòhánnù, láti ṣojú fún ògo àwọn ẹgbẹ́ àwọn ẹ̀dá nínú ọ̀wọ́ àyànmọ́ wọn tàbí àyíká ìṣẹ̀dá wọn, nínú ìgbádùn ìdùnnú ayérayé wọn.

4 Ìbéèrè: Kínni ó nílati yé wa nípa àwọn ojú àti àwọn ìyẹ́ apá, èyítí àwọn ẹranko náà ní?Ìdáhùn: Àwọn ojú wọn jẹ́ àfijọ kan fún ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀, tí ó jẹ́ pé, wọ́n kún fún ìmọ̀; àti àwọn ìyẹ́ apá wọn jẹ́ àfijọ kan fún agbára, láti ṣípòpadà, láti ṣe nkan, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

5 Ìbéèrè: Kínni ó nílati yé wa nípa àwọn alàgbà mẹ́rin àti ogún náà, tí Jòhánnù sọ nípa?Ìdáhùn: Ó níláti yé wa pé àwọn alàgbà wọ̀nyí tí Jòhánnù rí, ni àwọn alàgbà tí wọ́n ti jẹ́ olõtọ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọ́n sì ti kú; tí wọ́n jẹ́ ara àwọn ìjọ méje, wọ́n sì wà ní paradise Ọlọ́run nígbànáà.

6 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa ìwé tí Jòhánnù rí, èyítí a fi èdídí dì lẹ́hìn pẹ̀lú àwọn èdídí méje?Ìdáhùn: Ó nílati yé wa pé ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ni ìfẹ́ inú tí a fihàn, àwọn ohun ìjìnlẹ̀, àti àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; àwọn ohun tí a ti fi pamọ́ tí ó jẹ́ ti ìsúná rẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé yìí ní àkókò ẹgbẹ̀rún méje ọdún ti ìtẹ̀síwájú rẹ̀, tàbí ti wíwà rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

7 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa àwọn èdídí méje èyí tí a fi díi?Ìdáhùn: Ó níláti yé wa pé èdídí èkínní ní àwọn nkan ti ẹgbẹ̀rún ọdún àkọ́kọ́ nínú, àti èkéjì bákannáà jẹ́ ti àwọn nkan ti ẹgbẹ̀rún ọdún èkejì, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ títí dé èkeje.

8 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa àwọn ángẹ́lì mẹ́rin náà, tí a sọ nípa wọn ní orí ìkeje àti ẹsẹ ìkínní ti Ìwé Ìfihàn?Ìdáhùn: Ó níláti yé wa pé mẹ́rin ni àwọn ángẹ́lì tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àwọn tí a fi agbára fún ní orí ìpín mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé, láti gba ẹ̀mí là àti láti parun; àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n ní ìhìnrere àìlópin láti gbé e lé olúkúlùkù orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti àwọn ènìyàn lọ́wọ́; tí wọ́n ní agbára láti ti àwọn ọ̀run, láti fi èdídí dì sí ìyè, tàbí láti jù sí ìsàlẹ̀ sí àwọn agbègbè ti òkùnkùn.

9 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa ángẹ́lì náà tí ngòkè láti ìla oòrùn, Ìfihàn orí ìkeje àti ẹsẹ èkejì?Ìdáhùn: Ó nílati yé wa pé ángẹ́lì tí ngòkè láti ìlà oòrùn ni ẹní náà tí a fi èdídí Ọlọ́run alààyè fún ní orí àwọn ẹ̀yà méjìlá Isráẹlì; nítorínáà, ó kígbe sí àwọn ángẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n ní ìhìnrere àìlópin, wipé: Máṣe pa ayé lára, tàbí òkun, tàbí àwọn igi, títí tí a ó fi fi èdídí di àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú orí wọn. Àti pé, bí ìwọ yíò bá gbà á, èyí ni Elíasì èyítí yíò wá láti kó gbogbo ẹ̀yà Isráẹ́lì jọ tí yíò sì mú ohun gbogbo padàbọ̀sípò.

