Orí 51
Àwọn-afọbajẹ nlépa láti yí òfin padà kí nwọ́n sì fi ọba jẹ—Pahoránì àti àwọn-ẹni-òmìnira rí àtìlẹhìn gbà pẹ̀lú ohùn àwọn ènìyàn nã—Mórónì fi ipá mú afọbajẹ láti dábõbò orílẹ̀-èdè nwọn, láìṣe èyí nwọn yíò pa nwọ́n—Amalikíà àti àwọn ará Lámánì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá tí a ti mọdisí—Tíákúmì lé àwọn ará Lámánì padà sẹ́hìn ó sì pa Amalikíà nínú àgọ́ rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 67 sí 66 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún karundinlọgbọ̀n nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì, lẹ́hìn tí nwọ́n ti fi àlãfíà lélẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn Léhì àti àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì nípa ti ilẹ̀ nwọn, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ọdún karundinlọgbọ̀n pẹ̀lú àlãfíà;
2 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọn kò ní àlãfíà tí ó pé fún ọjọ́ pípẹ́ ní ilẹ̀ nã, nítorítí asọ̀ bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín àwọn ènìyàn nã nípa onídàjọ́ àgbà nã Pahoránì; nítorí kíyèsĩ, àwọn apá kan nínú àwọn ènìyàn nã fẹ́ kí nwọ́n yí díẹ̀ nínú òfin nã padà.
3 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Pahoránì kò yìi padà kò sì gbà kí nwọ́n yí òfin nã padà; nítorínã, kò tétísílẹ̀ sí àwọn tí nwọ́n ti fi ìfẹ́ inú nwọn àti ìbẽrè nwọn hàn nípa yíyí òfin nã padà.
4 Nítorínã, àwọn tí nwọ́n fẹ́ kí a yí òfin nã padà bínú síi, nwọ́n sì fẹ́ kí ó dẹ́kun láti jẹ́ onídàjọ́ àgbà lórí ilẹ̀ nã; nítorínã, àríyànjiyàn líle bẹ́ sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ nã, ṣùgbọ́n kò yọrí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀.
5 Ó sì ṣe pé àwọn tí ó fẹ́ kí a rọ Pahoránì sílẹ̀ lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ni à npè ní àwọn-afọbajẹ, nítorítí nwọ́n fẹ́ láti yí òfin padà ní ọ̀nà tí nwọn yíò fi da ìjọba olómìnira rú tí nwọn yíò sì fi ọba sí órí ilẹ̀ nã.
6 Àwọn tí nwọ́n sì fẹ́ kí Pahoránì wà síbẹ̀ gẹ́gẹ́bí onídàjọ́ àgbà lórí ilẹ̀ nã gba orúkọ àwọn-ẹni-òmìnira lé ara nwọn; báyĩ sì ni ìyapa wà lãrín nwọn, nítorítí àwọn ẹni-òmìnira nã ti pinnu tàbí pé nwọ́n dá májẹ̀mú láti gbé àwọn ẹ̀tọ́ àti ànfàní ìgbàgbọ́ nwọn ró ní ti ìjọba olómìnira.
7 Ó sì ṣe tí nwọ́n parí ọ̀rọ̀ asọ̀ tí ó wà lãrín nwọn nípa ohùn àwọn ènìyàn nã. Ó sì ṣe tí ohùn àwọn ènìyàn nã gbe àwọn ẹni-òmìnira, Pahoránì sì di ìtẹ́ ìdájọ́ mú, èyítí ó fa àjọyọ̀ púpọ́ lãrín àwọn arákùnrin Pahoránì àti pẹ̀lú púpọ̀ nínú àwọn ẹni-òmìnira, tí nwọ́n sì pa àwọn-afọbajẹ lẹ́nu mọ́, tí nwọn kò sì tó láti dãbá láti ṣe àtakò ṣùgbọ́n tí nwọn kò ṣaláì gbé ipa ti òmìnira ró.
