Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 102


Ìpín 102

Ìròhìn ti ìgbékalẹ̀ àjọ ìgbìmọ̀ gíga àkọ́kọ́ ti Ìjọ, ní Kirtland, Ohio, 17 Oṣù Kejì 1834. Ojúlówó ìròhin ni a ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ lati ọwọ́ àwọn alàgbà Oliver Cowdery àti Orson Hyde. Wòlíì ṣe àgbéyẹ̀wò ìròhìn ìpàdé náà ní ọjọ́ kejì, àti ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lée ìròhìn ìpàdé tí a ti túnṣe náà ni a fi ohùn sọ̀kan gbàwọlé láti ọwọ́ àwọn ìgbìmọ̀ gíga bíi “ìwé ètò àti ìwé òfin kan ti ìgbìmọ̀ gíga” ti Ìjọ. Àwọn ẹsẹ 30 títí dé 32, tí wọ́n ní í ṣe pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ ti àwọn Àpóstélì Méjìlá, ni wọ́n fi kún un ni 1835 ní abẹ́ ìdarí Joseph Smith nigbàtí ìpín yìí jẹ́ pípèsè fún títẹ̀ jade nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú.

1–8, Ìgbìmọ̀ gíga kan ni a yàn láti yanjú àwọn ìsòrò pàtàkì tí ó bá dìde nínú Ìjọ; 9–18, Àwọn ìgbésẹ̀ ni a fi fúnni fún gbígbọ́ àwọn ẹjọ́; 19–23, Ààrẹ ìgbìmọ̀ náà fi ìpinnu fúnni; 24–34, Ìgbésẹ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni a gbé kalẹ̀.

1 Ní ọjọ́ yìí ìgbìmọ̀ gbogbogbòò ti àwọn àlùfáà gíga mẹ́rìnlélógún péjọ ní ilé Joseph Smith Kékeré, nípa ìfihàn, wọ́n sì tẹ̀síwájú láti ṣe ètò ìgbìmọ̀ gíga ti ìjọ Krístì, èyítí yíó ní àwọn àlùfáà gíga méjìlá, àti ààrẹ kan tàbí mẹ́ta bí ọ̀rọ̀ náà bá ṣe gbà.

2 Ìgbìmọ̀ gíga náà ni a yàn nípa ìfihàn fún èrò yíyanjú àwọn ìṣòro pàtàkì èyítí ó lè dìde nínù ìjọ, èyítí ìjọ tàbí ìgbìmọ̀ bíṣọ́ọ̀pù kò bá lè yanjú sí ìtẹ́lọ́rùn àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn.

3 Joseph Smith Kékeré, Sidney Rigdon àti Frederick G. Williams ni àwọn ààrẹ tí a tẹ́wọ́gbà nípa ohùn ìgbìmọ̀ náà; àti Joseph Smith Àgbà, John Smith, Joseph Coe, John Johnson, Martin Harris, John S. Carter, Jared Carter, Oliver Cowdery, Samuel H. Smith, Orson Hyde, Sylvester Smith, àti Luke Johnson, àwọn àlùfáà gíga, ni a yàn láti wà nínú ìgbìmọ̀ dídúró kan fún ìjọ, nípa ìfòhùnṣọ̀kan ti ìgbìmọ̀ náà.

4 Àwọn olùdámọ̀ràn tí a dárúkọ lókè yí ni a bi léèrè nígbànáà bóyá wọ́n tẹ́wọ́gba yíyàn wọn, àti bóyá wọ́n yíò ṣiṣẹ́ nínú ipò iṣẹ́ náà ní ìbámu pẹ̀lú òfin ti ọ̀run, sí èyítí gbogbo wọn dáhùn pé àwọn gbà àwọn yíyàn wọn, àti pé àwọn yíò mú iṣẹ́ náà ṣe gẹ́gẹ́bí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún wọn.

5 Ìye àwọn tí wọ́n wà nínú ìgbìmọ̀ náà, tí wọ́n dìbò ní orúkọ àti fún ìjọ ní yíyàn àwọn olùdámọ̀ràn tí a dárúkọ́ lókè yí jẹ́ mẹ́tàlélógójì, bí ìwọ̀nyìí: àwọn àlùfáà gíga mẹ́sãn, àwọn alagbà mẹ́tàdínlógún, àwọn àlùfáà mẹ́rin, àti àwọn ọmọ ìjọ mẹ́tàlá.

