Ìpín 43
Ìfihàn tí a fi fúnni nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, ní Kirtland, Ohio, ní Oṣù Kejì 1831. Ní àkókò yìí àwọn ọmọ ìjọ díẹ̀ ní ìyọnu nípa àwọn ènìyàn kan tí wọn nparọ́ pé àwọn náà jẹ́ olùfihàn. Wòlíì náà béèrè lọ́wọ́ Olúwa ó sì gba ìbánisọ̀rọ̀ yìí tí ó dárí sí àwọn àlàgbà ìjọ. Apá kínni sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ àkójọ ìjọ; apá tí ó kẹ́hìn jẹ́ ìkìlọ̀ tí àwọn alàgbà yíò fún àwọn orílẹ̀-èdè ayé.
1–7, Àwọn ìfihàn àti àwọn òfin má nwá nípasẹ̀ ẹnìkan tí a yàn; 8–14, àwọn Ẹni Mímọ́ ni a yà sí mímọ́ nípa síṣe ohun gbogbo ní mímọ́ níwájú Olúwa; 15–22, A rán àwọn Alàgbà jade láti kígbe ironúpìwàdà àti láti pèsè àwọn ènìyàn sílẹ̀ fún ọjọ́ nlá Olúwa; 23–28, Olúwa ké pe àwọn ènìyàn nípa ohùn ara Rẹ̀ àti nípasẹ̀ agbára àwọn àdánidá; 29–35, Ẹgbẹ̀rún ọdún náà àti gbígbé Sátánì dè yíò wá.
1 Áà ẹ fetísílẹ̀, ẹ̀yin alàgbà ijọ mi, kí ẹ sì fi etí sí àwọn ọ̀rọ̀ èyítí èmi yíò sọ fún yín.
2 Nítorí kíyèsíi, lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, pé ẹ̀yin ti gba àṣẹ fún òfin kan sí ìjọ mi, nípasẹ̀ ẹnì náà tí èmi ti yàn fún yín láti gbà àwọn òfin àti àwọn ìfihàn láti ọwọ́ mi.
3 Àti pé èyí ni ẹ̀yin yíò mọ̀ dájúdájú—pé kò sí ẹlòmíràn tí a yàn fún yín láti gba àwọn òfin àti àwọn ìfihàn títí tí a ó fi mú un kúrò, bí òun bá ngbé nínú mi.
4 Ṣùgbọ́n lõtọ́, lõtọ́, ni mo wí fún yín, pé a kì yíò yan ẹlòmíràn fún ẹ̀bùn yìí bíkòṣe pé ó jẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀; nítórí bí a bá gbà á lọ́wọ́ rẹ̀ òun kì yíò ni agbára mọ́ bíkòṣe láti yan ẹlòmíràn dípò ara rẹ̀.
5 Àti pé èyí yíò jẹ́ àṣẹ fún yín, pé kí ẹ máṣe gba àwọn ẹ̀kọ́ ti ẹni yìówù tí yío wá síwájú yín gẹ́gẹ́bí àwọn ìfihàn tàbí àwọn òfin;
6 Àti pé èyí ni èmi fi fún yín pé kí wọ́n má baà tàn yín jẹ, kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé wọn kìí ṣe tèmi.
7 Nítorí lõtọ́ ni mo wí fún yín, pé ẹni tí a bá yàn nípasẹ̀ mi yíò wọlé ní ẹnu ọ̀nà a ó sì yàn án gẹ́gẹ́bí èmi ṣe wí fún yín ṣaájú, láti kọ́ni ní àwọn ìfihàn wọnnì tí ẹ̀yin ti gbà àti tí ẹ ó gbà nípasẹ̀ ẹni náà tí èmi ti yàn.
8 Àti nísisìyí, ẹ kíyèsíi, èmi fún yín ní òfin kan, pé nígbàtí ẹ̀yin bá péjọ̀ pọ̀ ẹ̀yin yíò fi ẹ̀kọ́ àti òye fún ara yín, kí ẹ̀yin lè mọ̀ bí ẹ ó ti ṣe àti bí ẹ ó ṣe darí ìjọ mi, bí ẹ̀yin yíò ṣe ṣe àmúlò àwọn kókó ti àwọn òfin àti àwọn àṣẹ mi, tí èmi ti fi fúnni.