8 Nísisìyí àwọn tí nfẹ́ kí ọba ó wa jẹ́ àwọn tí nwọn jẹ́ ìran olówó, nwọ́n sì nwá ọ̀nà láti jẹ́ ọba; nwọ́n sì rí àtìlẹhìn lọ́wọ́ àwọn tí nwá agbára àti àṣẹ lórí àwọn ènìyàn nã.
9 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àsìkò yĩ jẹ́ èyítí ó léwu kí asọ̀ ó wà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì; nítorí kíyèsĩ, Amalikíà ti rú ọkàn àwọn ènìyàn Lámánì sókè sí àwọn ènìyàn Nífáì, tí ó sì nkó àwọn ọmọ ogun jọ láti gbogbo ẹ̀ka ilẹ rẹ, ti o si ndi ìhámọ́ra fún nwọn, tí ó sì nṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀; nítorítí ó ti búra láti mu ẹ̀jẹ̀ Mórónì.
10 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwa ó ríi pé ìlérí rẹ̀ tí ó ṣe jẹ́ èyítí ó ṣe láì-farabalẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ṣe ìmúrasílẹ̀ ara rẹ̀ àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti jáde wá láti jagun pẹ̀lú àwọn ara Nífáì.
11 Nísisìyí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ kò pọ̀ tó ti àtẹ̀hìnwá, nítorí ti àwọn ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̃gbẹ̀rún tí nwọ́n pa nípasẹ̀ ọwọ́ àwọn ará Nífáì; ṣùgbọ́n l’áìṣírò àdánù nlá nwọ́n sí, Amalikíà ti kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó lágbára kan jọ, tóbẹ̃ tí ẹ̀rù bã láti sọ̀kalẹ̀ wá sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.
12 Bẹ̃ni, Amalikíà pãpã fúnrarẹ̀ sọ̀kalẹ̀ wá, níwájú àwọn ará Lámánì. Èyí sì jẹ́ ọdún karundinlọgbòn nínú ìjọba àwọn onídàjọ́; ó sì jẹ́ àkokò kannã tí nwọ́n ti bẹ̀rẹ̀sí parí ọ̀rọ̀ asọ̀ tí ó wà lãrín nwọn nípa ti onídàjọ́ àgbà, tĩ ṣe Pahoránì.
13 Ó sì ṣe pé nígbàtí àwọn tí nwọn npè ní àwọn-afọbajẹ ti gbọ́ wípé àwọn ará Lámánì nbọ̀wá láti bá nwọn jagun, nwọ́n yọ̀ nínú ọkàn nwọn; nwọ́n sì kọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun, nítorítí nwọ́n bínú gidigidi sí onídàjọ́ àgbà, àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn olómìnira nã, tí nwọ́n kọ̀ láti gbé ohun ìjà láti dãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn.
14 Ó sì ṣe pé nígbàtí Mórónì rí èyí, tí ó sì ríi pé àwọn ará Lámánì nbọ̀wá sínú etí ilẹ̀ nã, ó bínú gidigidi nítorí ọkàn líle àwọn ènìyàn nã tí òun ti ṣapá pẹ̀lú ìtẹramọ́ tí ó pọ̀ láti pa nwọ́n mọ́; bẹ̃ni, ó bínú púpọ̀-púpọ̀; ọkàn rẹ̀ kún fún ìrunú sí nwọn.
15 Ó sì ṣe tí ó fi ẹ̀bẹ̀ ránṣẹ́ sí bãlẹ̀ ilẹ̀ nã, ní ìbámu pẹ̀lú ohùn àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì fẹ́ kí ó kã, kí ó sì fún un (Mórónì) ní agbára láti mú àwọn olùyapa nnì dãbò bò orílẹ̀ èdè nwọn, tàbí kí ó pa nwọn.
16 Nítorítí ó jẹ́ ohun àníyàn àkọ́kọ́ fún un láti mú wá sí ópin àwọn ìjà àti àwọn ìyapa lãrín àwọn ènìyàn nã; nítorítí kíyèsĩ, èyí ni ó ti jẹ́ ìdí gbogbo ìparun nwọn láti àtẹ̀hìnwá. Ó sì ṣe tí olórí ilẹ̀ nã fi fún nwọn ní ìbámu pẹ̀lú ohùn àwọn ènìyàn nã.