10 Ìbéèrè: Àkókò wo ni àwọn nkan tí a sọ̀rọ̀ nípa wọn ní orí ìwé yìí yíò di ṣíṣe parí?Ìdáhùn: Wọn yíò di ṣíṣe parí ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún ọdún ẹ̀kẹfà, tàbí ní ìgbà ṣíṣí èdídí ẹ̀kẹfà.

11 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa fífi èdídí di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, lààrin àwọn ẹ̀yà ilé Isráẹ́lì—ẹgbẹ̀rún méjìlá lati inú olúkúlùkù ẹ̀yà?Ìdáhùn: Ó níláti yé wa pé àwọn tí a fi èdídí dì wọ̀nyí jẹ́ àwọn olórí àlùfáà, tí a yàn sínú ètò mímọ́ ti Ọlọ́run láti ṣe àkóso ìhìnrere ti àìlópin; nítorí àwọn ni àwọn tí a ti yàn láti inú olúkúlùkù orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti àwọn ènìyàn, lati ọwọ́ àwọn ángẹ́lì tí a fi agbára fún ní orí àwọn orílẹ̀-èdè ayé, láti mú iye àwọn tí ó bá wù lati wá sí inú ìjọ Àkọ́bí.

12 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa ríró àwọn fèrè, tí a mẹ́nubà ní orí ẹ̀kẹjọ ti Ìwé Ìfihàn?Ìdáhùn: Ó níláti yé wa pé bí Ọlọ́run ṣe dá ayé ní ọjọ́ mẹ́fà, àti ní ọjọ́ keje ó parí iṣẹ́ rẹ̀, ó sì yà á sí mímọ́, àti bákannáà ó mọ ènìyàn láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé, àní bẹ́ẹ̀ni, ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rún keje ọdún ni Olúwa Ọlọ́run yíò ya ayé sí mímọ́, tí yíò sì parí ìgbàlà ènìyàn, tí yíò ṣe ìdájọ́ ohun gbogbo, yíò sì ra ohun gbogbo padà, bíkòṣe èyíinì tí òun kò fi sí inú agbára rẹ̀, nígbàtí òun yíò ti fi èdídí di ohun gbogbo, sí òpin ohun gbogbo; àti dídún àwọn fèrè ti àwọn ángẹ́lì méje náà ni pípèsè àti píparí iṣẹ́ rẹ̀, ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún keje—títún ọ̀nà ṣe síwájú ìgbà bíbọ̀ rẹ̀.

13 Ìbéèrè: Nígbàwo ni àwọn ohun náà yío jẹ́ ṣíṣeparí, èyí tí a kọ ní orí ẹ̀kẹsãn ti Ìwé Ìfihàn?Ìdáhùn: Wọn yíò jẹ́ ṣíṣeparí lẹ́hìn ṣíṣí èdídí èkeje, síwájú bíbọ̀ Krístì.

14 Ìbéèrè: Kínni ó nílati yé wa nípa ìwé kékeré náà èyítí Jòhánnù jẹ, bí a ṣe mẹ́nubàá ní orí ẹ̀kẹwã ti Ìwé Ìfihàn?Ìdáhùn: Ó níláti yé wa pé iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan ni, àti ìlànà kan, fún òun lati kó àwọn ẹ̀yà ilé Isráẹ́lì jọ; kíyèsíi, èyi ni Elíásì, ẹnití, bí a ṣe kọ̀wé rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ wá láti mú ohun gbogbo padàbọ̀sípò.

15 Ìbéèrè: Kínni ó níláti yé wa nípa àwọn Ẹlérìí méjì náà, nínú orí ìkọkànlá ti Ìwé Ìfihàn?Ìdáhùn: Àwọn ni àwọn wòlíì méjì tí a ó gbé dìde fún orílẹ̀-èdè Júù ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn, ní àkókò ìmúpadàbọ̀sípò, àti láti sọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù lẹ́hìn tí a ti kó wọn jọ pọ̀ tí wọ́n sì ti kọ́ ìlú nlá Jérúsálẹ́mù ní orí ilẹ̀ àwọn bàbá wọn.