Orí 40
Krístì mú àjĩnde gbogbo ènìyàn wá—Àwọn olódodo tí ó ti kú lọ sí párádísè nígbàtí àwọn ènìyàn búburú lọ sí òkùnkùn lóde láti dúró de ọjọ́ àjĩnde nwọn—Gbogbo ohun ni a ó ṣe ìdápadà rẹ̀ sí ipò nwọn ní dídára àti pípé nínú Àjĩnde nã. Ní ìwọ̀n ọdún 74 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Nísisìyí ọmọ mi èyí ni ohun tí ó kù tí mo fẹ́ bá ọ sọ; nítorípé mo wòye pé ọkàn rẹ pòrũru nípa àjĩnde òkú.
2 Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, pé kò sí àjĩnde—tàbí, kí èmi kí ó wí báyĩ, ni ọ̀nà míràn, pé ara ti ayé yĩ kò lè gbé ara àìkú wọ̀, ìdíbàjẹ́ yĩ kò lè gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀—àfi lẹ́hìn àkokò ti Krístì bá ti dé.
3 Kíyèsĩ, òun ni ó mú àjĩnde òkú ṣẹ. Ṣùgbọ́n wõ, ọmọ mi, àjĩnde nã kò ì tĩ yá. Nísisìyí, èmi fi ohun ìjìnlẹ̀ kan hàn ọ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ ni ó wà ní ìpamọ́, tí ẹnìkẹ́ni kò mọ̀ nwọ́n àfi Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi fi ohun kan hàn ọ́, èyítí èmi ti ṣe ìwãdí rẹ̀ tọkàn-tọkàn lọ́dọ̀ Ọlọ́run pé kí èmi lè mọ̀—èyí ni nípa ti àjĩnde nã.
4 Kíyèsĩ, àkokò kan wà ti a ti yàn tí gbogbo àwọn tí ó ti kú yíò jáde wa láti ipò-òkú nwọn. Nísisìyí nígbàtí àkokò yìi yíò dé, kò sí ẹnití ó mọ̃; ṣùgbọ́n Ọlọ́run mọ̀ àkokò nã tí a ti yàn.
5 Nísisìyí, bóyá ìgbà kanṣoṣo ni, tàbí ìgbà ẹ̃kẹjì, tàbí ìgbà ẹ̃kẹta, tí àwọn ènìyàn yíò jáde wa láti ipò-òkú, kò já mọ́ nkan; nítorípé Ọlọ́run mọ́ àwọn ohun wọ̀nyí gbogbo; ó sì tọ́ fún mi láti mọ̀ pé ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ ni èyí—pé àkokò kan wà tí a ti yàn tí gbogbo àwọn tí ó ti kú yíò jí dìde kúrò nínú ipò-òkú.
6 Nísisìyí, o di dandan ki àlàfo kan wà lãrín àkókò ikú àti àkókò àjĩnde nã.
7 Àti nísisìyí èmi bẽrè pé kíni yíò ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí ènìyàn lẹ́hìn tí ó bá kú títí di ìgbà tí a ti yàn fún àjĩnde nã?
8 Nísisìyí bóyá ìgbà kanṣoṣo ni a yàn fún ènìyàn láti jí dìde, kò já mọ́ nkankan; nítorípé kĩ ṣe ìgbà kan nã ni gbogbo ènìyàn a máa kú, èyí kò sì já mọ́ nkankan; ohun gbogbo wọ̀nyí rí bí ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti pé àwọn ènìyàn nìkan ni nwọ́n a máa ṣírò ọjọ́ fún lílò ara nwọn.
9 Nítorínã, àkokò kan wà tí a ti yàn fún ènìyàn pé nwọn yíò dìde kúrò nínú ipò-òkú; àti pé ìgbà kan sì wà lãrín àkokò ikú àti àjĩnde nã. Àti nísisìyí, nípa ti ìwọ̀n àkokò yĩ, kíni yíò ṣẹlẹ̀ sí ọkàn ọmọ ènìyàn ni ohun tí èmi ti wãdí tọkàn-tọkàn lọ́wọ́ Ọlọ́run láti mọ̀; èyí sì ni ohun tí èmi mọ̀ nípa rẹ̀.
