Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84


Ìpín 84

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, 22 àti 23 Oṣù Kẹsãn 1832. Láàrin inú Oṣù Kẹsãn, àwọn alàgbà ti bẹ̀rẹ̀ sí padà láti ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn ní àwọn ìpínlẹ̀ ìlà oòrùn àti láti jíyìn nípa àwọn iṣẹ́ wọn. O jẹ́ ìgbà tí wọ́n wà papọ̀ ní àkókò ayọ̀ yìí ni a gba ìbánisọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀lé yìí. Wòlíì náà pèé ní ìfihàn ní oríi oyè àlùfáà.

1–5, Ìlú Jérúsálẹ́mù titun àti tẹ́mpìlì ni yíò di kíkọ́ ní Missouri; 6–17, Ìlà oyè àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Mósè sí Ádámù ni a fi fúnni; 18–25, Oyè àlùfáà títóbi jù ni ó di kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ Ọlọ́run mú; 26–32, Oyè àlùfáà kékeré ni ó di kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì àti ti ìhìnrere ìmúrasílẹ̀ mú; 33–44, Ènìyàn jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ ìbúra àti májẹ̀mú ti oyè àlùfáà; 45–53, Ẹ̀mí Krístì nfi òye yé àwọn ènìyàn, àwọn aráyé sì wà nínú ẹ̀ṣẹ̀; 54–61, Àwọn Ẹni Mímọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́rìí nípa àwọn ohun wọnnì tí wọ́n ti gbà, 62–76, Wọ́n níláti wàásù ìhìnrere, àwọn àmì yíò sì tẹ̀lée; 77–91, Àwọn alàgbà níláti jade lọ láì mú àpò owó tàbí àpamọ́wọ́, Olúwa yíò sì mójútó gbogbo àwọn àìní wọn; 92–97, Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti ègún ndúró de àwọn wọnnì tí wọ́n kọ ìhìnrere; 98–102, Orin titun ti ìràpadà Síónì ni a fi fúnni; 103–110, Ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn dúró sí ipò iṣẹ́ tirẹ̀ àti kí òun ṣiṣẹ́ nínú ìpè tirẹ̀; 111–120, Àwọn ìránṣẹ́ Olúwa níláti kéde àwọn ohun ìríra ti ìsọdahoro àwọn ọjọ́ ìkẹhìn.

1 Ìfihàn ti Jésù Krístì kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ Joseph Smith Kékeré, àti àwọn alàgbà mẹ́fà, bí wọ́n ṣe pa ọkàn wọn pọ̀ tí wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè sí ibi gíga.

2 Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀rọ̀ Olúwa nípa ìjọ rẹ̀, tí a gbé kalẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn fún ìmúpadàbọ̀ sípò àwọn ènìyàn rẹ̀, bí òun ṣe sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn Wòlíì rẹ̀, àti fún ìkójọ pọ̀ àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀ láti dúró ní orí Òkè Síónì, èyí tí yíò jẹ́ ìlú nlá Jérúsálẹ̀mù Titun.

3 Ìlú nlá èyí tí a ó kọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìpín ti tẹ́mpìlì, èyí tí a yàn nípa ìka Olúwa, ní ãlà-ilẹ̀ apá ìwọ̀ oòrùn ti Ìpínlẹ̀ Missouri, tí a sì yà sí mímọ́ lati ọwọ́ Joseph Smith Kékeré, àti àwọn míràn àwọn tí inú Olúwa dùn sí gidigidi.

4 Lõtọ́ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa, pé ìlú nlá Jerúsálẹ́mù Titun ni a ó kọ́ nípa ìkójọpọ̀ àwọn enìyàn mímọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ìhín yìí, àní ní ibi tẹ́mpìlì náà, tẹ́mpìlì èyítí a ó gbé sókè ní ìran yìí.

5 Nítorí lõtọ́ ìran yìí kì yíò kọjá lọ tán títí tí a ó fi kọ́ ilé kan fún Olúwa, ìkũkũ kan yíò sì sinmi ní oríi rẹ̀, ìkũkũ èyítí yíò jẹ́, àní ògo ti Olúwa, èyí tí yíò kún inú ilé náà.

