Àwọn Ìwé Mímọ́
Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 135


Ìpín 135

Ìkéde ti ikú ajẹ́rìíkú ti Wòlíì Joseph Smith àti arákùnrin rẹ̀, Hyrum Smith, Pátríákì náà, ní Carthage, Illinois, 27 Oṣù Kẹfà 1844. Ìwé yìí wà ní ìparí àtúntẹ̀ ti 1844 ti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú èyítí ó ti fẹ́rẹ̀ yọrí fún títẹ̀ nígbàti wọ́n pa Joseph Smith ati Hyrum Smith.

1–2, Joseph àti Hyrum kú ikú ajẹ́rìíkú nínú Ẹ̀wọ̀n Carthage; 3, Ipò gíga jùlọ ti Wòlíì náà ni a kéde; 4–7, Ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wọn njẹ́rìí sí òtítọ́ àti jíjẹ́ ti ọ̀run iṣẹ́ náà.

1 Láti fi èdídí di ẹ̀rí ìwé yìí àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a kéde ikú ajẹ́rìíkú ti Wòlíì Joseph Smith, àti Hyrum, Smith Pátríákì náà. A yìnbọn fún wọn nínú ẹ̀wọ̀n Carthage, ní 27 Oṣù Kẹfà, 1844, ní nkan bíi ago márùn ìrọ̀lẹ̀, láti ọwọ́ àgbájọ àwọn jàndùkú tí wọ́n dìhámọ́ra—tí wọ́n kun ara wọn sí dúdú—tí wọ́n tó bíi àádọ́jọ sí igba ènìyàn. Hyrum ni wọ́n kọ́kọ́ yìnbọn fún ó sì ṣubú jẹ́ẹ́, pẹ̀lú igbe kíkan: Mo kú o! Joseph fẹ́ bẹ́ láti ojú fèrèsé, a sì yìnbọn pa á níbi ìgbìyànjú, ó sì pariwó: Olúwa Ọlọ́run mi! Àwọn méjèjì ni a yìnbọn fún lẹ́hìn tí wọn ti kú tán, ní ọ̀nà ìkà, àwọn méjèjì sì gba ọta ìbọn mẹ́rin.

2 John Taylor àti Willard Richards, méjì nínú àwọn Méjìlá, nìkan ni àwọn ènìyàn tí wọ́n wà nínú yàrá ní àkókò náà; ẹni àkọ́kọ́ ní a pa lára ní ọ́nà ìkà pẹ̀lú ọta ìbọn mẹ́rin, ṣùgbọ́n tí ó ti gba ìlera láti ìgbà náà; ẹnikejì, nípa ìtọ́jú Ọlọ́run, yọ, àní láì sí ihò kan lára ẹ̀wù rẹ̀.

3 Joseph Smith, Wòlíì àti Aríran Ọlúwa, ṣe púpọ̀, yàtọ̀ sí Jésù nìkanṣoṣo, fún ìgbàlà àwọn ènìyàn nínú ayé yìí, ju ẹnikẹ́ni míràn tí ó ti gbé rí nínú rẹ̀. Ní àkókò kúkúrú ti ógún ọdún, òun ti mú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jade wá, èyítí ó túmọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run, ó sì ti jẹ́ ọ̀nà fún títẹ̀ ẹ́ jáde ní orí àwọn ìpín ilẹ̀ ayé méjì; ó ti rán ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ayérayé, èyí tí ó wà nínú rẹ̀, sí àwọn ìgun mẹ́rẹ̀rin ilẹ̀ ayé; ó ti mú àwọn ìfihàn àti àwọn òfin èyítí ó wà nínú ìwé Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú yìí jade wá, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìwé míràn ti ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ fún ire àwọn ọmọ ènìyàn; ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn Ẹni Mímọ̀ ti Ọjọ́-ìkẹ̀hìn jọ, ó tẹ ìlú nlá kan dó, ó sì fi òkìkí àti orúkọ kan sílẹ̀ tí kò ṣe é parun. Ó gbé ìgbé ayé nlá, ó sì kú ikú nlá ní ojú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn rẹ̀; àti bíi púpọ̀ nínú àwọn ẹni àmì òróró Olúwa ní àwọn ìgbà àtijọ́, ó ti ṣe èdídí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà sì ni arákùnrin rẹ̀ Hyrum. Ní ìyè, wọn kò pínyà, àti ní ikú, wọn kò yà ara wọn!