10 Nígbàtí àkokò nã yíò bá sì dé ti gbogbo ènìyàn yíò jí dìde, nígbànã ni nwọn yíò mọ̀ pé Ọlọ́run mọ́ gbogbo àkókò èyítí a ti yàn fún ọmọ ènìyàn.
11 Nísisìyí, nípa ti ipò ti ọkàn nã yíò wà lẹ́hìn ikú títí di ìgbà àjĩnde—Kíyèsĩ, a ti fi hàn mí nípasẹ̀ ángẹ́lì kan, pé ẹ̀mí ènìyàn gbogbo, ní kété tí ó bá ti fi ara sílẹ̀, bẹ̃ni, ẹ̀mí ènìyàn gbogbo, bí nwọ́n jẹ́ rere tàbí nwọ́n jẹ́ búburú, a ó múu lọ sí ilẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run nã, ẹnití ó fún nwọn ní ìyè.
12 Nígbànã ni yíò sì ṣe, tí a ó gba ẹ̀mí àwọn olódodo sí ipò ayọ̀, èyítí íṣe párádísè, ipò ìsinmi, ipò àlãfíà, níbití nwọn yíò ti sinmi kúrò nínú gbogbo lãlã nwọn, àti kúrò nínú gbogbo àníyàn, àti ìbànújẹ́.
13 Nígbànã ni yíò sì ṣe, tí ẹ̀mí àwọn ènìyàn búburú, bẹ̃ni, àwọn tí nwọ́n burú—nítorí kíyèsĩ, nwọn kò ní ipa tàbí ìpín nínú Ẹ̀mí Olúwa; nítorí kíyèsĩ, nwọ́n yan iṣẹ́ búburú rọ́pò rere; nítorínã ẹ̀mí èṣù wọ inú wọn lọ, ó sì fi àgọ́-ara nwọn ṣe ilé—àwọn yìi ni a ó sì lé jáde sínú òkùnkùn òde; níbẹ̀ ni ẹkún, òun ìpohùnréré ẹkún, òun ìpáhìnkeke yíò wà, èyí sì rí bẹ̃ nítorí àìṣedẽdé nwọn, tí a darí wọn sí ìgbèkùn nípa eṣu.
14 Báyĩ sì ni ipò tí ọkàn àwọn ènìyàn búburú wà, bẹ̃ni, nínú òkùnkùn, àti ipò ìbẹ̀rù, ìfòyà fún ìgbónà ìrunú ìbínú Ọlọ́run lórí nwọn; báyĩ ni nwọn ṣe wà ní ipò yĩ, àti àwọn olódodo pẹ̀lú ní párádísè, títí di àkokò àjĩnde nwọn.
15 Nísisìyí, àwọn kan nbẹ tí nwọ́n ti ní ìmọ̀ pé ipò ayọ̀ àti ipò ìbànújẹ́ ọkàn nã, ṣãjú àjĩnde, jẹ́ àjĩnde àkọ́kọ́. Bẹ̃ni, èmi gbà pé a lè pẽ ní irú àjĩde kan, jíjí dìde ẹ̀mí tàbí ọkàn, àti mímú nwọn bọ́ sínú ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ ti a ti sọ.
16 Sì kíyèsĩ, ẹ̀wẹ̀ a ti sọọ́, pé àjĩnde àkọ́kọ́ wà, àjĩnde gbogbo àwọn tí nwọ́n ti wà tẹ́lẹ̀ rí, tàbí tí nwọn ṣì wà, tàbí tí yíò wà, títí dé ìgbà àjĩnde Krístì kúrò nínú ipò-òkú.
