Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 2


Ìpín 2

Àwọn ohun tí a fà yọ nínú ìwé ìtàn Joseph Smith ní ṣíṣe àtúnsọ àwọn ọ̀rọ ángẹ́lì Mórónì sí Wòlíì Joseph Smith, nígbàtí ó wà ní ilé bàbá Wòlíì ní Manchester, New York, ní ìrọ̀lẹ́ 21 Oṣù Kẹsãn 1823. Moroni ni ìkẹhìn nínú àwọn ọ̀pọ̀ ònkọ̀tàn tí wọn ti ṣe àkọsílẹ̀ èyí tí ó wà níwájú gbogbo ayé nísisìyí gẹ́gẹ́bí Ìwé Ti Mọ́mọ́nì. (Ṣe àfiwé Málákì 4:5–6; bákannáà ìpín 27:9; 110:13–16; àti 128:18.)

1, Elijah ni yíò fi oyè-àlùfáà hàn; 2–3, Àwọn ìlérí ti àwọn bàbá ni a gbìn sínú ọkàn àwọn ọmọ.

1 Kíyèsíi, èmi yíò fi oyè àlùfáà hàn sí ọ, láti ọwọ́ Wòlíì Elijah, ṣíwájú bíbọ̀ ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa.

2 Òun yíò sì gbìn sí ọkàn àwọn ọmọ awọn ìlérí tí a ṣe fún àwọn bàbá, ati ọkàn ti àwọn ọmọ yíò sì yí sí ọ̀dọ̀ àwọn bàbá wọn.

3 Bí èyí kò bá rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ilé ayé ni yíò di ìfiṣòfò ní bíbọ̀ rẹ̀.