9 Àti pé bayìí ni ẹ̀yin yíò gba ẹ̀kọ́ nínú òfin ti ìjọ mi, tí a ó sì yà yín sí mímọ́ nípa èyí tí ẹ̀yin ti gbà, ẹ̀yin yíò sì so ara yín papọ̀ láti ṣe ohun gbogbo ní mímọ́ ní iwájú mi—
10 Pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin bá ṣe èyí, a ó fi ògo kún ìjọba èyí tí ẹ̀yin ti gbà. Níwọ̀n ìgbàtí ẹ̀yin kò bá sì ṣe é, a ó gbà á, àní èyí tí ẹ̀yin ti rí gbà.
11 Ẹ yọ àwọn àìṣedéédé èyítí ó wà lààrin yín kúrò; ẹ ya ara yín sí mímọ́ ni iwájú mi;
12 Àti bí ẹ̀yin bá sì fẹ́ àwọn ògo ti ìjọba náà, ẹ yan ìránṣẹ́ mi Joseph Smith Kékeré, kí ẹ sì tì í lẹ́hìn ní iwájú mi pẹ̀lú àdúrà ìgbàgbọ́.
13 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, mo wí fún yín, pé bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ti ìjọba náà, ẹ pèsè oúnjẹ àti aṣọ fún un, àti ohunkóhun tí òun bá nílò láti ṣe àṣeparí iṣẹ́ náà èyí tí mo ti pa láṣẹ fún un;
14 Àti pé bí ẹ̀yin kò bá ṣe èyí òun yíò wà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti gbà á, kí èmi ó lè ṣe àfipamọ́ fún ara mi àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ́ níwájú mi.
15 Lẹ́ẹ̀kansíi mo wí, ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin alàgbà ìjọ mi, ẹ̀yin tí mo ti yàn: A kò rán yín lọ láti gba ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n láti kọ́ àwọn ọmọ ènìyàn ní àwọn ohun tí èmi ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa agbára Ẹ̀mí mi.
16 A ó sì kọ́ọ yín láti òkè wá. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ a ó sì bùn yín ní ẹ̀bùn agbára, pé kí ẹ̀yin ó lè fi fúnni àní bí èmi ti sọ.
17 Ẹ fetísílẹ̀, nítorí, kíyèsíi, ọjọ́ nlá Olúwa súnmọ́ itòsí.
18 Nítorí ọjọ́ náà dé tán tí Olúwa yíò fọ́hùn rẹ̀ jade láti ọ̀run wá; àwọn ọ̀run yíò mì àti ayé yíò sì wárìrì, àti pé ipè Ọlọ́run yíò sì dún fún ìgbà pípẹ́ àti pẹ̀lú ariwo, yíò sì sọ fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó nsùn: Ẹ̀yin ènìyàn Mímọ́ ẹ dìde kí ẹ sì yè; ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹ dúró kí ẹ sì sùn títí tí èmi yíò fi tún pè lẹ́ẹ̀kansíi.
19 Nítorínáà ẹ di àmùrè yín bí bẹ́ẹ̀kọ́ a ó ríi yín lààrin àwọn ènìyàn búburú.
20 Ẹ gbé ohùn yín sókè kí ẹ má sì ṣe dásí. Ẹ pè àwọn orílẹ̀-èdè láti ronúpìwàdà, àti àgbà àti ọ̀dọ́, àti òndè àti òmìnira, wipe: Ẹ múrasílẹ̀ fún ọjọ́ nlá Olúwa;
21 Nítorí bí èmi, tí ó jẹ́ ènìyàn, bá gbé ohùn mi sókè tí mo sì pè yín kí ẹ ronípìwàdà, tí ẹ̀yin sì kórĩra mi, kín ni ẹ̀yin yíò wí nígbàtí ọjọ́ náà bá dé nígbàtí àwọn ààrá bá nfọ ohùn wọn láti àwọn òpin ilẹ̀ ayé, tí wọ́n nsọ̀rọ̀ sí etí gbogbo àwọn tí wọ́n wà láàyè, wipe—Ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì múrasílẹ̀ fún ọjọ́ nlá Olúwa?
