Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 60


Orí 60

Mórónì fi ẹjọ́ sun Pahoránì nípa ti àìfiyèsí ìjọba lórí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—Olúwa jẹ́ kí nwọ́n pa àwọn olódodo—Àwọn ará Nífáì níláti lo gbogbo ipá àti ìní nwọn láti gba ara nwọn lọ́wọ́ ọ̀tá nwọn—Mórónì kìlọ̀ pé òun yíò bá ìjọba nã jà àfi bí nwọ́n bá fi ìrànlọ́wọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun òun. Ní ìwọ̀n ọdún 62 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí ó tún kọ̀wé sí olórí ilẹ̀ nã, ẹnití íṣe Pahoránì, àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ó kọ, wípé: Kíyèsĩ, mo kọ ìwé mi sí Pahoránì, tí ó wà nínú ìlú-nlá Sarahẹ́múlà, ẹnití í ṣe adájọ́ àgbà àti olórí lórí ilẹ̀ nã, àti pẹ̀lú sí gbogbo àwọn tí àwọn ènìyàn yí yàn láti darí àti láti ṣe àkóso ọ̀rọ̀ nípa ti ogun yĩ.

2 Nítorí kíyèsĩ, èmi ní ohun kan láti bá nwọn sọ èyítí í ṣe ìbáwí; nítorí kíyèsĩ, ẹ̀yin fúnra nyín mọ̀ wípé a ti yàn yín láti kó ọmọ ogun jọ, kí ẹ sì dì nwọ́n ní ìhámọ́ra pẹ̀lú idà àti pẹ̀lú doje-ija àti onírũrú ohun ìjà-ogun lóríṣiríṣi, kí ẹ sì rán nwọn jáde lọ kọlu àwọn ará Lámánì, níbikíbi tí nwọn lè gbà jáde wá sínú ilẹ̀ wa.

3 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, mo wí fun nyín pé èmi fúnra mi, àti àwọn ọmọ ogun mi pẹ̀lú, àti Hẹ́lámánì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú, ti jìyà lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, àní ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀, àti onírũrú ìpọ́njú lóríṣiríṣi.

4 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, njẹ́ bí ó bá jẹ́ wípé èyí nìkan ni ìyà tí ó jẹ wá àwa kì bá ti kùn tàbí kí a ráhùn.

5 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìpakúpa nã pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín àwọn ènìyàn wa; bẹ̃ni, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ti subú nípa ti idà, èyítí kì bá tí rí bẹ̃ bí ẹ̀yin bá ti fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa ní agbára àti irànlọ́wọ́ tí ó tó. Bẹ̃ni, ìpatì nyin sí wa pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

6 Àti nísisìyí kíyèsĩ, àwa nífẹ́ láti mọ́ ohun tí ó fa irú ìpatì nlá yĩ; bẹ̃ni, àwa nífẹ́ láti mọ́ ohun tí ó fa irú ìwà àìnírònú nyín yĩ.

7 Njẹ́ ẹ̀yin lérò pé ẹ̀yin lè jókó sí órí ìtẹ́ nyín ní ipò àìnírònú aláìníyè yĩ, kí àwọn ọ̀tá nyín ó sì máa tan iṣẹ́ ìpànìyàn kákiri lãrín nyín? Bẹ̃ni, bí nwọ́n ṣe npa ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nínú àwọn arákùnrin nyín—

8 Bẹ̃ni, àní àwọn tí nwọ́n gbẹ́kẹ̀lé nyín fún ãbò, bẹ̃ni, tí nwọ́n fi nyín sí ípò tí ó yẹ fún nyín láti ràn nwọ́n lọ́wọ́, bẹ̃ni, ẹ̀yin ìbá ti fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ránṣẹ́ sí nwọn, láti fún nwọn ni ágbára, ẹ̀yin ìbá sì ti gba ẹgbẹ̃gbẹ̀rún nwọn lọ́wọ́ ìṣubú nipasẹ idà.

9 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ èyí kì i ṣe gbogbo rẹ̀—ẹ̀yin fà ọwọ́ ìpèsè oúnjẹ sẹ́hìn fún nwọn, tóbẹ̃ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ jà tí nwọ́n sì ṣẹ̀jẹ̀ kú nítorí ti ìfẹ́ nlá tí nwọ́n ní fún àlãfíà àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, eleyĩ ni nwọ́n sì ṣe nígbàtí nwọ́n fẹ́rẹ̀ kú fún ebi, nítorí ìpatì nlá nyín sí nwọn.