6 A dìbò: pé ìgbìmọ̀ gíga kò lè ní agbára láti ṣiṣẹ́ láìsí méje nínú àwọn olùdámọ̀ràn tí a dárúkọ lókè yí, tàbí àwọn arọpò wọn tí a yàn dáradára níbẹ̀.

7 Àwọn méje wọ̀nyìí yíò ní agbára láti yan àwọn àlùfáà gíga míràn, ẹnití wọ́n yío gbèrò pé ó yẹ àti pé ó kún ojú òsùnwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ipò àwọn olùdámọ̀ràn tí kò wá.

8 A dìbò: pé nígbàkúùgbà tí èyíkéyìí ààyè kan bá ṣí sílẹ̀ nípa ikú, ìyọkúrò ní ipò iṣẹ́ fún ẹ̀ṣẹ̀, tàbí yíyọkúrò ní ààlà èto ìṣàkóso ìjọ yìí, ti èyíkéyìí nínú àwọn olùdámọ̀ran tí a dárúkọ lókè yí, a ó dí i nípa àbá dídá aàrẹ tàbí àwọn ààrẹ, àti ìfẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ nípa ohùn ìgbìmọ gbogbogbò tí àwọn àlùfáà gíga, tí a pèjọ fún ìdí èyí, láti ṣiṣẹ́ ní orúkọ ìjọ.

9 Ààrẹ ìjọ, ẹnití í ṣe ààrẹ ti ìgbìmọ̀ náà bákannáà, ní a yàn nípa ìfihàn, à sì gbà á wọlé nínú iṣẹ àmójútó rẹ̀ nípa ohùn ìjọ.

10 Ó sì jẹ́ pé ní ìbámu sí ọ̀wọ̀ ti ipò iṣẹ́ rẹ̀ ni òun nílati ṣe àkóso ní orí ìgbìmọ̀ ìjọ; àti ó jẹ́ ànfàní rẹ̀ pé kí àwọn ààrẹ méjì míràn ó ràn án lọ́wọ́, àwọn tí a yàn ní ọ̀nà kannáà tí a yan òun tìkára rẹ̀.

11 Àti bí ìkan tàbí àwọn méjèèjì tí a yàn láti ràn án lọ́wọ́ kò bá sí níbẹ̀, òun ní agbára láti ṣe àkóso ní orí ìgbìmọ̀ náà láìsí olùrànlọ́wọ́; bí òun tìkára rẹ̀ kò bá sì sí níbẹ̀, àwọn ààrẹ míràn ní agbára láti ṣe àkóso dípò rẹ̀, àwọn méjèèjì tàbí ọ̀kan yìówù nínú wọn.

12 Nígbàkúgbà tí a bá ṣe ètò ìgbìmọ̀ gíga ti ìjọ̀ Krístì bí ó ti yẹ, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ tí a là sílẹ̀ lókè yí, yíó jẹ́ ojúṣe ti àwọn olùdámọ̀ràn méjìlá náà láti di ìbò wọn nípa iye, àti nípa bẹ́ẹ̀ rí àrídájú ẹni nínú àwọn méjìlá náà tí yíò kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, bẹ̀rẹ̀ ní orí ẹni àkọ́kọ́ àti bẹ́ẹ̀ ní sísẹ̀ ntẹ̀lé sí ẹni èkejìlá.

13 Nígbàkúùgbà tí ìgbìmọ̀ yìí bá péjọ láti ṣiṣẹ́ ní orí ọ̀rọ̀ kan, àwọn olùdámọ̀rọan méjìlá náà yíò gbà á yẹ̀wò bóyá ó jẹ́ èyí tí ó ṣòro tàbí bẹ́ẹ̀kọ́; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, méjì péré nínú àwọn olùdámọ̀ràn náà yíò sọ̀rọ̀ lé e lórí, gẹ́gẹ́bí ètò tí a kọ sí òkè.

