Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 45


Ìṣe àwọn ènìyàn Nífáì, àti ogun àti ìyapa nwọn, ní ìgbà ayé Hẹ́lámánì, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ ti Hẹ́lámánì, èyítí ó ṣe ní ìgbà ayé rẹ̀.

Èyítí a kọ sí àwọn orí 45 títí ó fi dé 62 ní àkópọ̀.

Orí 45

Hẹ́lámánì gba àwọn ọ̀rọ̀ Álmà gbọ́—Álmà ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun àwọn ará Nífáì—Ó súre fún, ó sì fi ilẹ̀ nã bú—Ó lè jẹ́ pé Ẹ̀mí ni ó mú Álmà lọ sí ókè ọ̀run, àní bí ti Mósè—Ìyapa gbilẹ̀ nínú ìjọ-onígbàgbọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 73 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì yọ̀ púpọ̀púpọ̀, nítorípé Olúwa tún ti gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn; nítorínã nwọn fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n sì gba ãwẹ̀ púpọ̀, nwọ́n sì gbàdúrà púpọ̀, nwọ́n sì sin Ọlọ́run pẹ̀lú ayọ̀ nlá tí ó pọ̀ púpọ̀.

2 Ó sì ṣe ní ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Álmà tọ ọmọ rẹ̀ Hẹ́lámánì wá, ó sì wí fún un: Ìwọ ha gba àwọn ọ̀rọ̀ èyítí èmi bá ọ sọ gbọ́ nípa àwọn àkọsílẹ̀ nnì èyítí a ti pamọ́ bí?

3 Hẹ́lámánì sì wí fún un: Bẹ̃ni, èmi gbàgbọ́.

4 Álmà sì tún wípé: Ìwọ ha gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ẹnití nbọ̀wá bí?

5 Ó sì wípé: Bẹ̃ni, èmi gba gbogbo ọ̀rọ̀ èyítí ìwọ sọ gbọ́.

6 Álmà sì tún wí fún un: Njẹ́ ìwọ yíò pa àwọn òfin mi mọ́ bí?

7 Òun sì wípé: Bẹ̃ni, èmi yíò pa àwọn òfin rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.

8 Nígbànã ni Álmà wí fún un: Ìbùkún ni fún ọ; Olúwa yíò sì ṣe rere fún ọ ní ilẹ̀ yí.

9 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, mo ní ohun kan tí èmi yíò ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún ọ; ṣùgbọ́n ohun nã tí èmi yíò ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún ọ ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọọ́ di mímọ̀; bẹ̃ni, ohun nã tí èmi yíò ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún ọ kò gbọ́dọ̀ di mímọ̀, àní títí di ìgbà tí ìsọtẹ́lẹ̀ nã yíò di mímú ṣẹ; nítorínã kọ àwọn ọ̀rọ̀ èyítí èmi yíò sọ sílẹ̀.

10 Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ nã: Kíyèsĩ, mo wòye pé àwọn ènìyàn yĩ pãpã, àwọn ará Nífáì, gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí ìfihàn èyítí nbẹ nínú mi, ní irínwó ọdún sí ìgbà tí Jésù Krístì yíò fi ara rẹ̀ hàn nwọ́n, yíò rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́.

11 Bẹ̃ni, nígbànã ni nwọn yíò sì rí ogun àti àjàkálẹ̀ àrùn, bẹ̃ni, ìyàn àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, àní títí àwọn ènìyàn Nífáì yíò di aláìsí—

12 Bẹ̃ní, èyí yíò sì rí bẹ̃ nítorítí nwọn ó rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ nwọn ó sì ṣubú sínú àwọn iṣẹ́ òkùnkùn, àti ìfẹ́kúfẹ, àti onírurú irú àìṣedẽdé gbogbo; bẹ̃ni, mo wí fún ọ, pé nítorítí nwọn yíò ṣẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀ ńlá àti ìmọ̀, bẹ̃ni, mo wí fún ọ, pé láti ìgbà nã lọ, àní ìran kẹrin kò ní kọjá lọ tí àìṣedẽdé nla yĩ yíò fi dé.

13 Nígbàtí ọjọ́ nlá nã yíò sì dé, kíyèsĩ, àkókò nã dé kánkán tí àwọn tí nbẹ nísisìyí, tàbí irú-ọmọ àwọn tí a kà mọ́ àwọn ènìyàn Nífáì lọ́wọ́lọ́wọ́ báyĩ, kò ní jẹ́ kíkà mọ́ àwọn ènìyàn Nífáì mọ́.

