Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 52


Orí 52

Ámmórọ́nì rọ́pò Amalikíà gẹ́gẹ́bí ọba àwọn ará Lámánì—Mórónì, Tíákúmì, àti Léhì ṣíwájú àwọn ará Nífáì nínú ogun àjàṣẹ́gun pẹ̀lú àwọn ará Lámánì—Nwọ́n tún ìlú-nlá Múlẹ́kì mú, nwọ́n sì pa Jákọ́bù ará Sórámù. Ní ìwọ̀n ọdún 66 sí 64 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, ẹ kíyèsĩ, nígbàtí àwọn ará Lámánì jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kíni ní oṣù kíni, ẹ kíyèsĩ, nwọ́n rí Amalikíà tí ó ti kú nínú àgọ́ rẹ̀; nwọ́n sì ríi pẹ̀lú pé Tíákúmì ṣetán láti bá nwọn jagun ní ọjọ́ nã.

2 Àti nísisìyí, nígbàtí àwọn ará Lámánì rí èyí ẹ̀rù bà nwọ́n; nwọ́n sì pa èrò nwọn láti kọjá lọ sínú ilẹ̀ tí ó wà lápá àríwá tí nwọ́n sì padà sẹ́hìn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ogun nwọn sínú ìlú-nlá Múlẹ́kì, nwọ́n sì bọ́ sínú ãbò àwọn ìmọdisí nwọn.

3 Ó sì ṣe tí nwọ́n yan arákùnrin Amalikíà lọ́ba sórí àwọn ènìyàn nã; orúkọ rẹ̀ sì ni Ámmórọ́nì, báyĩ ni ọba Ámmórọ́nì tí í ṣe arákùnrin ọba Amalikíà, di yíyàn láti jọba rọ́pò rẹ̀.

4 Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ fọwọ́mú àwọn ìlú-nlá nnì, èyítí nwọ́n ti mú nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀; nítorítí nwọn kò mú ìlú-nlá kankan bíkòbájẹ́wípé nwọ́n ta ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ sílẹ̀.

5 Àti nísisìyí, Tíákúmì ríi pé àwọn ará Lámánì ṣetán láti fọwọ́mú àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti mú, àti àwọn apá ilẹ̀ nã tí nwọ́n ti ní ní ìní; àti pẹ̀lú nígbàtí ó ríi bí nwọ́n ti pọ̀ tó, Tíákúmì wòye pé kò jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí òun gbìdánwò láti kọlũ nwọ́n nínú àwọn ibi ìsádi nwọn.

6 Ṣùgbọ́n ó fi àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pamọ́ yíká kiri, bí ẹnití ó nmúrasílẹ̀ fún ogun; bẹ̃ni, àti nítõtọ́ ó nṣe ìmúrasílẹ̀ láti dãbò bò ara rẹ̀ lọ́wọ́ nwọn, nípa mímọ́ àwọn ògiri yíká tí ó sì npèsè àwọn ibi ìsádi.

7 Ó sì ṣe tí ó nṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun báyĩ títí di ìgbà tí Mórónì fi fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ láti fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ní ágbára.

8 Mórónì sì tún ránṣẹ́ síi pé kí ó dá gbogbo àwọn òndè tí ó ṣubú lọ́wọ́ sĩ dúró; nítorítí bí àwọn ará Lámánì ṣe ti mú àwọn ondè púpọ̀, pé kí ó dá gbogbo àwọn òndè àwọn ará Lámánì dúró fún ìdásílẹ̀ fún àwọn ẹnití àwọn ará Lámánì ti mú.

9 Ó sì tún ránṣẹ́ síi pé kí ó dãbò bò ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ nnì, kí ó sì dãbò bò ọ̀nà tõró nnì èyítí ó wọ inú ilẹ̀ tí ó wà ní ìhà àríwá, kí àwọn ará Lámánì má lè gba ilẹ̀ nã kí nwọ́n sì lágbára láti dà nwọ́n lãmu ní gbogbo ìhà.