14 Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá rò pé ó ṣòro, mẹ́rin ni a ó yàn; àti bí ó bá tún sòro jù bẹ́ẹ̀ lọ, mẹ́fà; ṣùgbọ́n kì yíò sí ọ̀rọ̀ kan tí a ó yàn ju mẹ́fà lọ láti sọ̀rọ̀.

15 Ẹ̀ni náà tí a fi ẹ̀sùn kan, nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ní ẹ̀tọ́ sí ìdajì àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, láti yẹra fún títàbùkù ẹni tàbí àìṣododo.

16 Àwọn olùdámọ̀ràn tí a sì yàn láti sọ̀rọ̀ níwájú ìgbìmọ̀ ní láti gbé ẹjọ́ náà kalẹ̀, lẹ́hìn tí a bá ti ṣe àyẹ̀wò ẹ̀rí, bí ó ṣe rí gan an lõtọ́ níwájú ìgbìmọ̀; olúkúlùkù ènìyàn sì níláti sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí àìṣègbè àti òdodo.

17 Àwọn olùdámọ̀ràn tí wọ́n mú òunkà adọ́gba, èyíinì ni, eéjì, ẹẹ́rin, ẹẹ́jọ, ẹẹ́wàá, àti eéjìlá, ni wọ́n jẹ́ àwọn tí wọn yío dúró fún ẹnití a fi ẹ̀sùn kàn, wọn kì yíò sì gba títàbùkù ẹni àti àìṣòdodo láàyè.

18 Nínú gbogbo ẹ̀jọ́, olùpẹ̀jọ́ àti ẹnití a fi ẹ̀sùn kàn yíò ní ànfàní ti sísọ̀rọ̀ fún ara wọn níwájú ìgbìmọ̀ náà, lẹ́hìn tí wọ́n bá ti gbọ́ àwọn ẹ̀rí àti tí àwọn olùdámọ̀ràn tí a yàn láti sọ̀rọ̀ ní orí ẹjọ́ náà ti parí síṣe àwọn ọ̀rọ̀ sísọ wọn.

19 Lẹ́hìn tí wọ́n bá ti gbọ́ àwọn ẹ̀rí, tí àwọn olùdámọ̀ràn, olùfisùn àti ẹnití a fi ẹ̀sùn kàn ti sọ̀rọ̀, ààrẹ náà yíò sọ ìpinnu gẹ́gẹ́bí òye èyítí òun ní nípa ẹjọ́ náà, yíò sì pe àwọn olùdámọ̀ràn méjìlá láti fi ẹsẹ̀ èyí kannáà múlẹ̀ nípa ìbò wọn.

20 Ṣùgbọ́n bí àwọn olùdámọ̀ràn yìókù, tí wọn kò tĩ sọ̀rọ̀, tàbí ẹnìkankan nínú wọn, lẹ́hìn tí wọ́n ti gbọ́ àwọn ẹ̀rí àti àwọn ẹ̀bẹ̀ láìní ojúṣaájú, bá rí àṣìṣe kan nínú ìpinnu ààrẹ, wọ́n le fi í hàn, ẹjọ́ náà yíó sì ní àtúngbọ́.

21 Àti, lẹ́hìn tí a ti fi ara balẹ̀ tún ẹjọ́ náà gbọ́, bí àfikún ìmọ́lẹ̀ kan bá fi ara hàn ní orí ẹjọ́ náà, a ó ṣe àtúnṣe sí ìpinnu náà gẹ́gẹ́bí ó ṣe yẹ.

22 Ṣùgbọ́n bí a kò bá fúnni ní àfikún ìmọ́lẹ̀, ìpinnu àkọ́kọ́ náà yíò dúró, àwọn tí ó pọ̀jù nínú ìgbìmọ̀ náà ní agbára láti ṣe ìpinnu kannáà.

23 Bí ìṣòro bá wà ní bíbọ̀wọ̀ fún ẹ̀kọ́ tàbí ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, bí kò bá sí ohun kíkọ sílẹ̀ tí ó pọ̀ tó láti mú kí ẹjọ́ náà ó mọ́lẹ̀ sí ọ̀kàn àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ààrẹ le béèrè kí ó sì gba ọkàn Olúwa nípa ìfihàn.