10 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́—nítorípé ó yẹ kí ẹ̀yin ó jẹ́ àyànfẹ́; bẹ̃ni, ó sì yẹ kí ẹ̀yin ti ta ara nyín jí gírí fún àlãfíà àti òmìnira àwọn ènìyàn yĩ; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ̀yin ti pa nwọ́n tì tóbẹ̃ tí ẹ̀jẹ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún yíò wá sórí nyín fún ẹ̀san; bẹ̃ni, nítorítí gbogbo igbe nwọn àti gbogbo ìyà nwọn jẹ́ mímọ̀ sí Ọlọ́run—

11 Kíyèsĩ, ẹ̀yin ha lérò wípé ẹ lè joko lórí ìtẹ́ nyín bí, àti pé nítorí dídára Ọlọ́run tí ó pọ̀ púpọ̀ ẹ̀yin kò ní ṣe ohun kankan òun yíò sì gbà nyín? Ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin rõ, ẹ rõ lásán ni.

12 Ẹ̀yin ha lérò wípé, pípa ti á pa púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nyín nítorí ìwà búburú nwọn ni bí? Èmi wí fún nyín, bí ẹ̀yin bá lérò báyĩ ẹ̀yin rõ lórí asán ni; nítorítí mo wí fún nyín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ti ṣubú nípa idà; àti pé kíyèsĩ sí ìdálẹ́bi nyín ni;

13 Nítorítí Olúwa jẹ́ kí a pa olódodo kí àìṣègbè àti ìdájọ́ rẹ̀ lé wá sórí àwọn ènìyàn búburú; nítorínã kí ẹ̀yin ó máṣe ró wípé àwọn olódodo yíò ṣègbé nítorítí a ti pa nwọn; ṣùgbọ́n kíyèsĩ, nwọ́n wọ inú ìsinmi Olúwa Ọlọ́run nwọn.

14 Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún nyín, mo ní ìbẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run yíò wá sí órí àwọn ènìyàn yĩ, nítorí ìwà ìmẹ́lẹ́ nwọn, bẹ̃ni, àní ìwà ìmẹ́lẹ́ ìjọba wa, àti ìpatì nlá nwọn sí àwọn arákùnrin nwọn, bẹ̃ni, sí àwọn tí nwọ́n ti pa.

15 Nítorí bíkòbáṣe ti ìwà búburú èyítí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí wa, àwa ìbá ti dojúkọ àwọn ọ̀tá wa tí nwọn kò sì ní lè borí wa.

16 Bẹ̃ni, bíkòbáṣe nítorí ogun tí ó bẹ́ sílẹ̀ lãrín wa; bẹ̃ni, bí kò bá ṣe nítorí àwọn afọbajẹ wọ̀nyí, tí nwọ́n fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀ lãrín wa; bẹ̃ni ní àkokò tí àwa nbá ara wa jà, bí àwa bá ti fọwọ́sowọ́pọ̀ nínú agbára bí àwa ti ṣe tẹ́lẹ̀; bẹ̃ni, bí kò bá ṣe nítorí ti ìfẹ́ fún agbára àti àṣẹ èyítí àwọn afọbajẹ wọ̀nnì ní lórí wa; bí nwọ́n bá ti ṣe òtítọ́ sí ìjà-òmìnira nã, tí nwọ́n sì ti darapọ̀ mọ́ wa, tí nwọ́n sì jáde lọ dojúkọ àwọn ọ̀tá wa, dípò kí nwọ́n gbé idà nwọn sí wa, èyítí ó jẹ́ ohun tí ó fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lãrín ara wa; bẹ̃ni, bí àwa bá ti jáde lọ láti dojúkọ nwọ́n nínú agbára Olúwa, àwa ìbá ti tú àwọn ọ̀tá wa ká, nítorípé èyí ìbá ti rí bẹ̃, ní ìbámu pẹ̀lú ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

17 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, nísisìyí àwọn ará Lámánì ngbógun tì wá, nwọ́n sì ngba àwọn ilẹ̀ wa, nwọ́n sì npa àwọn ènìyàn wa pẹ̀lú idà, bẹ̃ni, àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa, nwọ́n sì nkó nwọn lọ ní ìgbẹ̀kùn, tí nwọ́n sì njẹ́ kí onírũrú ìyà jẹ nwọ́n, èyí sì rí bẹ̃ nítorí ti ìwà búburú àwọn tí nwá agbára àti àṣẹ, bẹ̃ni, àní àwọn afọbajẹ wọnnì.