10 Mórónì sì ránṣẹ́ síi, pé kí ó ṣe òtítọ́ láti dí agbègbè ilẹ̀ nnì mú, àti pé òun yíò wá gbogbo ọ̀nà láti nà àwọn ará Lámánì tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀, bí agbára òun ti tó, pé bóyá òun lè tún gba àwọn ìlú-nlá nnì tí nwọ́n ti gbà lọ́wọ́ nwọn tẹ́lẹ̀ padà; nípa ọgbọ́n ẹ̀tàn tàbí ní ọ̀nà míràn àti pé òun yíò kọ́ ìmọdisí àti fi agbára fún àwọn ìlú-nlá tí ó wà ní àyíká, àwọn tí nwọn kò tĩ bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.

11 Ó sì tún sọ fún un pé, èmi yíò tọ̃ wa, ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ti kọlũ wá ní ìhà ibi ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní apá ibi òkun apá ìwọ̀-õrùn; sì kíyèsĩ, mo lọ láti kọlũ nwọ́n, nítoriã ni èmi kò ṣe lè tọ̃ wa.

12 Nísisìyí, ọba nã (Ámmórọ́nì) ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó sì ti wí fún ayaba nípa ikú arákùnrin rẹ̀, ó sì ti kó àwọn ọmọ ogun púpọ̀ jọ, tí nwọ́n sì jáde lọ, láti dojúkọ àwọn ará Nífáì ní ibi ãlà ilẹ̀ nã tí ó wà ní ẹgbẹ́ òkun apá ìwọ oòrùn.

13 Báyĩ ni ó sì nlépa láti dãmú àwọn ará Nífáì, àti láti fa nínú àwọn ọmọ ogun nwọn sínú apá ilẹ̀ nnì, bí ó tilẹ̀jẹ́pé ó ti pàṣẹ pé kí àwọn tí ó fi sẹ́hìn ó mú àwọn ìlú-nlá nã ní ìní, pé kí àwọn nã ó dãmú àwọn ará Nífáì tí nwọ́n wà ní ibi ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní ẹgbẹ́ òkun apá ilà oòrùn, àti pé kí nwọ́n mú àwọn ilẹ̀ nwọn ní ìní bí agbára nwọn bá ti tó, gẹ́gẹ́bí agbára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn.

14 Báyĩ sì ni àwọn ará Nífáì wà nínú ipò ewu ní òpin ọdún kẹrìndínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

15 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó sì ṣe ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, ni Tíákúmì, nípa àṣẹ Mórónì—ẹnití ó ti kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun jọ láti dãbò bò àwọn ãlà ilẹ̀ tí ó wà ní apá gúsù àti apá ìwọ oòrùn ilẹ̀ nã, tí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá lọ sí apá ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, láti lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún Tíákúmì pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti gba àwọn ìlú-nlá tí nwọ́n ti pàdánù tẹ́lẹ̀—

16 Ó sì ṣe tí Tíákúmì ti gba àṣẹ láti lọ kọlũ ìlú-nlá Múlẹ́kì, kí ó sì gbã padà bí ó bá ṣeéṣe.

17 Ó sì ṣe tí Tíákúmì ṣe ìmúrasílẹ̀ láti lọ kọlũ ìlú-nlá Múlẹ́kì, kí ó sì kọjá lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti kọlu àwọn ará Lámánì; ṣùgbọ́n ó ríi pé kò ṣeéṣe fún òun láti borí nwọn nígbàtí nwọ́n wà nínú àwọn ibi ìsádi nwọn; nítorínã ó pa èrò wọ̀nyí tì, ó sì tún padà lọ sínú ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀, láti dúró de bíbọ̀wá Mórónì, láti lè gba agbára kún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.

