Ìwé ti Mọ́mọ́nì kọ́ni pé “ẹni gbogbo rí bákannáà sí Ọlọ́run,” nínú rẹ̀ ni “dúdú àti funfun, òndè àti òmìnira, akọ àti abo” (2 Néfì 26:33). Jákèjádò ìtàn ti Ìjọ, àwọn ènìyàn láti gbogbo ẹ̀yà àti àṣà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ni a ti rìbọmi tí wọ́n sì ti gbé bíi ọmọ Ìjọ ní tòótọ́. Ní ìgbà ayé Joseph Smith, àwọn ọkùnrin aláwọ̀ dúdú ọmọ Ìjọ díẹ̀ jẹ́ yíyàn sí oyè-àlufáà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn rẹ̀, àwọn olùdarí Ìjọ dáwọ́ dúró ní fífi oyè-àlùfáà sí orí àwọn ọkùnrin aláwọ̀ dúdú tí wọ́n jẹ́ àtẹ̀lé ìran Áfírikà. Àwọn àkọsílẹ̀ Ìjọ kò fi òye kedere sílẹ̀ sí ìṣẹ̀dálẹ̀ ìṣe yìí. Àwọn olùdarí Ìjọ gbàgbọ́ pé wọ́n nílò ìfihàn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe àyípadà ìṣe yìí wọn sì fi tàdúràtàdúrà wá ìtọ́ni. Ìfihàn náà wá sí Ààrẹ Ìjọ Spencer W. Kimball ó sì jẹ́ fífi múlẹ̀ sí àwọn olùdarí Ìjọ mĩràn ninú Témpìlì ti Salt Lake ní 1 Oṣù Kẹfà 1978. Ìfihàn náà ṣe àmúkúrò gbogbo ìdènà tí ó níí ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà, tí ó ti fi ìgbàkan jẹ́ mímúlò sí ọ̀rọ̀ oyè-àlùfáà.