17 Ó sì ṣe tí Mórónì pàṣẹ pé kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ kí ó lọ kọlũ àwọn afọbajẹ, láti mú ìgbéraga àti ìwà ìjọra-ẹni-lójú nwọn kúrò, kí nwọ́n sì pa nwọ́n, bíkòjẹ́ bẹ̃, kí nwọ́n gbé ohun ìjà nwọn kí nwọ́n sì ṣe àtìlẹhìn fún ìjà òmìnira nã.
18 Ó sì ṣe tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã kọjá lọ ní ìkọlù nwọ́n; tí nwọ́n sì mú ìgbéraga àti ìwà ìjọra-ẹni-lójú nwọn kúrò, tó bẹ̃ tí ó fi jẹ́ wípé bí nwọ́n ṣe ngbé àwọn ohun ìjà-ogun nwọn sókè láti bá àwọn ènìyàn Mórónì jà ni nwọ́n nké nwọn lulẹ̀ tí nwọ́n sì rẹ́ nwọn mọ́lẹ̀.
19 Ó sì ṣe tí iye àwọn olùyapa nnì tí nwọ́n fi idà ké lulẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin; àwọn olórí nwọn tí nwọn kò pa lójú ogun ni nwọ́n sì mú tí nwọ́n jù sínú tũbú, nítorítí kò sí àyè fún ìdájọ́ nwọn ní àkokò yìi.
20 Àwọn olùyapa tí ó sì ṣẹ́kù nnì, jọ̀wọ́ ara nwọn fún gbígbé àsíá òmìnira nã ró, kàkà kí nwọn ó di kíké lulẹ̀ lọ́wọ́ idà, nwọ́n sì mú nwọn gbé àsíá ọ̀mìnira sókè lórí àwọn ilé ìṣọ́ gíga nwọn, àti nínú àwọn ìlú-nlá nwọn, àti láti gbé ohun ìjà ogun fún ìdãbò bò orílẹ̀-èdè nwọn.
21 Báyĩ sì ni Mórónì fi òpin sí àwọn afọbajẹ nnì, tí kò sì sí ẹnìkẹni tí a nfi orúkọ afọbajẹ pè mọ́; báyĩ sì ni ó fi òpin sí ìwà ipá àti ìgbéraga àwọn ènìyàn nnì tí nwọn nhu ìwà ìjọra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n a rẹ̀ nwọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nwọn, àti láti jà takuntakun fún òmìnira nwọn kúrò nínú oko-ẹrú.
22 Kíyèsĩ, ó sì ṣe pé bí Mórónì ṣe nfi òpin sí àwọn ogun àti asọ̀ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, tí ó sì nmú nwọn sínú àlãfíà àti ọ̀làjú, tí ó sì nṣe ìlànà fún ìmúrasílẹ̀ fún ogun pẹ̀lú àwọn ará Lámánì, kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì ti wọ inú ilẹ̀ Mórónì wá, èyítí nbẹ ní ibi ìhà etí òkun.
23 Ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì kò lágbára tó nínú ìlú-nlá Mórónì; nítorínã, Amalikíà lé nwọn, ó sì pa púpọ̀. Ó sì ṣe tí Amalikíà mú ìlú-nlá nã ní ìní, bẹ̃ni, ó mú gbogbo àwọn ibi odi nwọn.
24 Àwọn tí nwọ́n sì sá jáde kúrò ní inú ìlú nlá Mórónì lọ sínú ìlú nlá Nífáìhà; àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìlú-nlá Léhì kó ara nwọn jọ, nwọ́n sì ṣe ìmúrasílẹ̀ nwọ́n sì ṣetán láti bá àwọn ará Lámánì jagun.
25 Ṣùgbọ́n ó ṣe tí Amalikíà kò gbà kí àwọn ará Lámánì ó lọ kọlũ ìlú-nlá Nífáìhà nínú ogun, ṣùgbọ́n ó mú nwọn dúró ní etí bèbè òkun, ó sì fi àwọn ènìyàn sí gbogbo ìlú-nlá láti pãmọ́ àti láti dãbò bò ó.