18 Ṣùgbọ́n èmi yíò ha ṣe sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí ohun yĩ? Nítorítí àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe pé ẹ̀yin tìkara yín nwá àṣẹ́. Àwa kò mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe pé ọlọ̀tẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú í ṣe sí ìlú nyín.

19 Tàbí ẹ̀yin ha ti pawá tì nítorípé ẹ̀yin wà ní ãrin inú ilẹ̀ orílẹ̀-èdè wa tí ãbò sì yí nyín ká, ni ẹ̀yin kò ṣe mú kí a fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí wa, àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun pẹ̀lú láti lè fi agbára kún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa?

20 Ẹ̀yin ha ti gbàgbé àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run nyín bí? Bẹ̃ni, ẹ̀yin ha ti gbàgbé ìkólọ sí ìgbèkún àwọn bàbá wa bí? Ẹ̀yin ha ti gbàgbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbà tí Ọlọ́run ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa bí?

21 Tabí ẹ̀yin ha lérò wípé Olúwa yíò tún gbà wá, bí àwa ti joko lórí ìtẹ́ wa tí àwa kò sì mú ohun tí Olúwa ti pèsè fún wa lò bí?

22 Bẹ̃ni, njẹ́ ẹ̀yin yíò ha jókó láìṣiṣẹ́ tí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn wọnnì sì yí nyín ká, bẹ̃ni, àti ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mẹwa, àwọn wọnnì tí nwọ́n sì joko láìṣiṣẹ́ pẹ̀lú, nígbàtí àwọn ẹgbẹ̃gbẹ̀rún wà kákiri ní agbègbè ilẹ̀ nã tí nwọ́n ṣubú nípa idà, bẹ̃ni, tí nwọ́n ti fi ara gba ọgbẹ́ tí nwọ́n sì nṣẹ́jẹ̀?

23 Ẹ̀yin ha lérò wípé Ọlọ́run yíò wò nyín pé ẹ̀yin wà láìlẹ́bi nígbàtí ẹ̀yin joko jẹ́jẹ́ tí ẹ sì nwo àwọn ohun wọ̀nyí? Kíyèsĩ mo wí fún nyín, rárá. Nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí pé Ọlọ́run ti wípé a ó kọ́kọ́ wẹ àgọ́ inú ara mọ́, lẹ́hìnnã sì ni a ó wẹ àgọ́ ara òde mọ́ pẹ̀lú.

24 Àti nísisìyí, àfi bí ẹ̀yin bá ronúpìwàdà ní ti èyítí ẹ̀yin ti ṣe, kí ẹ sì dìde sí iṣẹ́, kí ẹ sì fi oúnjẹ àti àwọn ọmọ ogun ránṣẹ́ sí wa, àti sí Hẹ́lámánì pẹ̀lú, kí ó lè dãbò bò àwọn apá ilẹ̀ wa nã tí ó ti gbà padà, àti pé kí àwa nã ó lè gba àwọn ohun-ìní wa tí ó kù ní àwọn apá ilẹ̀ yĩ padà, ẹ kíyèsĩ ó yẹ kí àwa ó máṣe bá àwọn ará Lámánì jà mọ́ títí àwa ó fi kọ́kọ́ wẹ àgọ́ inú ara wa mọ́, bẹ̃ni, àní àwọn olórí àgbà ìjọba wa.

25 Àti pé àfi bí ẹ̀yin bá fifún mi gẹ́gẹ́bí èmi ti bẽrè nínú ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi ẹ̀mí òmìníra ní tõtọ́ hàn mi ní gbangba, kí ẹ sì tiraka láti fi agbára kún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa, kí ẹ sì fún nwọn ní oúnjẹ fún àtìlẹhìn nwọn, ẹ kíyèsĩ èmi yíò fi apá kan nínú àwọn ènìyàn olómìnira mi sílẹ̀ láti dãbò bò ilẹ̀ wa tí ó wà ní apá yĩ, èmi yíò sì fi agbára àti ìbùkún Ọlọ́run sílẹ̀ sórí nwọn, kí agbára míràn máṣe lè bá nwọn jà—

26 Èyí sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó tóbi, àti sũrù nwọn nínú ìpọ́njú—

27 Èmi yíò sì tọ̀ nyín wá, bí ẹnìkẹ́ni bá sì wà lãrín nyín tí ó ní ìfẹ́ fún òmìnira, bẹ̃ni, bí a bá rí ìfẹ́ fún òmìnira bí ó ti wulẹ̀ kí ó kéré tó, kíyèsĩ èmi yíò dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ lãrín nyín, àní títí àwọn tí ó ní ìfẹ́ láti gba agbára àti àṣẹ yíò fi di aláìsí.