6 Àti pé àwọn ọmọ Mósè, gégébí Oyè Àlùfáà Mímọ́ èyí tí òun gbà ní abẹ́ ọwọ́ bàbá ìyàwó rẹ̀, Jẹ́trò;

7 Jẹ́trò sì gbà á lábẹ́ ọwọ́ Kálẹ́bù;

8 Kálẹ́bù sì gbà á lábẹ́ ọwọ́ Élíhù;

9 Àti Élíhù lábẹ́ ọwọ́ Jérémì;

10 Àti Jérémì lábẹ́ ọwọ́ ti Gádì;

11 Àti Gádì lábẹ́ ọwọ́ Ésíásì;

12 Àti Ésíásì sì gbà á lábẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run.

13 Ésíásì pẹ̀lú gbé ayé ní àwọn ọjọ́ Ábráhámù, a sì bùkún fún un nípasẹ̀ rẹ̀—

14 Ábráhámù tí ó gba oyè àlùfáà náà láti ọ̀dọ̀ Melkisédékì, ẹnití ó gbà á nípasẹ̀ ìdílé àwọn bàbá rẹ̀, àní títí dé ọ̀dọ̀ Nóà;

15 Àti láti ọ̀dọ̀ Nóà títí dé Énọ́kù, nípasẹ̀ ìdílé àwọn bàbá wọn;

16 Àti láti ọ̀dọ̀ Énọ́kù sí Ábẹ́lì, ẹni tí a pa nípa ìdìtẹ̀ arákùnrin rẹ̀, ẹnití ó gba oyè àlùfáà náà nípa àwọn òfin Ọlọ́run, láti ọwọ́ bàbá rẹ̀ Ádámù, ẹni tí ó jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́—

17 Oyè àlùfáà náà èyití ó tẹ̀síwájú nínú ìjọ Ọlọ́run ní gbogbo ìrandíran, àti tí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ tàbí òpin àwọn ọdún.

18 Olúwa sì fi ìdí oyè àlùfáà kan múlẹ̀ bákannáà ní orí Áárónì àti èso rẹ̀, jákèjádò gbogbo ìrandíran wọn, oyè àlùfáà náà èyí tí ó tẹ̀síwájú bákannáà àti tí ó dúró títí láe pẹ̀lú oyè àlùfáà náà èyítí ó tẹ̀lé ètò mímọ́ jùlọ ti Ọlọ́run.

19 Àti oyè àlùfáà tí ó ga jù yìí nṣe àkóso ìhìnrere ó sì di kọ́kọ́rọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọ̀ba náà mú, àní kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ ti Ọlọ́run.

20 Nítorínáà, nínú àwọn ìlànà ibẹ̀, agbára ìwàbí Ọlọ́run fi ara hàn.

21 Àti láìsí àwọn ìlànà ibẹ̀, àti àṣẹ ti oyè-àlùfáà, agbára ìwàbí Ọlọ́run kò lè fi ara hàn fún àwọn ènìyàn nínú ẹran ara;

22 Nítorí láì sí èyí ènìyàn kan kò le rí ojú Ọlọ́run, àní Baba, kí ó sì wà láàyè.

23 Nísisìyí èyí ni Mósè kọ́ni kedere sí àwọn ọmọ Isráẹ́lì nínú aginjù, ó sì fi taratara wá ọ̀nà láti yà àwọn ènìyàn rẹ̀ sí mímọ́ kí wọ́n ó lè rí ojú Ọlọ́run;

24 Ṣùgbọ́n wọ́n sé ọkàn wọn le wọ́n kò sì le fi ara da wíwà lọ́dọ̀ rẹ̀; nítorínáà, Olúwa nínú ìbínú rẹ̀, nítorí ìbínú rẹ̀ ru sókè sí wọn, búra pé wọn kì yíò wọlé sínú ìsinmi òun nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù, ìsinmi náà èyí tí í ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ògo rẹ̀.

25 Nítorínáà, ó mú Mósè kúrò ní ààrin wọn, àti Oyè Àlùfáà Mímọ́ bákannáà;

26 Oyè àlùfáà tí ó kéré sì tẹ̀síwájú, òyè àlùfáà náà èyí tí ó di kọ́kọ́rọ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì mú àti ti ìhìn ìmúrasílẹ̀;

27 Ìhìnrere èyítí ó jẹ́ ìhìnrere ti ironúpìwàdà àti ti ìrìbọmi, àti ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀, àti òfin ti àwọn àṣẹ ti ara, èyí ti Olúwa nínú ìbínú rẹ̀ mú kí ó tẹ̀síwájú pẹ̀lú ilé Áarónì ní ààrin àwọn ọmọ Ísráẹ́lì títí kan Jòhánnù, ẹni tí Ọlọ́run gbé sókè, ẹnití ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti inú ìyá rẹ̀.