17 Nísisìyí, àwa kò lérò pé àjĩnde àkọ́kọ́ yĩ èyítí à nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ọ̀nà yí, lè jẹ́ àjínde ti àwọn ọkàn àti mímú nwọn wá sí ipò ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́. Ìwọ kò lè rò pé ohun tí ó túmọ̀ sí ni èyí.
18 Kíyèsĩ, mo wí fún ọ, Rárá; ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí ìtúndàpọ̀ ẹ̀mí pẹ̀lú ara, ti àwọn wọnnì láti ìgbà ayé Ádámù títí dé ìgbà àjĩnde Krístì.
19 Nísisìyí i, bóyá ẹ̀mí àti ara àwọn wọnnì tí a ti sọ nípa nwọn yíò tún dàpọ̀ lẹ́sẹ̀kannã, tí àwọn ènìyàn búburú àti ti àwọn olódodo, èmi kò sọ bẹ̃; jẹ́ kí ó tẹ́ ọ lọ́run, pé mo wípé gbogbo nwọn jáde wá; tàbí kí a wípé, àjĩnde nwọn yíò wáyé ṣãjú àjĩnde àwọn tí ó kú lẹ́hìn àjĩnde Krístì.
20 Nísisìyí, ọmọ mi, èmi kò wípé àjĩndé nwọn yíò wáyé ní àkokò ti àjĩnde Krístì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èmi sọọ́ gẹ́gẹ́bí èrò ọkàn mi, pé ọkàn àti ara yíò tún dàpọ̀, ti àwọn olódodo, ní àkokò àjĩnde Krístì, àti ìgòkè re ọ̀run rẹ̀.
21 Ṣùgbọ́n bóyá ní àkokò àjĩnde rẹ̀ ni yíò jẹ́, tàbí lẹ́hìn èyí, èmi kò wí bẹ̃; ṣùgbọ́n eleyĩ ni èmi wí pé àkokò kan yíò wà lẹ́hìn ikú àti àjĩnde ara, àti ipò ẹ̀mí nínú ayọ̀ tàbí ìbànújẹ́ títí di àkokò nã èyítí Ọlọ́run yàn tí àwọn tí ó ti kú yíò jáde wá, tí nwọ́n ó sì tún dàpọ̀, ní ọkàn àti ara, tí a ó sì mú nwọn dúró níwájú Ọlọ́run, tí a ó sì ṣe ìdájọ́ fún nwọn gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn.
22 Bẹ̃ni, èyí ni ó mú ìmúpadàbọ̀sípò àwọn ohun wọnnì tí a ti sọ láti ẹnu àwọn wòlĩ wáyé.
23 A ó dá ọkàn padà sínú ara, àti ara sínú ọkàn; bẹ̃ni, gbogbo ẹ̀yà ara òun orike ara ni a ó mú padà sínú ara tirẹ̀; bẹ̃ni, àní ẹyọ irun orí kan kì yíò sọnù; ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni a ó mú padà bọ̀ sí ipò dídára àti pípé rẹ̀.
24 Àti nísisìyí, ọmọ mi, èyí ni ìmúpadàbọ̀sípò èyítí a ti sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlĩ—
25 Nígbànã ni àwọn olódodo yíò tàn jáde ní ìjọba Ọlọ́run.
26 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ikú búburú yíò dé bá àwọn ènìyàn búburú; nítorítí nwọn yíò kú ní ti ohun tĩ ṣe ti òdodo; nítorípé nwọ́n jẹ́ aláìmọ́, kò sì sí ohun àìmọ́ kan tí ó lè jogún ìjọba Ọlọ́run; ṣùgbọ́n a ó lé nwọn jáde, a ó sì mú nwọn jèrè iṣẹ́ ọwọ́ nwọn, tàbí iṣẹ́ nwọn, èyítí ó ti jẹ́ búburú; nwọn sì nmu gẹ̀dẹ̀gẹ̀dẹ̀ ãgo ìkorò.