14 Ṣùgbọ́n ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣẹ́kù, tí a kò sì parun ní ọjọ́ nlá nnì èyítí ó ní ẹ̀rù, ni a ó kà mọ́ àwọn ará Lámánì, nwọn ó sì dàbí nwọn, gbogbo nwọn, àfi àwọn díẹ̀ tí a ó pè ní ọmọ-ẹ̀hìn Olúwa; àwọn sì ni àwọn ará Lámánì yíò lé àní títí nwọn yíò fi di aláìsí. Àti nísisìyí nítorí àìṣedẽdé, ìsọtẹ́lẹ̀ yĩ yíò sì di mímúṣẹ.

15 Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí Álmà ti sọ àwọn ohun wọ̀nyí fún Hẹ́lámánì, ni ó súre fún un, àti fún àwọn ọmọ rẹ̀ yókù; ó sì súre fún ayé nítorí ti àwọn olódodo.

16 Ó sì wípé: Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí—Ìfibú ni ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, ilẹ̀ yìi, sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ède, àti ènìyàn, sí ìparun, tí nwọn nṣe búburú, nígbàtí nwọ́n bá gbó tán; bí èmi sì ti wí bẹ̃ ni yíò rí; nítorítí èyí ni ìfibú àti ìbùkún Ọlọ́run lórí ilẹ̀ nã, nítorítí Olúwa kò lè bojúwò ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú rárá bí ó ti lè wù kí ó mọ.

17 Àti nísisìyí, nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó sùre fún ìjọ-onígbàgbọ́ nã, bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí nwọn yíò dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ láti ìgbà nã lọ.

18 Nígbàtí Álmà sì ṣe eleyĩ tán ó jáde kúrò nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, bí èyítí yíò lọ sínú ilẹ̀ Mẹ́lẹ́kì. O sì ṣe tí a kò gbọ́ nípa rẹ̀ mọ́; nípa ti ikú tàbí sísin rẹ̀ a kò mọ̀ nípa rẹ̀.

19 Kíyèsĩ, àwa mọ́ eleyĩ, pé olódodo ènìyàn ni í ṣe; ìhín nã sì tàn ká lãrín gbogbo àwọn ènìyàn ìjọ-onígbàgbọ́ pé Ẹ̀mí ni ó mú u lọ sókè ọ̀run, tàbí pé ọwọ́ Olúwa ni ó gbée sin, àní bí ti Mósè. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, àwọn ìwé mímọ́ sọ pé Olúwa gba Mósè sọ́dọ̀ ara rẹ̀; àwa sì ropé ó ti gba Álmà pẹ̀lú nínú ẹ̀mí, sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀; nítorínã, fún ìdí èyí, a kò mọ́ ohunkóhun nípa ikú àti sísìn rẹ̀.

20 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọkàndínlógún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, tí Hẹ́lámánì kọjá lọ sí ãrín àwọn ènìyàn nã láti kéde ọ̀rọ̀ nã fún nwọn.

21 Nítorí ẹ kíyèsĩ, nítorí ìjà-ogun nwọn pẹ̀lú àwọn ará Lámánì àti àwọn ìyapa kékèké tí ó pọ̀ àti àwọn ìrúkèrúdò tí ó ti wà lãrín àwọn ènìyàn nã, ó jẹ́ ohun tí ó tọ́ pé kí a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín nwọn, bẹ̃ni, àti pé kí a ṣe ìlànà nínú ìjọ nã.

22 Nítorínã, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ láti tún dá ìjọ onígbàgbọ́ nã sílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, nínú gbogbo àwọn ìlú nlá jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã èyítí àwọn ènìyàn Nífáì ti ṣe ìjogún nwọn. O sì ṣe tí nwọn sì yan àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, lé gbogbo àwọn ìjọ nã lórí.

23 Àti nísisìyí ni ó sì ṣe lẹ́hìn tí Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti yan àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni lé orí àwọn ìjọ nã ìyapa bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn, tí nwọn kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ mọ́;

24 Ṣùgbọ́n nwọ́n di onigbéraga, nítorítí nwọ́n ṣe ìgbéraga nínú ọkàn nwọn, nítorí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ nwọn; nítorínã nwọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ lójú ara nwọn, tí nwọn kò sì ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ nwọn mọ́, láti máa wà ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run.