18 Ó sì ṣe tí Mórónì dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, ní òpin ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

19 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kéjìdínlọ́gbọ̀n ni Mórónì àti Tíákúmì àti púpọ̀ nínú àwọn olórí ológun sì ní àjọròpọ̀ nípa ti ogun—nípa ohun tí nwọn yíò ṣe láti mú àwọn ará Lámánì jáde wá bá nwọn jagun; tàbí pé kí nwọ́n wá ọ̀nà láti tàn nwọ́n jáde kúrò nínú àwọn ibi ìsádi nwọn, kí nwọ́n lè borí nwọ́n kí nwọn sì gba ìlú-nlá Múlẹ́kì padà.

20 Ó sì ṣe tí nwọ́n rán àwọn oníṣẹ́ sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, tí ó ndãbò bò ìlú-nlá Múlẹ́kì, sí olórí nwọn, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Jákọ́bù, pé nwọn fẹ́ kí ó jáde wá pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti pàdé nwọn lórí ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà lãrín àwọn ìlú nlá méjẽjì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Jákọ́bù, ẹnití í ṣe ará Sórámù, kọ̀ láti tọ̀ nwọ́n wá pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lórí ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ nã.

21 Ó sì ṣe tí Mórónì nítorí kò ní ìrètí láti pàdé nwọn lórí ilẹ̀ tí ó dọ́gba, nítorínã, ó gbèrò láti tan àwọn ará Lámánì nã jáde nínú àwọn ibi ìsádi nwọn.

22 Nítorínã, ó mú kí Tíákúmì kó àwọn ọmọ ogun díẹ̀ kí nwọn sì kọjá lọ sí ẹ̀gbẹ́ bèbè òkun; Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ní àṣálẹ́, sì kọjá lọ sínú aginjù, ní apá ìwọ̀-oòrùn ìlú-nlá Múlẹ́kì; báyĩ nã, ní ọjọ́ kejì, nígbàtí àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ará Lámánì rí Tíákúmì, nwọ́n sá nwọ́n sì sọọ́ fún Jákọ́bù, olórí nwọn.

23 Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì kọjá lọ ní ìkọlu Tíákúmì, tí nwọ́n rò wípé nípa pípọ̀ nwọn àwọn yíò borí Tíákúmì nítorípé nwọn kò pọ̀. Bí Tíákúmì sì ti rí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì tí nwọ́n nbọ̀wá dojúkọ òun ni ó bẹ̀rẹ̀sí sá padà lọ sí ẹ̀gbẹ́ bèbè òkun, sí apá àríwá.

24 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn arà Lámánì ríi pé ó nsá padà, nwọ́n ní ìgboyà nwọ́n sì sá tẹ̀lé nwọn pẹ̀lú agbára. Bí Tíákúmì sì ṣe ndarí àwọn ará Lámanì nã lọ tí nwọn nsá tẹ̀lée lásán, ẹ kíyèsĩ Mórónì pàṣẹ pé kí apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kọjá lọ sínú ìlú-nlá nã, kí nwọn ó sì múu ní ìní.

25 Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe, tí nwọ́n sì pa gbogbo àwọn tí nwọ́n fi sílẹ̀ láti dãbò bò ìlú-nlá nã, bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí nwọn kọ̀ láti jọ̀wọ́ àwọn ohun-ìjà ogun nwọn.

26 Báyĩ sì ni Mórónì ṣe gba ìlú-nlá Múlẹ́kì pẹ̀lú apá kan nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó sì kọjá lọ pẹ̀lú àwọn tí ó kù láti dojúkọ àwọn ará Lámánì nígbàtí nwọ́n padà bọ̀wá ní lílé tí nwọ́n lé Tíákúmì lọ.

27 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì lé Tíákúmì títí nwọ́n fi dé ẹ̀gbẹ́ ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀, tí Léhì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun kékeré kan tí nwọ́n ti fi sílẹ̀ láti dãbò bò ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀, sì pàdé nwọn.