28 Nítorí a rì í bọmi nígbàtí ó sì wà ní èwe rẹ̀, a sì yàn án nípasẹ̀ ángẹ́lì Ọlọ́run ní àkókò tí ó pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ sínú agbára yìí, láti bi ìjọba àwọn Júù ṣubú, àti láti ṣe ọnà Olúwa ní títọ́ ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀, láti jẹ́ kí wọn ó múrasílẹ̀ fún bíbọ̀ Olúwa, ní ọwọ́ ẹnití a fi gbogbo agbára sí.

29 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn ipò iṣẹ́ alàgbà àti ti bíṣọ́ọ̀pù jẹ́ àfikún tí ó ṣe pàtàkì ní jíjẹ́ ti oyè àlùfáà gíga.

30 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, àwọn ipò iṣẹ́ ti olùkọ́ àti ti díakónì jẹ́ ìfikún pàtàkì nípa jíjẹ́ ti oyè àlùfáà tí ó kéré jù, òyè àlùfáà èyítí a fi ẹsẹ̀ rẹ̀ mulẹ̀ ní orí Áarónì àti àwọn ọmọ rẹ̀.

31 Nítorínáà, bí èmi ṣe wí nípa àwọn ọmọ Mósè—nítorí àwọn ọmọ Mósè àti bákannáà àwọn ọmọ Áarónì yíò rú ẹbọ-ọrẹ àti ẹbọ kan tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà nínú ilé Olúwa, ilé èyí tí a ó kọ́ sí Olúwa nínú ìran yìí, ní ibi tí a ti yà-sọ́tọ̀ bí èmi ṣe ti yàn—

32 A ó sì kún inú àwọn ọmọ Mósè àti ti Áarónì fún ògo Olúwa, ní orí òkè Síónì ní inú ilé Olúwa, ọmọ ẹni tí ẹ̀yin í ṣe; àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ bákannáà tí èmi ti pè tí mo sì ti rán jade láti kọ́ ìjọ mi.

33 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ olõtọ́ sí gbígba àwọn oyè-àlùfáà méjèèjì wọ̀nyí tí èmi ti sọ nípa wọn, àti sí gbígbé ìpè wọn ga, ni a yà sí mímọ́ nípa Ẹ̀mí sí sísọ ara wọn di ọ̀tun.

34 Wọ́n di àwọn ọmọkùnrin Mósè àti ti Áarónì àti irú ọmọ Ábráhámù, àti ìjọ àti ìjọba, àti àyànfẹ́ Ọlọ́run.

35 Àti bákannáà gbogbo àwọn tí wọ́n gba oyè-àlùfáà yìí wọ́n gbà mí, ni Olúwa wí;

36 Nítorí ẹni náà tí ó gba àwọn ìránṣẹ́ mi gbà mí;

37 Àti pé ẹnití ó bá gbà mí gba Baba mi;

38 Ẹnití ó bá sì gbà Baba mi gba ìjọba Baba mi; nítorínáà gbogbo ohun tí Baba mi ní ni a ó fi fún un.

39 Àti èyí gẹ́gẹ́bí ìbúra àti májẹ̀mú èyí tí ó jẹ́ ti oyè àlùfáà náà.

40 Nítorínáà, gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n gbà oyè-àlùfáà náà, gba ìbúra yìí àti májẹ̀mú ti Bàbá mi, èyí tí òun kò leè rekọjá, tàbí kí á ṣí i ní ipò padà.

41 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ré májẹ̀mú yìí kọjá lẹ́hìn tí ó ti gbà á, àti tí ó yí padà kúrò níbẹ̀ pátápátá, kì yíò ní ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ó nbọ̀.

42 Ègbé sì ni fún gbogbo àwọn wọnnì tí wọn kò wá sínú oyè-àlùfáà yìí èyítí ẹ̀yin ti gbà, èyítí èmi fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nísisìyí ní orí ẹ̀yin tí ẹ wà níhĩn ní ọjọ́ yìí, nípa ohùn tèmi láti àwọn ọrun wá; àti pàápàá èmi ti fún àwọn ogun ọ̀run àti àwọn ángẹ́lì mi ní ojúṣe nípa yín.

