Ìpín 100
Ìfihàn tí a fifún Wòlíì Joseph Smith àti Sidney Rigdon, ní Perrysburg, New York, 12 Oṣù Kẹwã 1833. Àwọn arákùnrin méjì náà, nítorítí wọ́n kò ti wà pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, ní ìmọ̀lára ìtara díẹ̀ nípa wọn.
1–4, Joseph àti Sidney niláti kéde ìhìnrere fún ìgbàlà àwọn ọkàn; 5–8, A ó fi fún wọn ní wákàtí náà gan an ohun tí wọn yíò wí; 9–12, Sidney ni yíó jẹ́ agbẹnusọ Joseph ni yíò sì jẹ́ olùfihàn àti alágbára nínú ẹ̀rí; 13–17, Olúwa yíò gbe àwọn ènìyàn mímọ́ kan dìde, àwọn olùgbọ́ràn ni a ó sì gbàlà.
1 Lõtọ́, báyìí ni Olúwa wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi Sidney àti Joseph, àwọn ẹbí yín wà dáradára; wọ́n wà ní ọwọ́ mi, èmi yíò sì ṣe sí wọn bí ó ṣe dára ní ojú mi; nítorí nínú mi ni gbogbo agbára wà.
2 Nítorínáà, ẹ tẹ̀lé mi, kí ẹ sì tẹ́tí sí ìmọ̀ràn èyítí èmi yíò fi fún yín.
3 Ẹ kíyèsíi, ẹ sì wòó, èmi ní àwọn ènìyàn púpọ̀ ní ìhín yìí, ní àwọn agbègbè yíká káàkiri; àti pé àwọn ìlẹ̀kùn àìtàṣé ni a ó ṣí sílẹ̀ ní àwọn agbègbè yíká káàkiri ní ilẹ̀ ìlà oòrùn yìí.
4 Nítorínáà, èmi, Olúwa, ti fún yín ní ààyè láti wá sí ìhín yìí; nítorí báyìí ní ó tọ̀nà ní ojú mi fún ìgbàlà àwọn ọkàn.
5 Nítorínáà, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ gbé ohùn yín sókè sí àwọn ènìyàn yìí, ẹ sọ àwọn èrò inú tí èmi yíò fi sínú ọkàn yín, a kì yíò sì dààmú yín níwájú àwọn ènìyàn;
6 Nítorí a ó fi fún yín ní wákàtí gan an, bẹ́ẹ̀ni, ní ìṣẹjú gan an, ohun tí ẹ̀yin yíò wí.
7 Ṣùgbọ́n òfin kan ni èmi fi fún yín, pé ẹ̀yin yíò kéde ohunkohun tí ẹ bá kede ní orúkọ mi, ní fífi ọkàn sí ipò ọ̀wọ̀, nínú ẹ̀mí ìwà-pẹ̀lẹ́, nínú ohun gbogbo.
8 Èmi sì fi ìlérí yìí fún yín, pé níwọ̀nbí ẹ̀yin bá ṣe èyí Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ó tàn jade ní ìjẹ́rìí àkọsílẹ̀ sí àwọn ohun gbogbo èyíkéyìí tí ẹ̀yin yíò sọ.
9 Ó sì tọ̀nà lójú mi pé kí ìwọ, ìránṣẹ́ mi Sidney, ó jẹ́ agbẹnusọ kan sí àwọn ènìyàn yí; bẹ́ẹ̀ni, lõtọ́, èmi yíò yàn ọ́ sí ìpè yìí, àní láti jẹ́ agbẹnusọ kan sí ìránṣẹ́ mi Joseph.
10 Èmi yíò sì fún un ní agbára láti jẹ́ alágbara nínú ẹ̀rí.
11 Èmi yíò sì fún ọ ní agbára láti di alágbára nínú ṣíṣe àsọyé gbogbo ìwé mímọ́, kí ìwọ ó lè jẹ́ agbẹnusọ kan sí òun, òun yíò sì jẹ́ olùfihàn sí ìwọ, kí ìwọ ó lè mọ dídánilójú ohun gbogbo nípa àwọn ohun tí ìjọba mi ní orí ilẹ̀ ayé.
12 Nítorínáà, ẹ tẹ̀ síwájú ní ìrìnàjò yín kí ẹ sì jẹ́kí ọkàn yín ó yọ̀; nítorí ẹ kíyèsíi, ẹ sì wòó, èmi wà pẹ̀lú yín àní títí dé òpin.
13 Àti nísisìyí èmi fún yín ní ọ̀rọ̀ kan nípa Síónì. Síónì ni a ó rà-padà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a bá a wí fún àkókò díẹ̀.
14 Àwọn arákùnrin yín, ìránṣẹ́ mi Orson Hyde àti John Gould, wà ní ọwọ́ mi; àti pé níwọ̀nbí wọ́n bá pa àwọn òfin mi mọ́ a ó gbà wọ́n là.
15 Nítorínáà, ẹ jẹ́kí á tu ọkàn yín nínú; nítorí ohun gbogbo yíò ṣiṣẹ́ papọ̀ fún rere sí àwọn tí wọ́n bá rìn déédé, àti sí ìyàsímímọ́ ìjọ.
16 Nítorí èmi yíò gbé àwọn ènìyàn aláìlẽrí kan dìde sí ara mi, tí wọn yíò sìn mí ní òdodo;
17 Àti pé gbogbo àwọn tí wọ́n bá ké pe orúkọ Olúwa, tí wọ́n sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, ni a ó gbàlà. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amín.