28 Àti nísisìyí sì kíyèsĩ, nígbàtí àwọn olórí ológun àwọn ará Lámánì rí Léhì pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí nwọn nbọ̀ láti dojúkọ nwọ́n, nwọ́n sá nínú ìdàmú tí ó pọ̀, fún ìbẹ̀rù pé nwọn kò ní lè mú ìlú-nlá Múlẹ́kì kí Léhì tó lé nwọn bá; nítorítí ó ti rẹ̀ nwọ́n nítorí ìrìnàjò nwọn, tí àwọn ọmọ ogun Léhì ṣì lágbára.

29 Nísisìyí àwọn ará Lámánì kò mọ̀ pé Mórónì ti dé ẹ̀hìn nwọn pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀; tí ó sì jẹ́ wípé ẹ̀rù Léhì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nìkan ni ó nbá nwọ́n.

30 Nísisìyí Léhì kò ní ìfẹ́ láti lé nwọn bá títí nwọn ó fi pàdé Mórónì àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.

31 Ó sì ṣe pé kí àwọn ará Lámánì tó sá padà tán ni àwọn ará Nífáì yí nwọn ká, àwọn ọmọ ogun Mórónì ní apá kan, àti àwọn ọmọ ogun Léhì ní apá kejì, tí gbogbo nwọn sì wà nínú àkọ̀tun agbára tí ó péye; ṣùgbọ́n àwọn ará Lámánì ti di alãrẹ̀ nítorí ti ìrìn àjò nwọn.

32 Mórónì sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti kọlũ nwọ́n títí nwọn ó fi kó àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀.

33 Ó sì ṣe tí Jákọ́bù, ẹnití í ṣe olórí nwọn tí í ṣe ará Sórámù, tí ó sì tún ní ẹ̀mí akíkanjú, tí ó ṣãjú àwọn ará Lámánì lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrunú sí Mórónì.

34 Nítorípé Mórónì sì wà lójú ọ̀nà nwọn, nítorínã ni Jákọ́bù ṣe pinnu láti pa òun pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí ó sì la ãrín kọjá lọ si ìlú-nlá Múlẹ́kì. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Mórónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lágbára jù nwọ́n lọ; nítorínã nwọn kò fà sẹ́hìn níwájú àwọn ará Lámánì.

35 Ó sì ṣe tí nwọ́n jà ní apá méjẽjì pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìrunú; tí a pa púpọ̀ ní apá méjẽjì; bẹ̃ni, tí Mórónì sì fara gbọgbẹ́ tí a sì pa Jákọ́bù.

36 Léhì sì tẹ̀ síwájú látẹ̀hìn pẹ̀lú ìrunú púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ alágbára, tí àwọn ará Lámánì tí ó wà lẹ́hìn sì kó ohun ìjà ogun nwọn lélẹ̀; tí àwọn tí ó kù nínú nwọn, nítorítí ìdãmú púpọ̀ bá nwọn, kò sì mọ́ ibití nwọn yíò lọ tàbí ibití nwọn yíò kọlù.

37 Nísisìyí nígbàtí Mórónì rí ìdãmú nwọn, ó wí fún nwọn pé: Bí ẹ̀yin yíò bá kó ohun ìjà ogun nyín wá kí ẹ sì jọ̀wọ́ nwọn sílẹ̀, ẹ kíyèsĩ àwa yíò dáwọ́dúró nínú ìtàjẹ̀ nyín sílẹ̀.

38 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àwọn olórí ọmọ ogun nwọn, gbogbo àwọn tí a kò pa, jáde wá nwọ́n sì kó àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ Mórónì, tí nwọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun nwọn láti ṣe bákannã.

39 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn tí kò ṣe báyĩ pọ̀; àwọn tí kò sì kó idà nwọn lélẹ̀ ni a mú tí a sì dè, a sì gba àwọn ohun ìjà ogun nwọn lọ́wọ́ nwọn, a sì mú kí nwọn kọjá lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn sínú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀.

40 Àti nísisìyí iye àwọn tí nwọn kó lẹ́rú pọ̀ púpọ̀ ju iye àwọn tí a pa, bẹ̃ni, ju iye àwọn tí a ti pa ní apá méjẽjì.