4 Nígbàtí Joseph lọ sí Carthage lati jọ̀wọ́ ara rẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn nkan èké ti òfin náà nbéèrè, ní ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta ṣaájú pípa rẹ̀, ó sọ pé: “Mo nlọ bí ọ̀dọ́ àgùtàn sí pípa; ṣùgbọ́n èmi dákẹ́ bí òwúrọ̀ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; mo ní ẹ̀rí ọkàn tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kan sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àti sí ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn. Èmi yíò kú bíi aláìṣẹ̀, àti síbẹ̀ a ó sọ nípa tèmi—a mọ̀ọ́mọ̀ pa á”—Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kannáà, lẹ́hìn tí Hyrum ti ṣetán láti máá lọ—ṣé a lè sọ pé fún pípa? bẹ́ẹ̀ni, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó rí—òun ka apákan abala tí ó tẹ̀lé yìí, nítòsí ìparí orí èkejìlá Ìwé ti Étérì, nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ó sì sẹ́ etí ìwé náà lé e ní orí:

5 Ó sì ṣe tí mo gbàdúrà sí Olúwa pé kí òun fún àwọn Kèfèrí ní ore ọ̀fẹ́, kí wọ́n ó lè ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Ó sì ṣe pé Olúwa wí fún mi: bí wọn kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kò já mọ́ nkan sí ìwọ, ìwọ ti jẹ́ olõtọ́; nítorínáà àwọn aṣọ rẹ ni á ó sọ di mímọ́. Àti nítorítí ìwọ ti rí àìlera rẹ, a ó sọ ọ́ di alágbára, àní sí jíjókòó nínú ibikan èyítí èmi ti pèsè nínú àwọn ilé bàbá mi. Àti nísisìyí èmi…kíni pé ó dígbóṣe sí àwọn Kèfèrí; bẹ́ẹ̀ni, àti bákannáà sí àwọn arákùnrin mi ẹnití mo fẹ́ràn, títí tí a ó tún pàdé níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ti Krístì, níbití gbogbo ènìyàn yíò mọ pé àwọn aṣọ mi kò ní àbàwọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ yín. Àwọn onímájẹ̀mú náà ti kú nísisìyí, májẹmú wọn sì nnípá.

6 Hyrum Smith jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rinlélógojì ní Oṣù kejì, 1844, Joseph Smith sì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlógójì ní Oṣù Kejìlá, 1843; àti láti ìgbà náà lọ ni a ó to àwọn orúkọ wọn sí àrin àwọn ajẹ́rìíkú ti ẹ̀sìn; àti pé ònkàwé ní ọ̀kọ̀ọ̀kan orílẹ̀-èdè ni a ó ránlétí pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti ìwé yìí tí Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ti ìjọ, gba ẹ̀jẹ̀ tí ó dárajùlọ nínú ònkà àkókò ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún láti mú wọn jade wá fún ìgbàlà ayé tí ó ti bàjẹ́; àti pé bí iná bá lè ba igi tutu jẹ́ fún ògo Ọlọ́run, yíò ṣe rọrùn tó láti jó àwọn igi gbígbẹ láti sọ ọgbà ajarà ìbàjẹ́ di mímọ́. Wọ́n gbé láàyè fún ògo; wọ́n kú fún ògo; ògo sì ni èrè ayérayé wọn. Láti ìran sí ìran ni orúkọ wọn yíò máa lọ sí irú ọmọ bíi àwọn òkúta iyebíye fún àwọn tí a ti yà sí mímọ́.

7 Wọn jẹ́ aláilẹ́ṣẹ̀ sí òfin kankan, bí a ti fihàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà ṣaájú, àti pé a ṣá há wọ́n mọ́ inú túbú nípasẹ̀ ìdìtẹ̀ àwọn ọ̀dàlẹ̀ àti àwọn ènìyàn búburú; àti pé ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ wọn ní orí ilẹ̀ Ẹ̀wọ̀n Carthage jẹ́ èdídí tí ó hàn gbangba tí a so mọ́ ẹ̀kọ́ àti ìgbàgbọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ọjọ́ Ìkẹhìn tí kò le jẹ́ kíkọ̀ sílẹ̀ fún ilé ẹjọ́ kankan ní orí ilẹ̀ ayé, àti ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ wọn ní orí apata ti Ìpínlẹ̀ Illinois, pẹ̀lú yíyẹ̀ ìlérí ti Ìpínlẹ̀ bí gómìnà ṣe jẹ́ ẹ̀jẹ́, ni ẹ̀rí kan sí òtítọ́ ti ìhìnrere àìlópin tí gbogbo ayé kò lè fi ẹ̀sùn kàn; àti ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wọn ní orí ọ̀págun òminira, àti ní orí ìwé àṣẹ magna charta ti Ìlẹ̀ Amẹ́ríkà, jẹ́ ikọ̀ kan fún ẹ̀sìn Jésù Krístì, tí yíò fi ọwọ́ tọ́ ọkàn àwọn olõtọ́ ènìyàn láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; àti pé ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ wọn, pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ ti gbogbo àwọn ajẹ́rìíkú ní abẹ́ pẹpẹ tí Jòhánnù rí, yíò kígbe sí Olúwa Àwọn Ọmọ Ogun títí tí òun yíò fi gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ náà ní orí ilẹ̀ ayé. Àmín.