22 Bẹ́ẹ̀ni, àti lẹ́ẹ̀kansíi, nígbàtí àwọn mọ̀nàmọ́ná bá nkọ láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ rẹ̀, tí wọn yíò sì fọhùn wọn sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà láàyè, tí wọn yíò sì jẹ́ kí etí gbobo àwọn tí wọ́n bá gbọ́ hó, nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí—Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ọjọ́ nlá Olúwa dé tán.
23 Àti lẹ́ẹ̀kansíi, Olúwa yíò fọhùn rẹ̀ jáde láti ọ̀run wá, wipe: Ẹ fetísílẹ̀, Áà ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ayé, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà ẹnití ó dáa yín.
24 Áà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ayé, ìgbà melõ ni èmi ti kó yín jọ papọ̀ bí àgbébọ̀ adìẹ ṣe nràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀ ní abẹ́ ìyẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kì yíò fẹ́!
25 Ìgbà mélòó ni èmi ti pè yín láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi, àti nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹlì, àti nípa ohùn tèmi, àti nípa ohùn àwọn ààrá sísán, àti nípa ohùn àwọn mọ̀nàmọ́ná kíkọ, àti nípa ohùn àwọn ìjì líle, àti nípa ohùn àwọn ilẹ̀ ríri, àti nípa àwọn yìnyín nlá, àti nípa ohùn àwọn ìyàn àti ti àjàkálẹ̀ àrùn lónírúurú, àti nípa ariwo nlá ti ìpè kan, àti nípa ohùn ìdájọ́, àti nípa ohùn àánú ní gbogbo ọjọ́, àti nípa ohùn ògo àti ọlá àti àwọn ọrọ̀ ti ìyè àìnípẹ̀kun, a bá sì gbà yín là pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé kan, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!
26 Ẹ kíyèsíi, ọjọ́ náà ti dé, nígbà tí ago ìbínú ti ìrunú mi kún.
27 Ẹ kíyèsíi, lõtọ́ ni èmi wí fún yín, pé ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín.
28 Nítorínáà, ẹ ṣiṣẹ́, ẹ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà ajarà mi fún ìgbà ìkẹhìn—fún ìpè ìgbà ìkẹhìn ní orí àwọn olùgbé orí ilẹ̀.
29 Nítorí ní àkókò tí ó tọ́ ní ojú mi èmi yíò wá sí orí ilẹ̀ ayé ní ìdájọ́, àwọn ènìyàn mi ni a ó sì rà padà wọn yíò sì jọba pẹ̀lú mi ní orí ìlẹ̀ ayé.
30 Nítorí ẹgbẹ̀rún ọdún nla náà, nípa èyí tí mo ti sọ láti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi, yíò dé.
31 Nitorí a ó gbé Sátánì dè, nígbatí a bá sì tú u sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi òun yíò jọba fún àkókò díẹ̀, àti lẹ́hìn náà ni òpin ayé yíò dé.
32 Àti ẹni tí ó bá sì gbé nínú òdodo ni a ó pa lára dà ní ìṣẹ́jú àáyá, ayé yíò sì kọjá lọ bíi iná.
33 Àti pé àwọn ènìyàn búburú yíò kọjá lọ sínú iná àjóòkú, ìgbẹ̀hìn wọn ẹnikan kò sì mọ̀ ní orí ilẹ̀, tàbí kì yíò mọ̀ ọ́ láé, títí di ìgbà tí wọn yíò wá síwájú mi ní ìdájọ́.
34 Ẹ fetísílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ẹ kíyèsíi, èmi ni Jésù Krístì, Olùgbàlà aráyé. Ẹ fi àwọn nkan wọ̀nyí pamọ́ sí ọkàn yín, kí ẹ sì jẹ́kí ironú ti ayérayé ó sinmi sínú iyè yín.
35 Ẹ fi ara balẹ̀. Ẹ pa gbogbo àwọn òfin mi mọ́. Àní bẹ́ẹ̀ni. Amin.