43 Àti nísisìyí èmi fi òfin kan fún yín láti kíyèsára nípa ara yín, láti fi ãpọn ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ ti ìyè ayérayé.

44 Nítorí ẹ̀yin yíò gbé nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó jade wá láti ẹnu Ọlọ́run.

45 Nítorí ọ̀rọ̀ Olúwa jẹ́ òtítọ́, àti pé ohunkóhun tí ó bá jẹ́ òtítọ́ jẹ́ ìmọ́lẹ̀, ohunkóhun tí ó bá sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ jẹ́ Ẹ̀mí, àní Ẹ̀mí ti Jésù Krístì.

46 Ẹ̀mí ni ó sì nfi ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù èniyàn tí ó bá wá sí inú ayé; Ẹ̀mí náà ni ó sì nfi òye yé olúkúlùkù ènìyàn nípasẹ̀ ayé, èyí tí ó fetísílẹ̀ sí ohùn ti Ẹ̀mí.

47 Àti pé olúkúlùkù tí ó bá fetísílẹ̀ sí ohùn ti Ẹ̀mí wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àní Baba.

48 Baba sì kọ́ òun nípa májẹ̀mú náà èyí tí ó ti sọ di ọ̀tun àti tí ó ti fi múlẹ̀ lé orí yín, èyí tí a fi múlẹ̀ lé orí nitorí ti ara yín, kìí sìí ṣe nítorí tiyín nìkan, ṣùgbọ́n nítorí gbogbo aráyé.

49 Àti pé àwọn aráyé wà nínú ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì nkérora lábẹ́ òkùnkùn àti ní abẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀.

50 Àti nípa èyí ni ẹyin yíò le mọ̀ pé wọ́n wà lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀, nítorí wọn kò wá sí ọ̀dọ̀ mi.

51 Nítorí ẹnikẹ́ni tí kò bá wá sí ọ̀dọ̀ mi wà lábẹ́ ìdè ẹ̀ṣẹ̀.

52 Àti pé ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ohùn mi kò ní ìbárẹ́ pẹ̀lú ohùn mi, kìí sìí ṣe tèmi.

53 Àti nípa èyí ni ẹ̀yin yío lè mọ olódodo yàtọ̀ sí ẹni búburú, àti pé àwọn aráyé nkérora lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti òkùnkùn, àní nísisìyí.

54 Àti pé ọkàn yín ní àwọn ìgbà àtijọ́ ni a ti sọ di òkùnkùn nítorí àìgbàgbọ́, àti nítorítí ẹ̀yin ti fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ohun tí ẹ̀yin ti gbà—

55 Asán àti àìgbàgbọ́ èyítí ó ti mú gbogbo ìjọ wá sí abẹ́ ìdálẹ́bi.

56 Ìdálẹ́bi yìí sì sinmi lé orí àwọn ọmọ Síónì, àní gbogbo ènìyàn.

57 Wọn yíò sì wà ní abẹ́ ìdálẹ́bi yìí títí tí wọn yíò fi ronúpìwàdà àti tí wọ́n ó rantí májẹ̀mú titun, àní Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti àwọn òfin ti ìṣaájú èyítí èmi ti fifún wọn, kìí ṣe lati sọ nìkan, ṣùgbọ́n láti ṣe gẹ́gẹ́bí èyí tí èmi ti kọ—

58 Pé kí wọ́n ó lè mú èso jade tí ó yẹ fún ìjọba Bàbá wọn; bíbẹ́ẹ̀kọ́ ó ku ìjẹníyà kan àti ìdájọ́ lati di títú jade sí orí àwọn ọmọ Síónì.

59 Nítorí njẹ́ ó yẹ kí àwọn ọmọ ìjọ̀ba náà sọ ilẹ̀ mímọ́ mi di bíbàjẹ́? Lõtọ́, mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀kọ́.

60 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín ẹ̀yín tí ẹ ngbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi nísisìnyí, èyí tí í ṣe ohùn mi, alábùkúnfún ni ẹ̀yin níwọ̀n bí ẹ̀yin bá gba àwọn ohun wọ̀nyí;

61 Nítorí èmi yíò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín pẹ̀lú òfin yìí—kí ẹ̀yin ó wà ní ìdúróṣinṣin nínú ọkàn yín pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ẹ̀mí àdúrà, ní jíjẹ́rìí sí gbogbo ayé nípa àwọn ohun wọnnì èyí tí a ti sọ fún yín.