26 Báyĩ ni ó sì tẹ̀síwájú, tí ó nmú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, ìlú-nlá Nífáìhà, àti ìlú-nlá Léhì, àti ìlú-nlá Mọ́ríátọ́nì, àti ìlú-nlá Òmnérì, àti ìlú-nlá Gídì, àti ìlú-nlá Múlẹ́kì, gbogbo nwọn ni ó wà ní ibi ìhà ìlà-oòrùn ní ẹ̀gbẹ́ bèbè òkun.
27 Báyĩ sì ni àwọn ará Lámánì ṣe ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, nípasẹ̀ ọgbọ́n àrékérekè Amalikíà, nípasẹ̀ àìmọye àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn, gbogbo nwọn ni nwọ́n sì dãbò bò ní ọ̀nà ìmọdisí ti Mórónì; gbogbo nwọn ni ó sì jẹ́ ibi-ìsádi fún àwọn ará Lámánì.
28 Ó sì ṣe tí nwọ́n kọjá lọ sí etí ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, tí nwọ́n lé àwọn ará Nífáì níwájú nwọn tí nwọ́n sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀.
29 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Tíákúmì pàdé nwọn, ẹnití ó pa Mọ́ríátọ́nì tí ó sì ti ṣíwájú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní sísá tí ó nsálọ.
30 Ó sì ṣe tí ó ṣíwájú Amalikíà pẹ̀lú, bí ó ṣe nkó àwọn ẹgbẹ́-ọmọ ogun rẹ̀ púpọ̀ nnì kọjá lọ kí ó lè mú ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ ní ìní, àti ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá.
31 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ ó bá ìjákulẹ̀ pàdé nítorípé Tíákúmì àti àwọn ará rẹ̀ lée padà, nítorípé ajagun nlá ni nwọn í ṣe; nítorípé gbogbo ọmọ ogun Tíákúmì ni ó tayọ àwọn ará Lámánì nínú agbára nwọn àti nínú ọgbọ́n ogun jíjà nwọn, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì borí àwọn ará Lámánì.
32 Ó sì ṣe tí nwọ́n yọ nwọ́n lẹ́nu, tóbẹ̃ tí nwọ́n sì pa nwọ́n àní títí ilẹ̀ fi ṣú. Ó sì ṣe tí Tíákúmì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pàgọ́ nwọn sí ibi etí ãlà ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀; tí Amalikíà sì pàgọ́ rẹ̀ sí ibi etí ãlà ilẹ̀ ní bèbè ẹ̀gbẹ́ òkun, báyĩ sì ni nwọ́n ṣe lé nwọn.
33 Ó sì ṣe nígbàtí ó ti di alẹ́, Tíákúmì àti ìránṣẹ́ rẹ̀ yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ jáde nwọ́n sì jáde lọ ní alẹ́, nwọ́n sì lọ sínú ibùdó Amalikíà; sì kíyèsĩ, orun ti mú nwọn nítorítí ãrẹ̀ ṣe nwọ́n lọ́pọ̀, èyítí ó jẹ́ bẹ̃ nítorí lãlã tí nwọ́n ti ṣe lọ́jọ́ nã àti nítorí õru tí ó mú.
34 Ó sì ṣe tí Tíákúmì yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọ inú àgọ́ ọba lọ, ó sì gún un ní ọ̀kọ̀ wọ inú àyà rẹ̀ lọ; ó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láìjí àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀.
35 Ó sì tún yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ padà lọ sínú àgọ́ tirẹ̀, sì kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nsùn, ó sì jí nwọn, ó sì sọ gbogbo ohun tí òun ti ṣe.
36 Ó sì mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ dúró ní ìmúrasílẹ̀, bóyá àwọn ará Lámánì lè jí kí nwọ́n sì wá láti kọlũ nwọ́n.
37 Báyĩ sì ni ọdún karundinlọgbọ̀n ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì parí; báyĩ nã sì ni ọjọ́ ayé Amalikíà parí.