Ìpín 32
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí Parley P. Pratt ati Ziba Peterson, ní Manchester, New York, ní ìbẹ̀rẹ̀ Oṣù Kẹwàá, 1830. Àwọn alàgbà ní ìmọ̀lára ìfọkànsí ati ìfẹ́ nla nípa àwọn ará Lámánì, àwọn ẹnití Ìjọ ti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìbùkún wọn láti inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní àyọrísí, a bẹ̀bẹ̀ pé kí Olúwa fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn nípa bóyá kí á rán àwọn alàgbà ní àkókò náà sí àwọn ẹ̀yà Índíà tí wọ́n wà ní apá ìhà Ìwọ̀ oòrùn. Ìfihàn yìí ni ó tẹ̀lée.
1–3, Parley P. Pratt àti Ziba Peterson ni a pè láti wàásù sí àwọn ara Lámánì àti láti tẹ̀lé Oliver Cowdery àti Peter Whitmer Kékeré lọ; 4–5, Wọ́n níláti gbàdúrà fún òye nípa àwọn ìwé mímọ́.
1 Àti pé nísisìyí nípa ìránṣẹ́ mi Parley P. Pratt, kíyèsíi, mo wí fún un pé bí èmi ṣe wà láàyè èmi fẹ́ pé kí òun ó kéde ìhìnrere mi àti kí òun sì kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi, kí òun sì jẹ́ ọlọ́kàn tutu àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.
2 Àti pé èyíinì tí èmi ti yàn fún un ni pé kí ó lọ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi, Oliver Cowdery àti Peter Whitmer Kékeré, sí inú aginjù lààrin àwọn ará Lámánì.
3 Àti Ziba Peterson pẹ̀lú yíò lọ pẹ̀lú wọn; àti èmi tìkaraàmi yíò lọ pẹ̀lú wọn èmi yíò sì wà lààrin wọn; àti pé èmi ni Alágbàwí wọn pẹ̀lú Bàbá, ohunkóhun kì yíò sì lè borí wọn.
4 Àti pé wọn yíò ṣe àkíyèsí èyítí a ti kọ, wọn kì yíò sì ṣe bí ẹnipé wọ́n gba ìfihàn míràn; àti pé wọn yíò máa gbàdúrà nígba-gbogbo pé kí èmi ó lè ṣí awọn ohun kannáà sí òye wọn.
5 Àti pé wọn yíò ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọn kì yíò sì fi wọ́n ṣeré, èmi yíò sì bùkún fún wọn. Amin.