Ìpín 99
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith sí John Murdock, 29 Oṣù Kẹjọ 1832, ní Hiram, Ohio. Fún bíi ọdun kan ó lé, John Murdock ti nwàásù ìhìnrere nígbàtí àwọn ọmọ rẹ̀—aláìníyàá lẹ́hìn ikú ìyàwó rẹ̀, Julia Clapp, ni Oṣù Kẹrin 1831—gbé pẹ̀lú àwọn ẹbí mĩràn ní Ohio.
1–8, John Murdock ni a pè láti kéde ìhìnrere, àti pé àwọn wọnnì tí wọ́n gbà á, gba Olúwa, wọn yíò sì rí àánú gbà.
1 Kíyèsíi, báyìí ni Olúwa wí fún ìránṣẹ́ mi John Murdock—a ti pè ọ́ láti lọ sí inú àwọn orílẹ̀-èdè apá ìla oòrùn láti ojúlé sí ojúlé, láti ìletò sí ìletò, àti láti ìlú nlá sí ìlú nlá, láti kéde ìhìnrere ayérayé mi sí àwọn olùgbé ibẹ̀, láàrin inúnibíni àti ìwà búburú.
2 Ẹnití ó bá sì gbà ìwọ gbà èmi; ìwọ yíò sì ní agbára láti kéde ọ̀rọ̀ mi ní ìfarahàn ti Ẹ̀mí Mímọ́ mi.
3 Àti pé ẹnití ó bá gbà ọ́ bíi ọmọ kékeré, gba ìjọba mi; ìbùkún sì ni fún wọn, nítorí wọn yíò rí àánú gbà.
4 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kọ ìwọ sílẹ̀ ni Baba mi yío kọ̀ sílẹ̀ àti ilé rẹ̀; àti pé ìwọ yíò wẹ ẹsẹ̀ rẹ mọ́ ní àwọn ibi ìkọ̀kọ̀ ní ojú ọ̀nà fún ẹ̀rí kan lòdì sí wọ́n.
5 Àti kíyèsíi, sì wòó, èmi nbọ̀ kánkán sí ìdájọ́, láti yí ẹni gbogbo lọ́kàn padà níti ìṣe àiwàbíọlọ́run wọn èyítí wọn ti ṣe sí mi, bí a ṣe kọ ọ́ nípa mi nínú àwọn ìwé náà.
6 Àti nísisìyí, lõtọ́ ni mo wí fún ọ, pé kò tọ́ kí ìwọ ó lọ́ títí tí a ó fi pèsè fún àwọn ọmọ rẹ, àti tí ìwọ yíò fi rán wọn lọ pẹ̀lú ìyọ́nú sí ọ̀dọ̀ bíṣọ́ọ̀pù ti Síónì.
7 Àti lẹ́hìn àwọn ọdún díẹ̀, bí ìwọ bá fẹ́ láti ọ̀dọ̀ mi, ìwọ̀ lè lọ sókè bákannáà sí ilẹ̀ rere náà, láti ni ogún tìrẹ;
8 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìwọ yíò tẹ̀síwájú nínú kíkéde ìhìnrere mi títí tí a ó fi mú ọ́ kúrò. Amín.