24 Àwọn àlùfáà gíga, nígbàtí wọ́n bá wà ní ẹ̀hin odi, ní agbára láti pè àti láti ṣe ètò ìgbìmọ̀ kan ní títẹ̀lé àpèjúwe ti òkè yí, láti yanjú àwọn ìṣòro, nígbàtí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn tàbí èyíkéyìí nínú wọn bá béèrè rẹ̀.

25 Ìgbìmọ̀ àwọn àlùfáà gíga tí a wí yìí yíò ní agbára láti yan ẹnìkan nínú iye wọn láti ṣe àkóso ní orí irú ìgbìmọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

26 Yíó jẹ́ ojúṣe ìgbìmọ̀ tí a wí yìí láti fi ránṣẹ́, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀dà àwọn ohun tí wọn ṣe, pẹ̀lú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ ti ìjẹ́rìí tí yíó tẹ̀lé ìpinnu wọn, sí ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ gíga ti ìjókòó Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ.

27 Bí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn tàbí ọ̀kan nínú wọn kò bá ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìpinnu ìgbìmọ̀ tí a wí yìí, wọ́n lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ìgbìmọ̀ gíga ti ìjókòó Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ, kí wọ́n sì ṣe àtúngbọ́ ẹjọ́ náà, ọ̀rọ̀ èyítí wọn yíò darí, gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ ti ìṣaájú tí a kọ, bí ẹnipé wọn kó tíì ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀.

28 Ìgbìmọ̀ ti àwọn àlùfáà gíga yìí tí wọn wà ní ẹhìn odi ni a lè pè ní orí àwọn ẹjọ́ tí ó bá le jùlọ nìkan tí ó jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìjọ; kò sì sí ẹjọ́ tí ó wọ́pọ̀ tàbí tí kò ṣe pàtàkì tí yío pọ̀ tó láti pe irú ìgbìmọ̀ bẹ́ẹ̀.

29 Àwọn arìnrìnàjò àlùfáà gíga tàbí àwọn tí a fi sí ẹ̀hìn odi ní agbára láti sọ bóyá ó ṣe dandan láti pe irú ìgbìmọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́.

30 Ìyàtọ̀ wà láàrin ìgbìmọ̀ gíga tàbí àwọn arìnrìnàjò àlùfáà gíga ní ẹ̀hìn odi, àti arìnrìnàjò ìgbìmọ̀ gíga tí wọ́n jẹ́ àwọn àpóstélì méjìlá, nínú àwọn ìpinnu wọn.

31 Láti inú ìpinnu ti ìṣaájú pípe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn le wà; ṣùgbọ́n láti inú ìpinnu ti igbìmọ̀ ìkẹhìn kò le sí.

32 Ti ìkẹhìn kàn le jẹ́ pípè fún ìbéèrè nípasẹ̀ àwọn aláṣẹ gbogbogbòò ti ìjọ̀ nínú ẹjọ́ ìwà ìrékọjá.

33 Ìpinnu: pé ààrẹ tàbí àwọn ààrẹ ti ìjókòó Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ yíò ní agbára láti ṣe ìpinnu bóyá èyíkéyìí irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀, bí ó ṣe le jẹ́ àtúnpè, yẹ lati ní ẹ̀tọ́ sí títúngbọ́, lẹ́hìn síṣe àyẹ̀wò àtúnpè ẹjọ́ náà àti àwọn ẹ̀rí àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó pẹ̀lú rẹ̀.

34 Nígbànáà àwọn olùdámọ̀ràn méjìlá náà yíò tẹ̀síwájú láti sẹ́ kèké tàbí di ìbò, láti ṣe àrídájú ẹnití ó nílati kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, àtẹ̀lé yìí sì ni àbájáde, ó lọ báyìí: 1, Oliver Cowdery; 2, Joseph Coe; 3, Samuel H. Smith; 4, Luke Johnson; 5, John S. Carter; 6, Sylvester Smith; 7, John Johnson; 8, Orson Hyde; 9, Jared Carter; 10, Joseph Smith Àgbà; 11, John Smith; 12, Martin Harris.Lẹ́hìn àdúrà, ìpàdé àpapọ̀ náà sún sí ìgbà míràn.

Oliver Cowdery,

Orson Hyde,

Àwọn Akọ̀wé