62 Nítorínáà, ẹ lọ sí gbogbo ayé; àti sí ibikíbi tí ẹ̀yin kò lè lọ ẹ̀yin yío ránṣẹ́, pé kí ẹ̀rí náà lè lọ láti ọ̀dọ̀ yín sí gbogbo ayé sí olúkúlùkù ẹ̀dá.

63 Àti bí mo ṣe sọ fún àwọn àpóstélì tèmi, àní bẹ́ẹ̀ni èmi wí fún yín, nítorí ẹ̀yin jẹ́ àpóstélì tèmi, àní olórí àlùfáà ti Ọlọ́run; ẹ̀yin ni àwọn tí Bàbá mi ti fi fúnmi; ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ mi;

64 Nítorínáà, bí mo ṣe sọ fún àwọn àpóstélì tèmi mo wí fún yín lẹ́ẹ̀kansíi, pé olúkúlùkù ọkàn tí ó bá gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ yín, àti tí a sì rì bọmi nípa omi fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀, yíò gba Ẹ̀mí Mímọ́ náà.

65 Àwọn àmi wọ̀nyí ni yíò sì tẹ̀lé àwọn tí wọ́n gbàgbọ́—

66 Ní orúkọ mi wọn yíò ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu;

67 Ní orúkọ mi wọn yíò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jade;

68 Ní orúkọ mi wọn yíò mú aláìsàn láradá;

69 Ní orúkọ mi wọn yíò la ojú àwọn afọ́jú, àti sọ etí àwọn adití di gbígbọ́ràn;

70 Àti ahọ́n àwọn oodi ni yíò sọ̀rọ̀;

71 Bí ẹnikẹ́ni bá sì fún wọn ní májèlé kì yíò pa wọ́n lára;

72 Àti oró ejò kì yíò ní agbára láti pa wọ́n lára.

73 Ṣùgbọ́n òfin kan ni èmi fi fún wọn, pé wọn kì yíò fi ara wọn yangàn nípa àwọn ohun wọ̀nyí, tàbí sọ̀rọ̀ nípa wọn niwájú aráyé; nítorí a fi àwọn nkan wọ̀nyí fún yín fún ànfàní yín àti fún ìgbàlà.

74 Lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, àwọn tí kò gba àwọn ọ̀rọ̀ yín gbọ́, tí a kò sì rìbọmi nínú omi ní orúkọ mi, fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n ó lè gba Ẹ̀mí Mímọ́, ni a ó fi gégũn, wọn kì yíò sì wá sínú ìjọba Baba mi níbi tí Bàbá mi àti èmi wà.

75 Àti ìfihàn yìí sí yín, àti òfin, ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ipá láti wákàtí yìí gan an lọ ní orí gbogbo aráyé, àti pé ìhìnrere jẹ́ sí gbogbo àwọn tí wọn kò tíì gbàá.

76 Ṣùgbọ́n, lõtọ́ ni mo wí fún gbogbo ẹ̀yin ti a ti fi ìjọba náà fún—láti ọ̀dọ̀ yín a gbọ́dọ̀ wàásù rẹ̀ sí wọn, pé wọ́n níláti ronúpìwàdà àwọn iṣẹ́ búburú wọn ti ìṣaájú; nítorí a ó bá wọn wí fún ọkàn búburú wọn ti àìgbàgbọ́, àti àwọn arákùnrin yín ní Síónì fún ìsọ̀tẹ̀ wọn lòdì sí yín ní àkókò tí èmi rán yín.

77 Àti lẹ́ẹ̀kansíi mo wí fún yín, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí láti ìsisìnyí lọ́ èmi yíò máa pè yín ní ọ̀rẹ́ mi, ó tọ̀nà pé kí èmi ó fi òfin yìí fún yín, pé kí ẹ̀yin ó jẹ́ àní bíi àwọn ọ̀rẹ́ mi ní àwọn ọjọ́ tí èmi wà pẹ̀lú wọn, ní rírin ìrìnàjò láti wàásù ìhìnrere ní agbára mi;

78 Nítorí èmi kò fi ààyè gbà fún wọn láti ní àpò owó tàbí àpamọ́wọ́, tàbí ẹ̀wù méjì.

79 Kíyèsíi, èmi rán yín jade láti dán aráyé wò, alágbàṣe sì yẹ fún owó iṣẹ́ rẹ̀.

80 Àti pé ẹnikẹ́ni tí yíò bá lọ wàásù ìhìnrere ti ìjọba náà, tí kò sì kùnà láti tẹ̀ síwájú láti jẹ́ olõtọ́ nínú ohun gbogbo, kì yíò ṣe àárẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀, tàbí kí ó ṣókùnkùn, bọ́yá nínú ara, ẹ̀yà ara, tàbí oríkèé; àti pé ẹyọ irun kan ní orí rẹ̀ kì yíò bọ́ sílẹ̀ láì ṣe àkíyèsí. Ebi kì yíò sì pa wọ́n, tàbí òngbẹ.

