Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 117


Ìpín 117

Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Far West, Missouri, 8 Oṣù Keje 1838, nípa àwọn ojúṣe ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ ti William Marks, Newel K. Whitney, àti Oliver Granger.

1–9, Àwọn ìránṣẹ́ Olúwa kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí àwọn ohun ti ara, nítorí “kíni ohun ìní jẹ́ sí Olúwa?”; 10–16, Wọ́n níláti kọ kíkéré ọkàn sílẹ̀, àwọn ẹbọ-ọrẹ wọn yíò sì jẹ́ mimọ́ sí Olúwa.

1 Lõtọ́ báyìí ni Olúwa wí fún ìránṣẹ́ mi William Marks, àti bákannáà sí ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney, ẹ jẹ́kí wọn ó yanjú àwọn iṣẹ́ òwò wọn kánkán kí wọ́n ó sì rìn ìrìnàjò láti ilẹ̀ Kirtland, kí èmi, Olúwa, tó rán àwọn ojò dídì sí orí ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi.

2 Ẹ jẹ́ kí wọn ó jí gìrì, kí wọn ó sì dìde, àti kí wọn ó jade wá, kí wọ́n má sì ṣe dúró pẹ́, nítorí èmi, Olúwa, ló pa á làṣẹ.

3 Nítorínáà, bí wọ́n bá dúró pẹ́ kì yíò dára fún wọn.

4 Ẹ jẹ́kí wọ́n ó ronúpìwàdà gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti gbogbo àwọn ìfẹ́ ojúkòkòrò wọn, níwájú mi, ni Olúwa wí; nítorí kínni ohun ìnì jẹ́ sí mi? ni Olúwa wí.

5 Ẹ jẹ́kí àwọn ohun ìní ti Kirtland ó jẹ́ yíyípadà fún àwọn gbèsè, ni Olúwa wí. Ẹ jẹ́kí wọn ó lọ, ni Olúwa wí, ohunkóhun tí ó bá sì ṣẹ́kù, ẹ jẹ́kí ó dúró ní ọwọ́ yín, ni Olúwa wí.

6 Nítorí èmi kò ha ní àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, àti pẹ̀lú àwọn ẹja inú òkun, àti àwọn ẹranko ti orí àwọn òkè? Èmi kò ha ti dá ilẹ̀ ayé? Èmi kò ha mọ ìpín gbogbo àwọn ọmọ ogun ti àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé?

7 Nítorínáà, èmi kì yíò ha sọ àwọn ibi ahoro di ilẹ̀ ọlọ́rã àti láti yọ ìtànná, àti láti mú jade ní ọ̀pọ̀? ni Olúwa wí.

8 Kò ha sí ààyè tó ní orí àwọn òkè ti Adam-ondi-Ahman, àti ní orí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Olaha Shineha, tàbí ní ilẹ̀ níbi tí Adamu gbé, tí ẹ ó fi ṣe ojúkòkòrò èyìínì tí ó jẹ́ kékeré, tí ẹ ó sì ṣe àìbìkítà àwọn ohun tí ó níyelórí jù?

9 Nitorínáà, ẹ wá sí ìhín yìí sí ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi, àní Síónì.

10 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi William Marks ó jẹ́ olõtọ́ lóri àwọn ohun díẹ̀, a ó sì sọ ọ́ di alákòóso ní orí púpọ̀. Ẹ jẹ́kí òun ó ṣe àkóso láàrin àwọn ènìyàn mi ní ìlú nlá ti Far West, kí òun sì di bíbùkún fún pẹ̀lú àwọn ìbùkún ti àwọn ènìyàn mi.

11 Ẹ jẹ́kí ìránṣẹ́ mi Newel K. Whitney ó ní ìtìjú fún ẹgbẹ́ Nikolaitanì àti gbogbo àwọn ohun ìríra ìkọ̀kọ̀ wọn, àti ti gbogbo kíkéré ọkàn rẹ̀ níwájú mi, ni Olúwa wí, kí òun sì wá sí ilẹ̀ ti Adam-ondi-Ahman, kí òun sì di bíṣọ́ọ̀pù kan sí àwọn ènìyàn mi, ni Olúwa wí, kìí ṣe ní orúkọ, ṣugbọ́n ní ojúṣe, ni Olúwa wí.

12 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, èmi rantí ìránṣẹ́ mi Oliver Granger; kíyèsíi, lõtọ́ ni mo wí fún un pé orúkọ rẹ̀ yíò wà ní ìrantí mímọ́ láti ìran dé ìran, láé ati títí láéláé, ni Olúwa wí.

13 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí ó fi ìtara jà fún ìràpadà ti Àjọ Ààrẹ Ìkínní ti Ìjọ mi, ni Olúwa wí; àti nígbàtí òun bá ṣubú òun yíò tún dìde lẹ́ẹ̀kansíi, nítorí ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ yíò jẹ́ mímọ́ jù sími ju ọrọ̀ rẹ̀ lọ, ni Olúwa wí.

14 Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí òun wá sí ìhín yìí kánkán, sí ilẹ̀ Síónì; àti ní àkókò tí ó yẹ, a ó sọ ọ́ di oníṣòwò kan sí orúkọ mi, ni Olúwa wí, fún ànfàní àwọn ènìyàn mi.

15 Nítorínáà ẹ máṣe jẹ́kí ẹnikẹ́ni ó pẹ̀gàn ìránṣẹ́ mi Oliver Granger, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́kí àwọn ìbùkún ti àwọn ènìyàn mi ó wà ní orí rẹ̀ láé ati tití láéláé.

16 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, lõtọ́ ni mo wí fún yín, ẹ jẹ́kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi ní ilẹ̀ Kirtland rantí Olúwa Ọlọ́run wọn, àti ilé mi pẹ̀lú, láti pa á mọ́, àti láti ṣe ìtọ́jú rẹ̀ ní mímọ́, àti láti ṣẹ́gun àwọn tí wọn nṣe pàṣípààrọ̀ owó, ní àkókò tí ó tọ́ ní ojú mi, ni Olúwa wí. Àní bẹ́ẹ̀ni. Àmín.