28 Bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ èmi kò bẹ̀rù agbára nyín tàbí àṣẹ nyín, ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi ni ẹnití èmi bẹ̀rù rẹ̀; gẹ́gẹ́bí ìpaláṣẹ rẹ̀ ni èmi sì fi gbé idà mi láti dãbò bò ipa ọ̀nà ìfẹ́ orílẹ̀-èdè mi, àti nítorí àìṣedẽdé nyín ni àwa ṣe rí àdánù tí ó pọ̀ báyĩ.

29 Ẹ kíyèsĩ àsìkò ti tó, bẹ̃ni, àkokò nã ti dé tán, pé àfi bí ẹ̀yin bá ta ara nyín jí fún ìdãbò bò orílẹ̀-èdè nyín àti àwọn ọmọ nyín, idà yíò wà ní gbígbé sókè lórí nyín; bẹ̃ni, yíò sì kọlũ nyín tí yíò sì bẹ̀ nyín wò àní sí ìparun nyín pátápátá.

30 Kíyèsĩ, èmi ndúró de ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ nyín; àti pé, àfi bí ẹ̀yin bá ràn wá lọ́wọ́, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò tọ̀ nyín wá, àní nínú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, èmi yíò sì kọlũ nyín pẹ̀lú ida, tó bẹ̃ tí ẹ̀yin kò lè ní agbára mọ́ láti dá itẹsiwaju àwọn ènìyàn yĩ duro nínú ija fun ipa ominira wa.

31 Nítorí ẹ kíyèsĩ, Olúwa kò ní jẹ́ kí ẹ̀yin wà lãyè kí ẹ sì di alágbára nínú àìṣedẽdé nyín láti lè pa àwọn ènìyàn rẹ̀ tí í ṣe olódodo run.

32 Kíyèsĩ, ẹ̀yin ha lérò wípé Olúwa yíò dá nyín sí tí yíò sì ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ará Lámánì, nígbàtí ó ṣe wípé àṣà àwọn bàbá nwọn ni ó fa ìkorira tí nwọ́n ní, bẹ̃ni, tí àwọn tí nwọ́n fẹ́ yapa kúrò lára wa sì tún sọọ́ di ìlọ́po síi, nígbàtí ìwà búburú nyín sì wà nítorí ìfẹ́ nyín fún ògo àti ohun asán ayé yĩ bí?

33 Ẹ̀yin mọ̀ wípé ẹ̀yin rékọjá sí òfin Ọlọ́run, ẹ̀yin sì mọ̀ wípé ẹ̀yin ntẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ nyín. Kíyèsĩ, Olúwa wí fún mi pé: Bí àwọn tí ẹ̀yin ti yàn gẹ́gẹ́bí aláṣẹ nyín kò bá ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àìṣedẽdé nwọn, ìwọ yíò lọ kọlũ nwọ́n ní ìjà.

34 Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi, Mórónì, ó di dandan fún mi nípa májẹ̀mú tí èmi ti dá láti pa òfin Ọlọ́run mi mọ́; nítorínã ni èmi ṣe fẹ́ kí ẹ̀yin ó ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ sì ránṣẹ́ sí mi ní kánkán pẹ̀lú àwọn ìpèsè oúnjẹ àti àwọn ọmọ ogun nyín, àti sí Hẹ́lámánì.

35 Sì kíyèsĩ, bí ẹ̀yin kò bá ṣe èyí èmi nbọ̀ wá bá nyín kánkán; nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwa ó kú lọ́wọ́ ebi; nítorínã yíò fifún wa nínú oúnjẹ nyín, àní bí ó tilẹ̀jẹ́wípé nípa idà. Nísisìyí kí ẹ ríi pé ẹ̀yin mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ.

36 Kíyèsĩ, èmi ni Mórónì, tí í ṣe balógun àgbà nyín. Èmi kò lépa agbára, bíkòṣe láti wóo lulẹ̀. Èmi kò wá ọlá ti inú ayé yĩ, ṣùgbọ́n fún ògo Ọlọ́run mi, àti ominira àti ìwà àlãfíà orílẹ̀-èdè mi. Báyĩ sì ni èmi pará ọ̀rọ̀ mi.