81 Nítorínáà, ẹ máṣe ṣe àníyàn fún ọ̀la, fún ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí aṣọ wo ni a ó fi wọ̀ yín.

82 Nitorí, ẹ kíyèsí àwọn lílì inú ìgbẹ́, bí wọ́n ṣe ndàgbà, wọn kìí ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ni wọn kìí ran òwú; àti pé àwọn ìjọba ayé, nínú gbogbo ògo wọn, kò ní ọ̀ṣọ́ tí ó dàbí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí.

83 Nítorí Bàbá yín, ẹnití nbẹ ni ọ̀run, mọ̀ pé ẹ̀yin nílò gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí.

84 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ọ̀la ó ṣe àníyàn fún àwọn ohun tirẹ̀.

85 Tàbí kí ẹ̀yin rò ṣaájú nípa ohun tí ẹ ó sọ; ṣùgbọ́n ẹ fi pamọ́ bíi ìṣúra sínú ọkàn yín ní gbogbo ìgbà àwọn ọ̀rọ̀ ìyè, a ó sì fi í fún un yín ní wákàtí gan an apákan èyí tí ẹ ó pín fún olúkúlùkù ènìyàn.

86 Nítorínáà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni láàrin yín, nítorí òfin yìí jẹ́ ti gbogbo àwọn olõtọ́ tí Ọlọ́run pè nínú ìjọ sínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ náà, láti wákàtí yìí mú àpò owó tàbí àpamọ́wọ́, tí ó njáde lọ láti kéde ìhìnrere yìí tí ṣe ti ìjọba náà.

87 Kíyèsíi, èmi rán yín jade láti bá ayé wí nípa gbogbo ìwà àìṣòdodo wọn, àti láti kọ́ wọn nípa ìdájọ́ kan èyí tí yíò wá.

88 Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà yín, níbẹ̀ ni èmi yíò wà pẹ̀lú, nítorí èmi yíò lọ́ ṣíwájú yín. Èmi yíò wà ní apá ọ̀tún yín àti ní apá òsì yín, Ẹ̀mí mi yíò sì wà nínú ọkàn yín, àti àwọn ángẹ́lì mi yíò yí yín ká, láti gbé yín sókè.

89 Ẹníkẹ́ni tí ó bá gbà yín gba èmi; òun kan náà yíò sì bọ́ọ yín, àti fi aṣọ wọ̀ yín, àti fún yín ní owó.

90 Àti pé ẹni tí ó bá fún yín ní oúnjẹ, tàbí fún yín ní aṣọ, tàbí fún yín ní owó, kì yíò pàdánù èrè rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.

91 Ẹnití kò bá sì ṣe àwọn nkan wọ̀nyí kìí ṣe ọmọ ẹ̀hìn mi; nípa èyí ni ẹ ó fi mọ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mi.

92 Ẹ̀ni tí kò bá gbà yín, ẹ lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ẹ̀yin níkan tìkara yín, ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín mọ́ àní pẹ̀lú omi, omi tí ó mọ́, bóyá nínú ooru tàbí nínú òtútù, kí ẹ sì jẹ́rìí nípa rẹ̀ sí Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run, kí ẹ má sì ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ẹni náà mọ́.

93 Àti ní ìletò tàbí ìlú nlá tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ ṣe bákannáà.

94 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ wádìí pẹ̀lú aápọn kí ẹ sì máṣe dásí; ègbé sì ni fún ilé náà, tàbí ìletò náà tàbí ìlú nlá náà tí ó bá kọ̀ yín, tàbí ọ̀rọ̀ yín, tàbí ẹ̀rí yín nípa mi.

95 Ègbé, mo tún wí i lẹ́ẹ̀kansíi, ni fún ilé náà, tàbí ìletò náà tàbí ìlú nlá náà tí ó kọ̀ yín, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ yín, tàbí ẹ̀rí yín nípa èmi;

96 Nítorí èmi, Alágbára jùlọ, ti gbé ọwọ́ mi lé orí àwọn orílẹ̀-èdè, láti jẹ wọ́n níyà fún ìwà búburú wọn.

97 Àti pé àwọn àjàkálẹ̀ àrùn yíò jade lọ, a kì yíò sì mú wọn kúrò ní orí ilẹ̀ ayé títí tí èmi yíò fi parí iṣẹ́ mi, èyí tí yíò yá kánkán nínú òdodo—

98 Títí tí gbogbo ènìyàn yíò fi mọ̀ mí, ẹnití ó ṣẹ́kù, àní láti ẹnití ó kéré jùlọ sí ẹnití ó tóbi júlọ, a ó sì kún wọn pẹ̀lú ìmọ̀ Olúwa, wọn yíò rí i ní ojú kojú, wọn yíò sì gbé ohùn wọn sókè, àti pẹ̀lú ohùn wọn lápapọ̀ kọ orin titun yìí, ní wíwí pé:

99 Olúwa ti mú Síónì padà lẹ́ẹ̀kansíi;Olúwa ti ra àwọn ènìyàn rẹ̀, Isráẹ́lì padà,Gẹ́gẹ́bí yíyàn ti oore ọ̀fẹ́,Èyítí a múwá sí ìmúṣẹ nípa ìgbàgbọ́Àti májẹ̀mú àwọn bàbá wọn.

100 Olúwa ti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà;Sátánì sì ti wà nínú ìdè kò sì sí àkókò mọ́.Olúwa ti kó ohun gbogbo jọ sí ọ̀kan.Olúwa tí mú Síónì wá sísàlẹ̀ láti òkè.Olúwa ti mú Síónì wá sí òkè láti ìsàlẹ̀.

101 Ilé ayé ti ṣe làálàá ó sì ti mú ipá rẹ̀ jade wá;A sì ti gbé òtítọ́ kalẹ̀ ní inú rẹ̀;Àti pé àwọn ọ̀run ti ní ojúrere sí orí rẹ̀;A sì ti wọ̀ ọ́ ní aṣọ pẹ̀lú ògo Ọlọ́run rẹ̀;Nítorí òun dúró láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

102 Ògo, àti ọlá, àti agbára, àti ipá,Ni fún Ọlọ́run wa; nítorí ó kún fún àánú,Òdodo, oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́, àti àlãfíà,Láéláé ati títí láé, Àmín.

103 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, ó tọ̀nà kí olúkúlùkù ènìyàn tí ó njáde lọ láti kéde ìhìnrere ayérayé mi, pé níwọ̀nbí wọ́n bá ní ìdílé, àti tí wọ́n bá gba owó nípa ẹ̀bùn, pé wọ́n níláti fi ránṣẹ́ sí wọn tàbí kí wọ́n lòó fún ànfàní wọn, gẹ́gẹ́bí Olúwa yíò ṣe darí wọn, nítorí báyìí ni ó dára ní ojú mi.

104 Ẹ sì jẹ́kí àwọn tí wọn kò ní ìdílé, tí wọ́n gba owó, fi ránṣẹ́ sí bíṣọ́ọ̀pù ní Síónì, tàbí sí bíṣọ́ọ̀pù ní Ohio, kí á lè yàá sí mímọ́ fún mímú àwọn ìfihàn jade wá àti ìwé títẹ̀ náà, àti fún àgbékalẹ̀ Síónì.

105 Àti pé bí ẹnikẹ́ni bá fún ẹnikan nínú yín ní ẹ̀wù kan, tàbí ẹ̀wù alákànpọ̀ kan, ẹ mú èyí tí ó ti gbó fún aláìní, kí ẹ sì lọ ní ọ̀nà yín nínú ayọ̀.

106 Àti bí ẹnikẹ́ni láàrin yín bá jẹ́ alágbára nínú Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí òun mú òun tí ó jẹ́ aláìlágbára kan pẹ̀lú rẹ̀, pé kí òun lè dàgbàsókè nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo, kí òun náà lè di alágbára bákannáà.

107 Nítorínáà, ẹ mú àwọn tí a ti yàn sínú oyè àlùfáà tí ó kéré pẹ̀lú yín, kí ẹ sì rán wọn ṣaájú yín láti ṣe àwọn àdéhùn, àti láti tún ọ̀nà ṣe, àti láti lọ sí ibi àwọn àdéhùn tí ẹ̀yin tìkára yín kò bá lè mú ṣẹ.

108 Kíyèsíi, èyí ni ọ̀nà tí àwọn àpóstélì tèmi, ní ọjọ́ ìgbàanì, fi kọ́ ìjọ mi sí mi.

109 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn dúró ní ipò iṣẹ rẹ̀, kí ó sì ṣiṣẹ́ nínú ìpè rẹ̀; kí orí ó má sì ṣe sọ fún ẹsẹ̀ pé òun kò nílò ẹsẹ̀; nítorí láì sí ẹsẹ̀ báwo ni ara yíò ṣe lè dúró?

110 Bákannáà ni ara nílò olúkúlùkù ẹ̀yà ara, kí gbogbo wọn ó lè dàgbàsókè papọ̀, kí ètò àgọ́ ara lè wà ní pípé.

111 Àti kíyèsíi, àwọn àlùfáà gíga níláti rin ìrìn-àjò, àti bákannáà àwọn alàgbà, àti bákannáà àwọn àlùfáà tí ipò wọn kéré; ṣùgbọ́n àwọn díákónì àti àwọn olùkọ́ni nílati jẹ́ yíyàn láti ṣe àmójútó ìjọ, lati dúró bíi òjíṣẹ́ Olúwa sí ìjọ náà.

112 Àti bíṣọ́ọ̀pù, Newel K. Whitney, bákannáà níláti rin ìrìn-àjò yíkáàkiri àti ní ààrin gbogbo àwọn ìjọ, ní ṣíṣe àwárí àwọn tálákà láti mójútó àwọn àiní wọn nípa rírẹ àwọn ọlọ́rọ̀ sílẹ̀ àti àwọn agbéraga.

113 Ó níláti gba aṣojú kan pẹ̀lú látí ṣe àkóso àti lati ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ́ ti ara gẹ́gẹ́bí òun yíò ṣe darí.

114 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí bíṣọ́ọ̀pù ó lọ sí ìlú nlá New York, àti sí ìlú nlá Albany, àti pẹ̀lú sí ìlú nlá Boston, kí òun sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn ní àwọn ìlú nlá wọnnì pẹ̀lú ìró ìhìnrere náà, pẹ̀lú ohùn ariwo, ní ti ìsọdahoro àti ìparẹ́ èyítí ó dúró dè wọ́n bí wọn bá kọ̀ àwọn nkan wọ̀nyí.

115 Nítorí bí wọ́n bá kọ àwọn nkan wọ̀nyí wákàtí ìdájọ́ wọn súnmọ́ itòsí, àti pé àwọn ilé wọn ni a ó fi sílẹ̀ fún wọn ní ahoro.

116 Ẹ jẹ́ kí òun gbẹ́kẹ̀ lé mi òun kì yíò sì dààmú; àti pé ẹyọ kan nínú irun orí rẹ̀ kì yíò bọ́ sílẹ̀ láì ṣe àkíyèsí.

117 Àti lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin ìránṣẹ́ mi ìyókù, ẹ jade lọ bí ipò tí ẹ wà bá ṣe gbà yín láàyè, nínú oríṣiríṣi àwọn ìpè yín, sí àwọn ìlú nlá títóbi àti olókìkí àti àwọn ìletò, ní bíbá aráyé wí nínú òdodo fún gbogbo ìṣe wọn ti àìsòdodo àti àìwà bí Ọlọ́run, ní fífí lélẹ̀ kedere ati yíyéni yéké nípa ìsọdahoro ti ohun ìríra ní àwọn ọjọ́ tí ó kẹ́hìn.

118 Nítorí, pẹ̀lú yín ni Olúwa Alágbára Jùlọ wí, èmi yíò fa àwọn ìjọba wọn ya; èmi kì yíò mi ayé níkan, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run tí ó ntàn bíi ìràwọ̀ náà yíò wárìrì.

119 Nítorí èmi, Olúwa, ti na ọwọ́ mi jade láti lo àwọn agbára ọ̀run; ẹ̀yin kò lè rí i nísisìyí, síbẹ̀ ni àìpẹ́ ẹ̀yin yíò sì rí i, ẹ ó sì mọ̀ pé èmi ni, àti pé èmi yíò wá lati jọ́ba pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi.

120 Èmi ni Álfà àti Ómégà, ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin. Àmín.